America police killing: Ọlọ́pàá Amẹ́rìkà tún ti yìnbọn pa ọmọ Áfíríkà míì, bàbá ọmọ fárígá!

Akole ifehonuhan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìfẹ̀hónúhàn lórí ìwà àìtọ́ tí àwọn ọlọpàá ń hù sí àwọn aláwọ̀ dúdú nílẹ̀ Amerika

Ọlọpaa ilẹ Amẹrika kan tun ti yinbọn pa alawọ dudu miran

Ẹni ti wọn pa yii jẹ ọmọ oṣiṣẹ ajọ isọkan agbaye, United Nations, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Gambia nilẹ Afirika

Baba ọmọ naa ati ẹbi rẹ si ti n beere fun iwadii to mọnyan lori lọwọ Amẹrika.

Gbogbo bi wọn ṣe n jẹ ekuru pipa awọn ọmọ ilẹ adulawọ lorilẹ-ede Amẹrika ko tan lawo, ṣe lo dabii pe awọn kan tun n gbọn ọwọ si i.

Kini o ṣẹlẹ gangan ni Georgia?

Gẹgẹ bi ajọ aṣewadii ilu Georgia ṣe ṣọ ọ, wọn yinbọn pa Lamin Sisay ẹni ọdun mọkandinlogoji lẹyin ti wọn fi ọkọ le ara wọn ni ilu Georgia lọjọ Ẹti to kọja.

Loju ẹsẹ naa ni wọn kede pe o ti jẹ Ọlọrun ni'pe.

Awọn ọlọpaa ni ṣe ni Lamin funrarẹ fa ibọn yọ.

Yiyinbọn pa arakunrin yii waye lasiko ti ifẹhonuhan n waye nitori George Floyd, ọmọ Adulawọ kan ti ọlọpaa ilẹ Amẹrika fi orunkun pa lọsẹ to koja yii.

KILO SẸLẸ SI SISAY?

Awọn aṣewadii ilu Georgia ni USA jẹ ko di mimọ pe ni deede aago mẹrin ku iṣẹju mọkanla owurọ ni ọlọpaa kan ni Snellville, Georgia gbiyanju lati da ọkọ Lamin duro ṣugbọn o kọ lati duro, ni wọn ba gba tọ ọ lẹyin.

Awọn ọlọpaa sun mọ ọkọ ọhun wọn si pa a laṣẹ ko fi ọwọ rẹ han, nigba ti ẹni to n wa ọkọ kọ... lo ba na ibọn si awọn ọlọpaa.

Ka to wi, ka to fọ, ko to pẹ, ọlọpaa da ibọn bo o wọn si sa pada lati fara pamọ lẹyin ọkọ ti wọn fi n rede.

Awọn aṣewadii Georgia fi kun un pe awọn ọlọpaa tun ke si ikọ ọlọpaa SWAT ti awakọ ọhun tun yinbọn si awọn naa.

Wọn ni ọlọpaa SWAT kan naa yinbọn lasiko naa.

Lare Sisay, baba oloogbe to n ṣiṣẹ pẹlu. ajọ United Nations ni awọn ọlọpaa ko ṣe ohun to tọ lati yanju iṣẹlẹ ọhun lalaafia ati pe oun gbagbọ pe irọ ni, nitori pe ọmọ oun ko ni ibọn.

Orukọ Ọgbẹni Sisay ti wọpọ lori ayelujara lọsẹ yii pe o n ṣatilẹyin fun ipolongo lodi si aidaa awọn ọlọpaa Amẹrika si awọn eeyan alawọdudu.

Ẹwẹ, ọlọpaa to pa George Floyd lọsẹ to kọja ti ọrọ rẹ n fa ifẹhonuhan kaakiri Amẹrika lọwọlọwọ ti gba idaduro lẹnu iṣẹ ọlọpaa wọn si ti fi ẹsun ipaniyan kan an.

Bakan naa ni iwadii ti fihan pe Floyd ni ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra.