Amotekun ìpínlẹ̀ Ondo ti ń wá àwọn òṣìṣẹ́ ojú ọ̀nà mẹ́ta tí wọ́n jí gbé lágbègbè Akoko

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Ikọ amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn ti kan sinu igbo lati ṣawari awọn oṣiṣẹ oju ọna mẹta ti awọn ajinigbe ji gbe lopopona Ikaramu si Akunnu Akoko.
Adari ikọ naa ni ipinlẹ Ondo, Adeleye Olusanyero lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan.
O ni "Ootọ ni pe wọn ji awọn eeyan mẹta to n ṣiṣẹ oju ọna marosẹ Ikaramu si Akunnu-Akoko gbe, ṣugbọn a ti kan lu inu igbo ti wọn gbe wọn lọ lati ṣawari wọn."
Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ ileeṣẹ ti awọn eeyan mẹta naa n ṣiṣẹ fun, o ni wọn kii ṣe oṣiṣẹ ileeṣẹ to n tu ọna ṣe fun ijọba ipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Adeleye ṣo siwaju si pe oun ko le sọ boya awọn ajinigbe ọhun ti kan si ẹbi awọn ti wọn ji gbe lati bere fun owo itusilẹ kankan, ṣugbọn awọn ti n ṣiṣẹ takuntakun ninu igbo naa lati ṣawari awọn eeyan ọhun.
- Ọwọ́ NDLEA tẹ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tó n ta 'cookies' tí wọ́n fi oògùn olóro ṣe fún àwọn ọmọ́de
- Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ ìdálẹ́bi fún Derek Chauvin lórí ẹ̀sùn gbogbo lórí ikú Floyd
- Wo ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU Ile Ife fi gbẹ̀mí ara rẹ̀
- Èéti jẹ́ tí Iyabọ Ojo fún ọmọ rẹ̀, Priscilla ní gbèdéke ọjọ́ orí 24 láti ṣe ìgbéyàwó?
- Chelsea, Arsenal, Liverpool, Tottenham Man City, Man United yọ ara wọn kúrò nínú ìdíje Super League tuntun
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ṣe lè jàǹfàní ṣíṣe àtìpó ní Britain
Lori ipo ti iṣẹ oju ọna naa wa lẹyin ti wọn ji awọn oṣiṣẹ naa gbe tan, Adeleye sọ pe iṣe naa ko duro, nitori ikọ alabo Amotekun ti bẹrẹ si n pese abo to peye fun awọn oṣiṣẹ to ku, wọn si ti pada sẹnu iṣẹ wọn.
Iroyin sọ pe ọjọ Iṣẹgun ni wọn ji awọn eeyan naa gbe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ, iṣẹlẹ ijinigbe ọhun si ti mu ibẹrubojo ba ọpọ olugbe ilu naa.
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Tee-Leo Ikoro sọ pe awọn ti n ṣiṣẹ lati ti daju pe awọn eeyan naa bọ lọwọ awọn ajinigbe naa lai farapa.
Iṣẹlẹ ijinigbe naa lo n waye lẹyin ọjọ diẹ ti Ọba Auga, iyẹn Alauga ti ilu Auga-Akoko, Ọba Samuel Agunloye rọ gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lati fi awọn ẹṣọ alaabo ṣowọ si agbegbe naa nitori eto abo to mẹhẹ.
Ṣaaju ni Akeredolu ti kọkọ ṣeleri fun awọn eeyan ọhun pe oun yoo ṣe aṣepari opopona Akunnu si Ikaramu ati Oke Agbe Akoko, eyii to sọ pe awọn ijọba to ṣaaju rẹ ti kọ silẹ lati nnkan bii ọdun mejidinlogun.















