Insecurity: Buhari bẹ̀bẹ̀ pé kí Amẹ́ríkà gbé olú iléeṣẹ́ ológun Àfíríkà wá sí Nàíjíríà

Buhari ati Blinken n se ipade lori ayelujara

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kesi orilẹede Amẹrika lati gbe olu ileeṣẹ ikọ ọmọogun Afirirka (AFRICOM) ti ilẹ Amẹrika n saakoso rẹ, kuro ni orilẹede Germany.

Aarẹ Buhari sọ ọrọ yii nibi ipade ori ẹrọ ayelujara to se pẹlu minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni ilẹ Amẹrika, Anthony Blinken.

Africom to jẹ ikọ ọmọogun ilẹ Amẹrika to n ṣe iranwọ fun awọn orilẹede Afrika to wa ninu laasigbo, ni wọn da silẹ lọdun 2007, amọ 2008 ni wọn bẹrẹ si ni ṣiṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn ibi ti wọn ti kopa ni orilẹede Niger, Djibouti, Chad ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Femi Adesina fi lede, Buhari ni gbigbe olu ileeṣẹ naa wa si ilẹ Afrika pọn dandan, nitori idojukọ eto aabo to dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria lọwọlọwọ.

Ibọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Aarẹ Buhari ni ti wọn ba gbe ileeṣẹ ogun ilẹ Amẹrika naa wa si orilẹede Naijiria, eyi yoo dẹkun iṣekupani to n waye naa.

''Eto aabo to dẹnukọlẹ lagbegbe Iwọ oorun ilẹ Afrika, to fi mọ aarin gbungbun ati agbegbe Lake Chad kii ṣe keremi, awọn orilẹede ni ilẹ Afrika ko si le e da nikan koju rẹ, nitori naa wọn nilo iranwọ.

''Amọ ikọ oloogun Naijiria n ja fitafita lojoojumọ lati koju eto aabo to dẹnukọlẹ naa, amọ iranlọwọ orilẹede Amẹrika ṣe koko fun wọn lati bori awọn agbebọn ati agbesunmọmi ti wọn n koju.''

Bakan naa ni aarẹ Buhari ni awọn mu ibaṣepọ pẹlu orilẹede Amẹrika ni okunkundun, ti awọn ko si fi sere rara.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Nitori naa, aarẹ Buhari dupẹ lọwọ ijọba aarẹ ilẹ Amerika, Joe Biden, si bi wọn se gbegi kuro lori ifofinde irinajo awọn ọmọ Naijiria to fẹ se atipo lorilẹede Amerika.

Ninu ọrọ rẹ, Blinken ni inu oun dun wi pe orilẹede Amẹrika ni Buhari kọkọ ba sọrọ lori ẹrọ ayelujara ninu eleyii to yẹ ko jẹ irinajo oun si ilẹ Afrika.

O fi da aarẹ Buhari loju wi pe, orilẹede Amẹrika ṣetan lati tẹsiwaju ninu ibaṣepọ to dan mọran pẹlu orilẹede Naijiria.

Amin iyasọtọ kan

Ajínigbé jí èèyàn lọ́nà Ife sí Ikire, ọdẹ ìbílẹ̀ àti ọlọ́pàá wọnú igbó láti wá wọn rí - ọlọ́pàá Osun

Opopona Ibadan, Ife si Ilesa

Oríṣun àwòrán, OSSG

Pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọlọ́paàá àti àwọn ọlọ́dẹ ní ìpińlẹ̀ Osun ni wọ́n fi rí ọgbẹ́ni Okunade Yinka gba padà lọ́wọ́ awọn ajínígbé.

Sáájú ní ìròyin ti jáde pé àwọn ajínígbé gbé àwọn arìnrìnajo kan ni òpópónà Akure si Ilesha ní nńkan bii aago méje àbọ̀ alẹ́ lọjọ Satide.

Ìwádìí fihàn pé àwọn ajínígbé yìí kàn sí ẹbí ẹni ti wọ́n jígbé, láti san owó ìtúsílẹ̀, kí wọ́n tó tu sílẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olùgbé Osun kan, Faboro Adewale sàlàyé pé, àwọn agbébọn náà ń yin ìbọn sókè lákọlákọ láti jẹ́ ki mọto náà dúró, ti wọ́n sì jí ènìyàn mẹta gbé nínú ọkọ̀ èrò náà.

Bákan náà ni agbẹnusọ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Osun Yemisi Opalola náà fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lọ́jọ́ Ajé pé, ǹkan ti ọlọ́pàá gbọ́ ni pé ènìyàn kan péré ni wọ́n jígbé.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa ààlọ́ nílẹ̀ Yorùbá

Gẹ́gẹ́ bi Rebecca Okunade se wi, o mú ẹjọ́ ló si agọ́ ọlapàá pe ọkọ òun tó wọ ọkọ̀ láti Akure, ti pè òun láti sọ pé àwọn ajínígbe ti gbé òun.

Rebecca tó n gbe ni Panada Ikire, ló mẹ́jọ lọ agọ ọlọ́pàá lọ́jọ́ Satide ní nǹkan bíi aago méjọ ku ọgún iṣẹ́jú.

Opalola ni wọ́n jí awọ́n eeyan naa gbé ni opopona Ife si ikorita Akure.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ni àjọṣepọ̀ ọlọ́pàá àti awọn ọlọ́dẹ lo wọ inú igbó Osun, ti wọ́n sì gba ọkùnrin áà láì farapa.

Bákan náà ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC Yorùbá pé, àná ni wọ́n rí ọkùnrin náà dóòlà, ti wọ́n si ti fàá lé àwọn ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́.

Deede ààgo mẹ́wàá òwúrọ̀ ọjọ́ Iṣẹgun si ni ọkunrin naa dara pọ mọ awọn ẹbi rẹ.