Insecurity in Nigeria: Èèyàn bíi àádọ́ta kú ikú òjijì lọ́jọ́ Ajé láti ọwọ́ agbébọ̀n

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Ọjọ Aje to kun fun ẹjẹ ni ọjọ ana, nigba tawọn agbebọn sọsẹ, ti wọn si n pa eeyan kiri yika orilẹede Naijiria.

Se ni ilẹ mu ẹjẹ nipinlẹ Rivers, Kebbi, Anambra, Borno, Ebonyi ati Imo.

Koda rogbodiyan tun waye nilu Eko, ti ẹmi awọn eeyan miran si tun bọ.

Lapapọ, o le ni aadọta eeyan to jade laye lairotẹlẹ yika Naijiria ti akọsilẹ wa fun, lati ọwọ awọn agbebọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sọja marun lo ku nipinlẹ Rivers, ọlọpaa mẹfa ni Imo, eeyan mọkanla ni Kebii, marun ni Eko ati mẹsan ni Anambra.

Bakan naa, sọja mẹfa miran ku ni Borno, meji ni Imo nigba ti awọn akẹkọọ meji lara awọn ti wọn ji gbe ni fasiti Greenfield naa jalaisi.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa ààlọ́ nílẹ̀ Yorùbá

Ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Kebbi ti fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ti pa ọga agba ọlọpaa kan ati osisẹ ọlọpaa mẹjọ pẹlu fijilante meji.

Agbebọn soro ni Kebbi:

Awọn eeyan mọkanla naa lo jade laye lasiko ti awọn ati agbebọn doju ibọn kọ ara wọn lọjọ Aiku.

Osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpa, Nafiu Abubakar sọ fun ileesẹ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN pe deede aago meji abọ ọsan ni isẹlẹ naa sẹlẹ.

Awọn agbebọn naa lo doju ija kọ agbegbe Dankolo, Sakaba, Makuku, Dokar Kambari ati Kurmin Hodo ti gbogbo wọn wa nijọba ibilẹ Sakaba.

Bakan naa, ileesẹ ọlọpaa ni awọn agbebọn naa ko fi ara re lọ sile pẹlu lasiko ija naa.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Olugbe kan ni agbegbe naa, Salisu Adamu sọ funleesẹ NAN pe "Wọn pa ọga ọlọpaa Jimoh Abdullahi. Awọn ọlọpaa mii ati osisẹ fijilante meji mii.

Ẹ jọọ a nilo adura, eeyan meje mii ni wọn tun pa ni abule Inana."

O tun sisọ loju rẹ pe awọn agbebọn naa tun ko ẹgbẹlẹgbẹ maalu lọ ni awọn abule naa.

"Se ni wọn n yinbọn soke laibikita eyi to mu ki awọn ara abule naa sa asala fun ẹmi wọn kaakiri."

Ẹnikan tiẹ tun fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ọlọpaa lo tun di awati lẹyin ikọlu naa.

Amin iyasọtọ kan

Buhari ló ń ki àwọn agbésùnmọ̀mí láyà láti ṣe ìkọlù - Ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan kan, Human Rights Writers Association of Nigeria, HURIWA, ti di ẹbi ikọlu awọn agbesumọmi si awọn ile ijọsin Kristẹni ni Kaduna ru Aarẹ Muhammadu Buhari.

HURIWA sọ pe bi ijọba Buhari ṣe kọ lati jawe lọ gbele ẹ fun minisita eto ibaraẹnisọrọ, Isa Pantami, lo sokunfa isẹlẹ naa.

Ẹgbẹ ajafẹtọẹni naa ni lẹyin ti Pantami jẹwọ pe lootọ ni oun ti fi igba kan ṣe atilẹyin fun awọn ẹgbẹ agbesumọmi bii Al-Qaeda ati Taliban, Buhari ko se ohunkohun si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Huriwa ni eyi lo ki awọn agbesumọmi Naijiria laya lati maa kọlu awọn ile ijọsi bo ṣe wu wọn.

Ninu atẹjade kan ti HURIWA fi sọwọ si awọn akọroyin, eyii to tẹ BBC lọwọ lo ti sọ bẹẹ.

O ni iwa ti Aarẹ Buhari wu ọhun n ṣapẹrẹ fun awọn agbesumọmi naa, lati maa ṣe ohun to wu wọn, ti ohunkohun ko si ni ti ẹyin rẹ jade.

Ikọlu ti awọn agbesumọni naa ṣe si awọn Kristẹni kẹyin ni eyii to waye lọjọ Aiku nile ijọsin kan ni abule Manini Tasha, ni ipinlẹ Kaduna, nibi ti wọn ti pa dokita kan, ti ọpọ ọmọ ile ijọsin naa si farapa.

Gẹgẹ bii ohun ti oṣojumi koro kan sọ, nnkan bii aago mẹsan an owurọ ni awọn agbesumọni naa kọlu ile ijọsin ọhun lasiko ti isin n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

O ni wọn ṣina ibọn bolẹ, eyii to mu ki isin daru, ti wọn si pa dokita kan to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si eto ilera.

HARIWA ti wa ke si awọn ọmọ Naijiria lati rọ ijọba ilẹ Amẹrika, Canada ati ilẹ Gẹẹsi lati kede ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari bii eyii to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ agbesumọmi Al-Qaeda and Taliban.

O tun ni ki awọn ọmọ Naijiria kan an nipa fun awọn adari ijọba lagbaye lati ri ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bii eyii to n faye gba ipakupa awọn eeyan ilu lati ọwọ awọn Fulani darandaran atawọn alakakiti ẹsin Musulumi.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

HARIWA ni "Igbagbọ wa ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko le dẹwọ iṣekupani awọn ọmọ Naijiria nitori oun funra rẹ n ṣatilẹyin fun wọn, awọn adari ijọba lagbaye nikan lo le gba awọn ọmọ Naijiria silẹ, ti wọn si le dawọ ogun abẹle to n bọ ni Naijiria duro."

Ibanujẹ lo jẹ fun wa bi agbebọn se n kọlu Kristiẹni - CAN

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ẹka ti ipinlẹ Kaduna ti bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu awọn Kristẹni ni Kaduna.

Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Caleb Ma'aji fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni o jẹ ohun ibanujẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi n kọlu awọn ile ijọsin lai si idaduro Kankan.

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

CAN ni "Ki ni ẹsẹ awọn ọmọ ilu yii gan to fi jẹ pe awọn agbesumọmi ni ominira ati abo ju awọn ọmọ ilu ti ko lẹṣẹ lọ?"

Lẹyin naa ni CAN ke pe awọn ẹṣọ alabo lati tu awọn ti awọn agbesumọmi naa ji gbe silẹ ni kankan, wọn si tun ke si ijọba apapọ lati ji giri si ojuṣe rẹ loi eto abo dipo eyii to fi n pariwo ẹnu lasan.

Amin iyasọtọ kan

Ọjọ́ ìsinmi òni ro! Agbébọn ṣé ikọlù sílé ìjọ́sìn ní Kaduna, wọ́n jí ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn gbé lọ

Aworan Gomina Kaduna

Oríṣun àwòrán, Twitter/GovKaduna

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti fidi ọrọ mule pe awọn agbebọn kan ti ya wọ ile ijọsin kan nilu Kaduna, ti wọn si pa eeyan kan.

Samuel Aruwan Kọmisana feto aabo abẹle ni Kaduna sọ pe ille ijọsin naa wa ni ijọba ibile Chukun.

O ni lootọ ni ikọlu waye lowurọ ọjọ Aiku lasiko tawọn Kristẹni n jọsin ni abule Manini ni ijọba ibilẹ Chikun.

O ni ni nkan bi ago mẹsan abọ aarọ lawọn agbofinro kan si ile ijọsin Haske Baptist Church nibi ti wọ n ti ri pe awọn agbebọn pa olujọsin kan.

Dokita Zechariah Dogonyaro lorukọ rẹ si n jẹ.

Yatọ si dokita ti wọn pa, wọn tun gbe awọn olujọsin mẹrin salọ.

Sheu Mainika to jẹ olugbe adugbo naa la tun gbọ pe o farapa.

Aruwan ninu atẹjade yi tun fidi ọrọ mulẹ pe awọn agbebọn tun ṣe ikọlu sawọn abule mii ni ijọba ibilẹ Birnin Gwari ti wọn si pa eeyan mẹfa.

Ẹwẹ, awọn agbebọn miran gẹgẹ bi Aruwan ṣe salaye tun pa arabinrin kan,Rahila Dauda ni abule Amfu ni Kachia bakan naa.

Ọlọpa ilẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ̀ yòó wáyé

Gomina El Rufai bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ wọnyi to si ba awọn ara ile ijọsin ti ikọlu yi ti waye kẹdun.

Agbegbe Chukun jẹ ibi tawọn agbebọn janduku ti n ṣoro bii agbọn, ti gbogbo igbiyanju awọn ara adugbo lati dẹkun rẹ si ja si pabo.

Laipẹ yi ni wọn ri oku awọn akẹkọọ ileewe fasiti Greenfield mẹta kan ti awọn ajinigbe gbe ni ijọba ibilẹ yii bakna naa.

Nileewe taa n wi yi, awọn agbebọn ji awọn akẹkọọ gbe lalẹ ọjọ Iṣẹgun lẹyin ti wọn pa ọlọdẹ ileewe naa.