Ikere-Ekiti cult clash: Èèyàn mẹ́fà kú nínú ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn, ọ̀rọ̀ di ẹni orí yọ ó dilé ní Ikẹrẹ-Ekiti

Ami idanimọ ẹgbẹ okunkun

Èèyàn mẹ́fà kú nínú ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn , ọ̀rọ̀ di ẹni orí yọ ó dilé ní Ikẹrẹ-Ekiti

Ọrọ di bo o lọ, yago fun mi nilu Ikẹrẹ-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lọjọ Isinmi, lasiko ti ija ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Iroyin ta a gbọ ni pe alẹ ọjọ Satide ni wahala naa ti bẹrẹ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan yinbọn pa ọkunrin kan ti wọn pe ni Ojuale.

A gbọ pe nitosi Gbọngan ilu naa to wa ni agbegbe Odo Oja ni wọn ti yinbọn pa Ojuale, ti iroyin sọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni oun naa.

Awọn iwe iroyin abẹle sọ pe botilẹ jẹ pe ọmọ ilu Ikẹrẹ ni Ojuale, ṣugbọn ilu Port Harcourt lo n gbe.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ayẹyẹ igbeyawo ọrẹ rẹ kan la gbọ pe o wa fun, ki awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to o yinbọn pa.

Ko pẹ lẹyin ti wọn pa Ojuale, ni awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ naa tu jade pẹlu oriṣiriṣi nkan ija oloro, ti wọn si bẹrẹ si ni kọju ija si awọn olugbe ni agbegbe naa.

"Bẹẹ ni wọn n yin ibọn lakọlakọ, eyi to mu ki awọn araalu o sa asala fun ẹmi wọn.

Nigba to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

O ni ṣugbọn, ọwọ ti tẹ afurasi 45 lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti wa ni agọ ọlọpaa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Bakan naa lo sọ pe awọn ọlọpaa ṣi wa ni agbegbe naa lati tẹsiwaju pẹlu eto aabo titi ti alaafia yoo fi jọba.

A gbọ pe awọn ara ilu Ikẹrẹ ti bẹ ijọba ipinlẹ Ekiti, lati tọpinpin bi ija laarin awọn ẹgbẹ okunkun ṣe n waye nigba gbogbo ninu ilu naa.

Lori eyi, Abutu sọ pe lootọ ni, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti mu awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun kan, ṣaaju ikọlu to tun waye ni ọjọ Satide.

Ninu iṣẹlẹ to waye lọjọ Satide mọju ọjọ Aiku yii, iroyin ti ao ti le fidirẹmulẹ sọ pe ko din ni eeyan mẹfa to kú.