Infidelity in marriage: Wo àwọn àmì mẹ́jọ ti o lè fi mọ̀ pé ọkọ tàbí aya rẹ ti ń ṣe ìta

Lootọọ lawọn eeyan maa n sọ pe, ọrọ ifẹ bi adanwo lo ṣe ri.
Idi ni pe ifẹ lo mu eeyan meji gbe inu ile kan naa, ifẹ naa ni kii jẹ ki eeyan kiyesi aida.
Ifẹ dun bi oyin, koda iwe mimọ gan an jẹri pe ifẹ ni akoja ofin.
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
- Wọ́n ti tú akọ̀ròyìn BBC, Girmay Gebru sílẹ̀ kúrò látìmọ́lé ní Tigray
- Ayé àkámarà! Liverpool laná ní Anfield, Chelsea pa òkúta sí gaàrí wọn
- Áwa Hausa tá a wà l'Ogbomoṣọ ti di Yorùbá- Oba Haruna Sabo Ogbomoso
- Mò ń bẹ Ọlọ́run pé kí ìdàgbàsókè Nàíjíríà ṣojú ẹ̀mí mi - Obasanjo
Ṣugbọn bi ifẹ ṣe dun yungba to, to dun ju oyin lọ, ti ẹtan ba ti wọ ọ, ina ifẹ yoo bẹrẹ si ni jo ajorẹyin.
Eyi lo difa fun awọn onimọ nipa ọrọ ifẹ laarin lọkọ laya to sọ nipa awọn nnkan to maa n ṣẹlẹ gbara ti ọkunrin tabi obinrin ba ti bẹrẹ si ni ṣe ita.
Wọnyii ni koko mẹwaa to maa n ṣaaba waye ti ọkan ninu awọn ololufẹ meji ba ti bẹrẹ si ni ṣe ita.
1. Irọ pipa ati fifi ọrọ pamọ
Awọn onimọ nipa ọrọ ifẹ laarin lọkọ laya sọ pe ẹni to ba ti ri ibi ti ọkọ tabi iyawo rẹ ti pa irọ fun ẹlomiran gbọdọ mọ pe o si to maa parọ foun naa.
Wọn ohun to le mu ki ọkọ tabi iyawo parọ fun ẹlomiran naa ni yoo jẹ ko parọ fun aya ati ọkọ rẹ pẹ.
Eleyi to tun dabi rẹ ni ki ọkọ tabi iyawo maa fi ọrọ pamọ fun ẹnikeji rẹ.
2. Ti ọrọ ọkọ tabi aya rẹ ba ti n taṣe
Ko nira lati sọ fun ololufẹ rẹ pe o nifẹ rẹ, ṣugbọn ohun to nira ni ṣiṣe ohun ti o fi ẹnu ara rẹ sọ,
Yoruba bọ, wọn ni ẹnu dun ro ẹfọ, agada ọwọ ṣee bẹgi.
Ti o ba ti de wi pe ọrọ ololufẹ rẹ ti n taṣe ara wọn, ọkan lara ami wi pe o ti n ṣe ita niyẹn.
3. Ikuna lati mu ileri ṣẹ
Ileri ṣiṣe wọ pọ laarin ololufẹ meji papaa julọ nigba ti ina ifẹ ba si n jo bula bula laarin wọn.
Ṣugbọn ọtọ ki eeyan ṣe ileri, ọtọ si ni ko mu ileri ọhun ṣẹ.
Ti ololufẹ rẹ ba ti bẹrẹ si ni kuna lati mu ileri rẹ ṣẹ, mọ wi pe o ṣeeṣe ki o ti maa ṣe ita.
Maa ṣe ilrei ohun ti o ko ni ṣe fun ololufẹ rẹ, ṣe bi o ti mọ, ẹlẹwa ṣapọn.
4. Aiwaye lati jọ wa papọ
Eyi maa n ṣaaba ṣẹlẹ ti awọn ololufẹ mejeeji ba n ṣiṣẹ ti ko fun wọn laye.
Ṣugbọn ko si bi ọwọ eeyan ṣe le di to ki o maa wa aye fun ohun to ba fẹ ṣe.
Otitọ to wa nibẹ ni pe ti ololufẹ rẹ ba nifẹ rẹ de ọkan ni tootọọ, yoo waye lati wa papọ pẹlu rẹ.
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
- Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbọn AK-47
- Ìyá Leah Sharibu ké gbàjarè sí ìjọba Buhari
- Sanwo-Olu àti Osinbajo ẹ gbà mí o, mo ti jẹ gbèsè - Iyabo Ojo figbe ta
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
5. Aifọkan si ọrọ ajọsọpọ
Ti ifẹ otitọ ba wa laarin lọkọ laya, ọkan awọn mejeeji ma nibi ọrọ ti wọn ba n sọ lai fiye si ibo miran.
Ko si ohun ti eeyan le maa ro to le mu ki eeyan maa fi ọkan si ohun ti ololufẹ rẹ ba n sọ.
Afaimọ ko maa jẹ pe ọkunrin tabi obinrin ti n wo ita to ba ti di pe ko fi ọkan si ọrọ ti wọn ba n jọ sọ pọ mọ.
6. Aini ifarada fun ololufẹ ẹni
Ifarada fun ololufẹ ẹni wa lara ọkan pataki ninu abuda ifẹ.
Ẹnikẹni ti ko ba ṣetan lati ni ifarada fun ololufẹ rẹ, o ṣeeṣe ko jẹ pe o ti ni oju miiran nita ni.
- UNO bẹnu àtẹ́ lu ìdàdúró Onnoghen
- INEC: Kò sí ìká tí o kò lè fí dìbò, ṣáà tí tẹ̀ ẹ́ sójú ẹ dáadáa
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Wo ohun táwọn aṣọ́gbó ń kojú pẹ̀lú Ìnàkí tí wọ́n ń ṣọ́
7. FIfi aṣiri pamọ
Onimọ kan nipa ọrọ awọn ololufẹ sọ pe awọn ololufẹ ti wọn ba n ṣe ita lo maa n fi aṣiri pamọ fun ara wọn.
O ni iru wọn ni wọn kii jẹ ki ololufẹ wọn mọ awọn ẹbi wọn ni kiakia.
Ọkunrin tabi obinrin to n ṣe ita lo maa sọ pe ẹlomiran ko gbọdọ mọ nipa ibaṣepọ to wa laarin awọn mejeeji.
8. Ede-ai-yede gbogbo igba
Awọn ololufẹ ti wọn n ba ni ede-ai-yede n gbogbo igba n fihan pe ko si ifẹ otitọ laarin awọn mejeeji.
O yẹ ki lọkọ laya tabi ololufẹ meji le yanju ede-ai-yede to ba ṣẹlẹ laarin wọn ni itubi inubi.
Ṣugbọn to ba ti di ija lonii ija lọla, a jẹ wi pe ejo ti lọwọ ninu niyẹn.



















