Ondo Election tribunal judgment: Ilé ẹjọ́ kótẹ́milọ́rùn ló kù, dídùn lọsàn á sò- Ondo PDP

Oríṣun àwòrán, @Jegede
Lẹyin idajọ ileẹjọ to gbọ ẹjọ eto idibo to waye ni ipinlẹ Ondo loṣu kẹwa ọdun to kọja ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni pe ko tan sibẹ.
PDP ti Eyitayo Jegede dije dupo gomina labẹ rẹ ti sọrọ soke wi pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ni awọn n lọ bayii nitori idajọ naa ku diẹ kaato.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa nipinle Ondo, Kennedy Ikantu Peretei fi sita ni wọ́n ti sọ pe PDP mọ pe iroyin ayọ ni wọn a ba bọ nibẹ.
PDP ni igbagbọ ẹgbẹ naa ni pe ko si ẹni to le tẹ ofin ọdun 1999 Naijiria mọlẹ lọna aitọ.
Bakan naa ni wọn tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati ni suuru nitori adun lo maa gbẹyin ewuro ẹjọ Jegede gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ondo.
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa Olufon, Ọba Adekunle Magbagbeola tó wàjà
- Tani Mahamat Kaka Idriss Deby tó di aàrẹ̀ tuntun ilẹ̀ Chad lẹ́yìn ìṣekúpani bàbá rẹ̀?
- Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ ìdálẹ́bi fún Derek Chauvin lórí ẹ̀sùn gbogbo lórí ikú Floyd
- Ọwọ́ NDLEA tẹ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tó n ta 'cookies' tí wọ́n fi oògùn olóro ṣe fún àwọn ọmọ́de
- Olufon ti ilu Ifon-Orolu, Ọba Almarouf Adekunle Magbagbeola ti wàjà

Oríṣun àwòrán, Eyitayo jegede/twitter
Iléẹjọ́ da ẹjọ́ Jegede, olùdíje PDP l'Ondo nù, Ó ní Akeredolu ni gómìnà
Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye kotẹmilọrun esi idibo gomina ni ipinlẹ Ondo ti fontẹ lu Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi ẹni taraalu dibo yan sipo gomina nipinlẹ Ondo.
Iléẹjọ́ da ẹjọ́ Jegede, olùdíje PDP nù, Ó ní Akeredolu ni gómìnà tárá Ondo dìbò yaǹ.
Ninu idajọ to gbe kalẹ loni, onidajọ Umar Abubakar to lewaju awọn adajọ mẹta to gbọ ẹjọ naa wọgile ẹjọ ti Jẹgẹdẹ pe lori pe awọn ko laṣẹ labẹ ofin lati gbọ ohun to fẹ ki wọn da ẹjọ le.
Ile ẹjọ naa ni ohun ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ gbe wa siwaju ile ẹjọ naa kii ṣe ohun ti wọn lee yọ ṣuti ete si nitori ọrọ abẹnu laarin abẹ orule ẹgbẹ oṣelu kan ni ko kan ile ẹjọ rara.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- Wo ọ̀rọ̀ tí TB Joshua sọ tó mú kí Youtube àti Facebook kọjú ìjà sí i?
Ile ẹjọ naa ni ẹgbẹ oṣelu APC fa Oluwarotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa kalẹ gẹgẹ bi ọmọ oye fun ipo gomina.
O ni eyi wa ni ibamu pẹlu ilakalẹ abala kẹtadinlọgọsan iwe ofin Naijiria ati abala ikọkanlelọgbọn iwe ofin eto idibo lorilẹede Naijiria.
Onidajọ Abubakar ni iwe ofin idibo ko la kalẹ pe ẹni bayi ni pato ni ki wọn gbe orukọ oludije ibo le lọwọ ati pe kẹnu maa gbofo ni ti guguru ni bi alaga ba tẹwọ gbaa.

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ naa ti ni ori ayelujara 'zoom' ni wọn yoo ti gbe idajọ naa kalẹ.
Gẹgẹ bi o ṣe jẹ oni ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu kẹrin, ọdun 2021 lawọn Adajọ ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo gomina ni ipinlẹ Ondo mu fun idajọ lori ẹjọ ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP Eyitayọ Jẹgẹdẹ pe tako esi idibo to gbe Rotimi Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ondo.
Amọṣa, ile ẹjọ naa ti ni ori ayelujara 'zoom' ni wọn yoo ti gbe idajọ naa kalẹ.
Eyi ni pe ko si ẹnikẹni ti yoo wa ninu ile ẹjọ lati gbọ idajọ naa, ori ayelujara ikansira ẹni zoom ni gbogbo awọn ti ọrs kan ninu ẹjọ naa yoo ti feti ko idajọ naa.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, igbesẹ naa waye latari iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ lorilẹede Naijiria to n lọ lọwọ lati ja fun ominira iṣuna fun ẹka eto idajọ lorilẹede Naijiria.
- Ìjọba Chad kéde kónílé-ó-gbélé aláìlọ́jọ́ lẹ́yìn ikú Ààrẹ Idriss Deby
- Mo ti fi iṣẹ́ akọ̀ròyìn sílẹ̀, iṣẹ́ ajíhìnrere Jesu ni ọpọ́n sún kàn- Kemi Olunloyo
- Wo àwọn ìkọlù àgọ́ ọlọ́pàá tó ti wáyé lẹ́kùn àríwá gúúsù Nàìjíríà ní lọ́wọ́ yì
- Àwọn Gomina ṣetán láti yọwọ́ kúrò nínú sísan owó oṣù àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ àti Adájọ́- Fayemi
- Wo àtúpalẹ̀ nkan tí òmìnira tí àwọn gómìnà fi ọwọ́ sí fún ẹ̀ka ìdájọ́ Naijiria túmọ̀ sí
Láàrin Akeredolu àti Jegede, ta ni ilé ẹjọ́ yóò gbé ipò gómìnà fún lónìí?
Eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo ti waye koda, wọn ti bura fun Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi gomina nibẹ.
Amọṣa, loni ni ile ẹjọ yoo sọ bi ọmọ yoo ṣe ṣori lori aga gomina ni ipinlẹ naa laarin gomina Rotimi Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu APC ati Eyitayo Jẹgẹdẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP.

Oríṣun àwòrán, Eyitayo jegede/twitter
Eyitayọ Jẹgẹdẹ gbe Rotimi Akeredolu lọ sile ẹjọ lẹyin ti ajọ INEC kede esi idibo naa ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.
Nibẹ ni o si ti n rọ ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo ni ipinlẹ naa lati wọgile ikede INEC naa ki o si kede oun Jẹgẹdẹ gẹgẹ bii gomina ti araalu dibo yan ni ipinlẹ Ondo.
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Makinde pàṣẹ pé kí wọ́n wó iléègbé àwọn òṣìṣẹ́ BCOS ní Ibadan?
- Tani Akeredolu tó wọlé láti tukọ̀ ìṣàkóso ípìnlẹ̀ Ondo lẹ́ẹ̀kejì yìí?
- Ààrẹ Buhari kí Akeredolu kú orííré bí ó ṣe jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò gómínà
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
Kini o le ṣẹlẹ nibi idajọ ti yoo waye lonii ni Ondo?
Pẹlu idajọ ti yoo waye loni, ọna mẹta lọrọ naa lee jasi:
Yala ki ile ẹjọ naa ni ki Gomina Rotimi Akeredolu o tẹsiwaju gẹgẹ bi gomina, tabi ko wọgile ibo naa ko kede atundi ibo.
Ohun kẹta ti ile ẹjọ naa lee pa laṣẹ ni ki o kede Jẹgẹdẹ gẹgẹ bi gomina.
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- PDP borí ìdìbò káńsù ní Rivers, AAC, SDP fárígá
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí 45 lórí ọ̀rọ̀ ìkọlù ẹgbẹ́ òkunkùn tó wáyé ní Ikẹrẹ Ekiti- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá
Eyi yoo wu ko jẹ nibẹ, Ọjọ Iṣẹgun ogunjọ, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yoo ni ami ninu eto idibo ipinlẹ Ondo.
Ni ọsẹ to kọja ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021 ni ile ẹjọ fi idajọ rẹ si lori ẹjọ naa ṣugbọn o dabi ẹni pe ayipada ti de ba eyi.
















