Naira Marley: Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley yóò ṣe bá ọ bẹ̀bẹ̀ kí ó tó wọlé

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Instagram/@nairamarley

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja akọrin, Azeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley ti sọ pe oun ni yoo kọkọ wọ ọrun, tako igbagbọ awọn eeyan kan.

Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ lo ti sọ pe oun ko ni nkankan ṣe pẹlu ọrun apadi, nitori pe oorun to n mu ni aye gan-an ju ti ina jaanamọ lọ.

O ni aanu oun ṣe awọn eeyan to ma n sọ pe ẹnikan lo ma a kọkọ lọ si ọrun apadi.

O ni "emi ati Ọlọrun mọ ibi ti a di ibaṣepọ wa si. Aanu ẹ ṣe mi."

Naira Marley sọ pe oun lo ma a ba awọn eeyan naa bẹbẹ ni ẹnu ọna ọrun, ki wọn o to o le wọle.

"Bi mo ṣe ma a bayin bẹbẹ niyẹn lẹnu ibode ọrun pe Ọlọrun, ẹ jọ ẹ jẹ ki eleyi wọle. Mo mọ eleyi ri, Mallam ni, ẹ jẹ ko wọle. Bi mo ṣe ma bayin bẹbẹ niyẹn."

Akọrin naa to fi lawani bo ori lo wa ninu ọkọ pẹlu awọn kan to ṣe e sẹ ko jẹ isọmọgbe rẹ, ti ọkan lara wọn si mu tẹsibiyu dani.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Lati igba ti awẹ Ramadan ti ọdun 2021 ti bẹrẹ lo dabi ẹni pe gbajugbaja akọrin naa n kọ awọn ọrs ẹsin lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ninu ọrọ kan to kọkọ fi si ori ayelujara rẹ ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, Naira Marley ṣe atupalẹ ati itọni lori bi awọn musulumi ṣe le ka Kuraani tan laarin ọgbọn ọjọ ti Ramadan yoo fi waye.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ọpọ eeyan si lo jẹ iyalẹnu fun pe iru awọn ọrọ 'iwa mimọ' bẹẹ le jade lẹnu Marley, ti awọn eeyan kan gbagbọ pe ẹlẹṣẹ ni.

Eyi ko ṣẹyin iru awọn orin ati aṣa to ma n da, eyi ti awọn eeyan ti tọka si ni ọpọ igba pe ko bojumu.

Àkọlé fídíò, hhhhhh