Eniola Badmus: Gbajúgbajà òṣèré tíátà di aṣojú LAWMA ní ìpínlẹ̀ Eko

Eniola Badmus

Oríṣun àwòrán, Instagram/Eniola Badmus

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja oṣere tiata, Eniola Badmus ti di aṣjoju ajọ LAWMA to n ri si gbigba ipinlẹ Eko mọ.

Eniola fi oriṣiiriṣii fọto bi wọn ṣe sọ di aṣoju ajọ LAWMA soju opo Instagram rẹ.

Gbajugbaja oṣere naa ṣalaye pe aṣọ ti oun wọ lọ si ibi ayẹyẹ ''Headies award'' lo sun oun de bi ibi ire bayii.

''Ori ayelujara mi titi lori aṣọ ti Eniola wọ lọ si ibi ami ẹyẹ Headies Award niluu Eko, ọpọ lo sọ pe mo da bi oṣiṣẹ LAWMA pẹlu aṣọ ti mo wọ lọ si ibi ayẹyẹ naa.

Mo gbagbọ pe ifẹ tawọn eeyan ni si mi lo jẹ ki wọn sọ pe mo dabi oṣiṣẹ LAWMA to n ko idọti loju titi.

Ṣugbọn ọrọ ti wọn sọ ni bii oṣu meji sẹyin bayii ti ja si oriire fun mi.

Nkan iwuri lo jẹ fun mi pe mo ti di aṣoju ajọ LAWMA nipinlẹ Eko.

Mo ṣetan lati lo ẹbun ti Eledua fun mi lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ LAWMA,'' Eniola ṣalaye.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Eniola dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Eko fun anfaani ti wọn fun mi lati ṣiṣẹ pọ gbe ipinlẹ Eko ga si.

O tun dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ bakan naa, o rọ wọn lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba gbe ipinlẹ Eko ga si.

Eniola ti darapọ mọ Woli Arole, Bolanle Ninalowo ati Tobi Bakre gẹgẹ bi awọn oṣere to jẹ aṣoju ajọ LAWMA nipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Ọkọ àti ìyàwó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tani yóò wọlé nínú PDP tàbí APC