George Floyd: Ilé ẹjọ́ ni Derek Chauvin jẹ̀bi ẹ̀sùn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n fi kàn án lórí ikú Floyd

Patako alakọle kan nipa iku Floyd

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ ti gbe idajọ kalẹ pe ọlọpaa to kunlẹ le oloogbe George Floyd lọrun to fi ku lọdun 2020, iyẹn ọgbẹni Derek Chauvin, jẹbi ẹsun ipaniyan mẹtẹẹta ti wọn fi kan an.

Amọṣa, yoo to ọsẹ mẹjọ si asiko yii ki wọn to ran an lọ si ẹwọn bi o tilẹ jẹ wi pe ahamọ awọn ọlọpaa ni yoo wa titi di igba naa.

Ọlọpaa ni Derek Chauvin ni ipinlẹ Minnesota lorilẹ-ede Amẹrika ti fidio kan ti ọdọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Darnella ya lasiko ti Derek fi gbe orunkun le ọkunrin alawọdudu kan ti orukọ rẹ n jẹ George Floyd lọrun nigba ti wọn fẹ fi panpẹ ofin mu.

Fidio yii lo di ilu mọọka lori ayelujara ti gbogbo agbaye fi kọminu lori iwa kotọ awọn ọlọpaa si araalu paapaa awọn Adulawọ nibẹ, eleyi to bi iwọde "Black lives matter"

Ni ọjọ Iṣẹgun lawọn igbimọ oludajọ nile ẹjọ to gbọ ẹsun ti wọn fi kan ọlọpaa naa, Derek Chauvin gbe ero wọn sita lori ẹsun naa ti wọn si ni pe o jẹbi ẹsun naa.

Aarẹ Biden ati Igbakeji rẹ Kamala

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lawọn adari lagbaye n sọ?

Aarẹ Biden ati igbakeji rẹ Kamala Harris

Aarẹ Biden ati igbakeji rẹ Kamala Harris wa lara awọn aṣiwaju lagbaye ti wọn kọkọ sọrọ lori idajọ naa.

Biden ni idajọ naa ko to o, o fihan pe omi ṣi n bẹ lamu fawọn adari lorilẹ-ede Amẹrika. O ni wọn ni lati dẹkun iwa ẹlẹyamẹya lẹka gbogbo lorilẹ-ede Amẹrika.

Biden ni "a o le e dawọ duro nibi ti a de yii," ti oun ati igbakeji rẹ si, Kamala Harris si ṣalaye pe iwa ẹlẹyamẹya lẹkajẹka gbogbo to ti n waye ninu itan orilẹ-ede Amẹrika jẹ "abawọn lara ẹmi orilẹ-ede wa".

Bakan naa ni Aarẹ Joe Biden, aya rẹ, pẹlu igbakeji rẹ Kamala Harris tun pe ẹbi oloogbe Floyd ni kete ti idajọ naa jade ti wọn si ki wọn ku irọju.

Koda, wọn tun ṣe ileri pe igbesẹ yoo tọ idajọ naa lẹyin fun ayipada to yẹ lori ọrọ ẹlẹyamẹya nilẹ Amẹrika lati rii pe iku ẹni wọn ko ja si asan.

Awọn ero n yọ lẹyin idajọ naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Boris Johnson, olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi

Ninu ọrọ tirẹ, olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson wa lara awọn olori orilẹ-ede lagbaye to kọkọ sọrọ lori idajọ naa.

Boris Johnson, loju opo Twitter rẹ, kan sara si idajọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Iku Floyd bami ninu jẹ gidi, inu mi si dun si idajọ naa."

Al Sharpton, ajafẹtọ lorilẹede Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Al Sharpton, ajafẹtọ ọmọniyan lorilẹede Amẹrika

Ẹwẹ, eekan ajafẹtọ ọmọniyan lorilẹ-ede Amẹrika, alagba Al Sharpton tọka si idajọ naa gẹgẹ bi akoko imọlẹ laarin kurukuru ọjọ.

"Loni, a le e nu omije wa nu kuro ki a si tun mura ija fun ọjọ miran"

Awọn ero n yọ lẹyin idajọ naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bakan naa ni alagba Sharpton ṣeranti awọn alawọdudu gbogbo ti wọn ku latọwọ awọn ọlọpaa alawọfunfun.

O si ran awọn ajafẹtọ bii tirẹ leti nibi ipade adura kan lẹyin idajọ naa pe isinku Daunte Wright, ọmọ ogun ọdun tawọn ọlọpaa yinbọn pa lọsẹ to kọja ku ọjọ meji pere.

Barrack Obama pẹlu aya rẹ Michelle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Barack Obama ati aya rẹ Michelle

Barack Obama ati aya rẹ Michelle pẹlu ti sọrọ lori idajọ naa.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, awọn mejeeji ni "ohun to tọna ni ilu Minneeapolis ṣe" ati pe "igbesẹ to yẹ loju ọna ilọsiwaju" ni.

Derek Chauvin

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nigba wo ni Dereck Chauvin yo bẹrẹ gbigba ijiya rẹ?

Nibayii ni wọn ti gbe idajọ rẹ kalẹ, yoo to bii ọsẹ mẹjọ ki wọn to gbe ijiya rẹ sita.

Amọṣa, niwọn to jẹ wi pe ko fi jẹ pe ko ni akọsilẹ iwa ọdaran kankan sẹyin, ilakalẹ ofin ni ipinlẹ Minnesota fihan pe o le e lọ si ẹwọn ọdun mejila.

Awọn ero n yọ lẹyin idajọ naa

Awọn olupẹjọ lee gbe awijare kalẹ niwaju ile ẹjọ naa pe ki wọn fun un ni ẹwọn to to ogoji ọdun iyẹn bi onidajọ Peter Cahill to n gbọ ẹjọ naa ba wo o pe ọran rẹ le pupọ.

Àkọlé fídíò, Black lives Matter: Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá nílẹ̀ Amerika.

Ni kete ti wọn gbe idajọ kalẹ ni ariwo ayọ lo gbode ni gbagede ile ẹjọ naa ti awọn eeyan kaakiri orilẹ-ede Amẹrika ti wọn ti peju lati mọ bi idajọ naa yoo ṣe lọ si n fo fayọ pe idajọ ododo fidi mulẹ lori iṣẹlẹ iku Floyd.

Floyd

Oríṣun àwòrán, Reuters