Oluwo: Kí làwọn obìnrin ń wá kiri, tí wọn ń sanwó láti fẹ́ ọkùnrin

Oríṣun àwòrán, oluwo
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Ilufemiloye Telu 1, ti kilọ fun awọn obinrin lori ẹrọ ayelujara lati ṣọra fun awọn ayederu eniyan ti wọn n fi orukọ rẹ gba owo lọwọ awọn obinrin.
Eyi ko ṣẹyin ẹsun ti Oluwo fi kan awọn obinrin kan to n wa si aafin, lati wa fi ẹjọ awọn gbajuẹ ti wọn n lu wọn ni jibiti lori oju opo Facebook sun.
Oluwo ni lori Facebook ni wọn ti n lu awọn obinrin naa ni jibiti owo, ti oun ko si si lori Facebook, yatọ si oju opo Instagram.
- Ọ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo
- Oluwo àti Olorì àná, Chanel Chin tahùn síra
- Ẹ má lọgun ‘Oduduwa Nation’ mọ́, Yorùbá ló kàn láti jẹ ààrẹ - Oluwo
- Ọba ni mí, mi ò le b'ọ̀rìṣà, Olorì tuntun tó ń bọ̀ já gbogbo ''scale''- Oluwo ti Iwo
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
Kabiyesi ni awọn gbajuẹ naa ṣi 'personal page' lori Facebook ti wọn ti n lu awọn obinrin yii ni jibiti, pẹlu ileri pe Oluwo yoo fi wọn ṣe aya.
''Emi o wa iyawo o, mo ni ẹni ti mo n fẹ, obinrin to ba n wa ọkọ, ko wa lọ si iwaju
Awọn ti wọn n wa si aafin n sọ wi pe wọn n gba owo ọti ni ọwọ awọn lati fi ṣe etutu lati fi fẹ wọn.
A kii ṣe etutu ni ilu Iwo, a ki n bọ orisa ni aafin ti wa, nitori naa irọ lasan ni''
Oluwo ti ilu Iwọ ni obinrin to wa si aafin ni wọn gba 17,500 Naira ni ọwọ oun, wi pe wọn fẹ fi ra ọti lati fi ṣe etutu.
''Ki ni awọn obinrin yii n wa kiri, ti wọn n san owo lati fi fẹ ọkunrin.
Ẹni to ba n wa ọkọ, ko wa si aafin lati wa wo o boya Oluwo ko ni aya, amọ mi o si lori igba mọ, laipẹ ni ma a ṣe afihan ayaba tuntun.
''Mo ti ni iyawo ti temi, ẹni to ni oruka to wa ni ọwọ Oluwo ti gba a, mi o fẹ iyawo ori ayelujara.
''Nitori ọpọ ti n wa si aafin, ọkan ni 92,000 ni oun san nitori oun fẹ fẹ Oluwo, ko si lori atẹ o''
''Nigba wo ni aye di radarada to jẹ wi pe obinrin ni yoo ma a san owo lati fẹ ọkunrin, eleyii ko bojumu rara.''
Bakan naa ni Oluwo ṣeleri wi pe laipẹ laijina, awọn ti wọn ba n ṣe iru rẹ yoo foju wina ofin nitori awọn ti fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Ti ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni wọn fẹsun kan ọba kan ni ipinlẹ Ogun wi pe o lu awọn obinrin ni jibiti lori ayelujara, eleyii to ṣeleri igbeyawo fun wọn.

Ta ló ń fi orúkọ Oluwo lu àwọn obìnrin ní jìbìtì lórí ayélujára?

Oríṣun àwòrán, Facebook/emperortelu1
Oye to kan ara Iwo ni Yoruba a maa sọ, wọn ni bo pẹ boya yoo kan ara Ẹdẹ.
Boya nitori ki iru nkan to ṣẹlẹ si oriade kan nilẹ yi laipẹ, maa ba a ṣẹlẹ si, lo mu ki Oluwo ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu Kinni, se maa lọgun pe, oun ko wa iyawo.
Ninu atẹjade kan to fi sọwọ sawọn oniroyin ni Oluwo ti lọgun bẹẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó tún n rúgbó bọ̀! Ṣé lóòótọ́ ni Olori Damilọla ti sá kúrò ní ààfin Ọyọ?
- Omi àlàáfíà Nàíjíríà kò le tòrò àyàfi... - Afenifere
- Ajínigbé jí èèyàn lọ́nà Ife sí Ikire, ọdẹ ìbílẹ̀ àti ọlọ́pàá wọnú igbó láti wá wọn rí - ọlọ́pàá Osun
- Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha
- Bàálù ọmọ ogun òfúrufú ṣèèèsì pa sọ́jà 20 ní Borno, ọmọ Naijiria fárígá
- Yorùbá, ẹ má ṣùn o lórí ààbò tó mẹ́hẹ torí àìláṣọ lọ́rùn pààká... - ARG lọgun
- Ọjọ́ Ajé gba ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ ọmọ Nàíjíríà láti ọwọ́ àwọn agbébọn
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
Oba Abdulrasheed Akanbi ni pẹlu bi awọn kan se n ko sọwọ gbajuẹ, paapaa bi awọn obinrin to fẹ fẹ oun ṣe n pọ si, oun ni lati sọ faraye pe oun ko wa iyawo rara.
Oluwo ni ẹnikẹni to ba ko sọwọ awọn gbajuẹ yii ṣe bẹẹ fun ori ara rẹ ni, o ni oun kọ loun n kọ ẹnu ifẹ si wọn loju opo ayelujara.
''Eti wa ti kun pe awọn gbajuẹ wọnyii ti ṣi oju opo lorukọ Oluwo, ti awọn obinrin ṣi n kopa ninu etutu orisi nitori pe wọn fẹ di Olori''
O tẹsiwaju pe, awọn obilẹjẹ ẹda yii fẹ ba Oluwo lorukọ jẹ ni, nitori naa, oun n fi to araalu leti pe, Oluwo ko ni oju opo kankan lori Facebook yatọ si ti tẹlẹ.
Bakan naa lo kede pe oun ti fi ọrọ naa to ileesẹ ọlọpaa leti.
O wa kilọ pe ẹnikẹni to ba ko sọwọ awọn gbajuẹ naa ko ni nkankan ṣe pẹlu Oluwo.
Bẹẹ ba gbagbe, ko si Olori kankan lọọdẹ Kabiyesi Oluwo titi di akoko yii, lẹyin ti Olori Channel tii se ayaba kẹru kuro laafin, ni nkan bi ọdun kan sẹyin.























