Animal, DR Congo's Virunga National Park: Wo ohun táwọn aṣọ́gbó ń kojú pẹ̀lú Ìnàkí tí wọ́n ń ṣọ́

Oríṣun àwòrán, AFP
Wo ohun táwọn aṣọ́gbó ń kojú pẹ̀lú Ìnàkí tí wọ́n ń ṣọ́
Iṣẹ ni iṣẹ n jẹ.
Didaabo bo igbo Oba Virunga National Park lẹkun ila oorun orilẹ-ede Democratic Republic of Congo jẹ iṣẹ.
Ninu ọgba yii ni awọn okundun ọmọ ọdẹ ti n da ẹmi awọn inaki ori apata legbodo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi lo si bi iṣẹ to le diẹ ti awọn eeyan kan n ṣe.
Koda bi eniyan ba pee ni ọkan lara awọn iṣẹ to le julọ lagbaye, eeyan o jayo pa o.
Laarin osu mejila sẹyin,ko din ni ogun oṣiṣẹ igbo ọba naa tawọn eeyan kan ti pa.

Ni ọsẹ to kọja lawọn kan si n fi ẹsun kan awọn ikọ agbebọn kan nibẹ pe wọn ṣekupa aṣoju ijọba orilẹ-ede Italy ni DR Congo ti wọn si tun pa alaabo rẹ ati dẹrẹba ninu igbo yii kan naa.
Lori awọn ẹgbẹrin ẹṣọ igbo ọba naa ti iwadii sọ pe oun lo pẹ julọ ti o si tun tobi julọ nilẹ Afirika, Emmanuel de Merode ṣalaye pe "sisọ awọn Igbo yii kun ara ifaraenijin ti le ju lati ṣe lagbaye"

Oríṣun àwòrán, Alamy
Iwon bi ẹgbẹrun maili ni fifẹ ati gigun ni, oniruuru ohun abẹmilo si kun ibẹ titi kan awọn oke riru, adagun omi nla, Igbo ati awọn oke nlanla.
Ñkan bii ọgorun ọdun sẹyin ni wọn ṣe agbekalẹ igbo ọba yii lati daabo bo awọn inaki ori apata to wa nibẹ.
Ni bi a ṣe n sọrọ gii, awọn ẹya I aki yii to wa lagbaye ko ju ẹgbẹrun kan lọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Amọsa, iroyin ayọ ibẹ ni pe iye awọn inaki yii tin pọsi nitoripe wọn ti n bimọ sii .

Oríṣun àwòrán, Getty Images














