Bolanle Ninalowo: Bolanle Ninalowo sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tó fi kúrò nínú Islam di Krístẹ́nì

Bolanle Ninalowo

Oríṣun àwòrán, iamnino_b/Instagram

Yoruba ni iriri aye kii ti ni titi, ko ti ni pa, ọgbọn naa ni yoo fi kọ ni.

Bẹẹ si ni bi iriri aye ba de ba ẹ́da kan, awọn ọ̀na ti yoo gba yọ kuro nibẹ ni yoo maa wa lasiko naa, ki ọkan rẹ le balẹ.

Ohun to sẹlẹ ree pẹlu gbajugbaja oṣere tiata Yoruba kan, Bolanle Ninalowo, ẹni to ṣalaye idi to ṣe fi ẹsin Islam silẹ di ọmọlẹyin Kristi.

Ninalowo sọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan to se lori ẹrọ Instagram.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bo ti salaye, idile musulumi gidi ni wọn bi Ninalowo si, amọ o ṣalaye pe oun yipada sí Kristẹni nitori iriri kan ti ko dara ti oun ni.

Ninalowo ti orukọ musulumi rẹ n jẹ Azeez sọ pe, awọn obi oun, to fi mọ awọn ẹbi ti wọn jẹ musulumi, ko le gba oun nigba ti iṣoro de.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Gbajumọ oṣere naa ni iwe mimọ Bibeli nikan lo gba oun ninu iṣoro naa, eyi ti ko salaye rẹ faraye.

O ni lati igba naa, ni oun ti n ka Bibeli nigba gbogbo, ti oun si di ọmọlẹyin Kristi bi o tilẹ jẹ pe oun kii lọ sile ijọsin rara lati jọsin.

"Ni kete ti mo gba bibeli mu, o di iwe to n tọ mi sọna ni igbesi aye mi lati igba naa," Ninalowo lo sọ bẹẹ.

Arẹwa ọkunrin oṣere naa ni, oun ko le gbagbe bi oun ti ri ojutuu sí iṣoro ti o n ba oun finra nigba naa ninu Bibeli.

Bolanle Ninalowo

Oríṣun àwòrán, iamnino_b/Instagram

Ninalowo sọ pe ẹẹkan pere ni oun bawọn jọsin ni sọọsi ri sugbọn o salaye pe ojoojumọ ni oun maa n ka Bibeli ni akaye.