Fiditi Amotekun killing: Àwọn agbébọn pa ọmọ ikọ̀ Amọtẹkun kan ni ìpínlẹ̀ Oyo

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Amotekun

Àwọn ọmọ ikọ̀ Amọtẹkun ti ké gbàjarè pé àwọn nílò nkan ìjà láti lè kojú àwọn jàndùkú tó ń da ìhà gúúsù ìwọ-oòrùn Nàìjíríà láàmú.

Ìpè yìí kò ṣẹ̀yìn iṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ni agbègbè Fiditi níbi ti wọn ni àwọn agbébọn pa Suleiman Quadri to jẹ́ ọmọ ikọ̀ Amọtẹkun tó n ṣọ́ àwọn òṣìṣẹ́ Living Farm.

Quadri, ẹni ọdún márùn-úndínlọ́gbọ̀n ló pàdé ikú lọ́jọ́ Isẹgun lọ́wọ́ àwọn agbébọn tó tó mọ́kànlá to lọ dènà dè wọ̀n ni oko Living Farm tó wà ní agbègbè Fiditi, nípìnlẹ̀ Oyo.

Ádárì àwọn ikọ̀ Amọtẹkun col. Olayinka Olayanju fìdí ọ̀rọ̀ naa múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan ní Ọjọ́rú nílùú Ibadan.

Gẹ́gẹ́ bí Olayanju ṣe sọ Quadri ati Amo Yisau ń sin àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ náà lọ sí ibiṣẹ́ ni lásìkò ìkọlù ọ̀hún."Ìbọ́n ba Yisau naa ṣùgbọ́n ó yèé, ó sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn kan nílùú Oyo."

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

O ni: "The gallant Quadir left behind an aged father, a wife and a son.

"Ìyá àti bàbá rẹ̀ arúgbó, ìyàwó àti ọmọkùnrin kan ni Quadridi sílẹ̀ lọ

"Wọ́n tí sin ni ìlànà ẹ̀sìn Islam" gẹ́gẹ́ bi Olayanju ṣe sọ.

Ẹ̀wẹ̀, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo sọ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gbogbo àwọn agbébọn naa tó ṣekú pa ọmọ ikọ̀ Amọtẹkun ni ọwọ́ yóò tẹ̀.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo Adewale Osifeso to tún fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fi kún pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa.

O ní: "Ìwádìí tó gbòòrò ni ó ti bẹ̀rẹ̀ láti tọpasẹ àwọn ọ̀daràn naa."

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa