Ebenezer Obey: Ìdí iṣẹ́ agbẹjọ́rò tàbí dókítà ni mo rò pé mo ti máa ṣe oríire

Ebenezer Obey

Oríṣun àwòrán, @THEWILLNG

Agbabọje akọrin juju, Ebenezer Obey Fabiyi ti tẹnu bọọrọ lori idi ti iya rẹ ko fi fẹ ko ya sidi orin kikọ.

O ni iya to bi oun lọmọ ko fi tọkantọkan ro wi pe oun yoo se isẹ orin nisẹ asela.

Ninu alaye ti ilumọọka akọrin yi se fun ileeṣẹ iroyin abẹle Punch, o sọ pe dipo isẹ olorin isẹ dokita tabi agbẹjọro ni iya oun nifẹ si ki oun se.

Ko kuku si ẹni to mọ irinajo ẹda, nitori naa lo fi da bi ẹni pe iya Chief Commander fi maa n sọ fun tọsan-toru pe ko sinmi lati maa lu ilu kaakiri, ko si gbajumọ ẹkọ la ti le di dokita tabi agbẹjọro.

"Nise ni mama mi maa n sọ pe, ṣe iwọ ko fẹ soriire laye ni?"

Ebenezer Obey

Oríṣun àwòrán, @Go247B

"Bi o ba kọju mọ ẹkọ rẹ, ti o si di agbẹjọro se o mọ pe awọn eeyan yoo maa pe mi ni iya lawyer ni?"

Obey tun sọ pe mama oun yoo tun beere pe "ṣe iwọ ko nifẹ si ko ma wa ọkọ ayọkẹlẹ ni?''

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

O tẹsiwaju pe mama ko mọ ni ati pe oun ko da wọn lẹbi rara.

''Ṣugbọn nigba ti wọn ri pe isẹ orin yi lọna mi ati pe nnkan ti mo fẹ se niyẹn, wọn fi mi silẹ laaye ara mi.''

Ohun to n fa ifoya fun iya Ebenezer Obey gẹgẹ bi ohun to sọ ko sẹyin igbagbọ tawọn eeyan ni pe awọn olorin a maa mu siga, wọn a si maa mu ọti.

Lati le jẹ ki ọkan mama rẹ balẹ, Ebenezer Obey sọ pe oun ṣe ileri lati yago fun gbogbo nkan ti mama oun ko nifẹ si.

"Amọran ti wọn gba mi yi jẹ ojulowo amọran nitori nigba ti mo de oju agbami orin kikọ, gbogbo awọn nkan wọn yi ni mo ba pade."

''Pẹlu ogo lọdọ Ọlọrun mo ṣe ileri lati yago fawọn iwakiwa yi, mo si dupe pe mo se ileri yi notori ohun lo jẹ ki n yan kin yanju lonii niyẹn.''

Àkọlé fídíò, hhhhhh