Famous Street in Lagos: Lára àwọn àdúgbò tó gbajúmọ̀ l‘Eko ní Bourdillion wa

Oríṣun àwòrán, Google
Awọn adugbo nla nla ati opopona wa ni ilu Eko, eyi to jẹ ko jẹ ilumọọka kaakiri orilẹede Naijiria, to fi mọ awọn alejo lati oke okun.
Awọn adugbo yii ti wa fun ọpọlọpọ ọdun, ti awọn eniyan si mọ wọn fun agbegbe igbafẹ, iṣẹ ati ibi ti ọrọ aje wa.
Awọn agbegbe yii wuyi to jẹ wi pe yoo mu ki eniyan fẹ lọ sibẹ lati wọ bi o ṣe ri.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Wo ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tí Aláàfin ṣe láti àádọ́ta ọdún tó ti jọba
- Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
Ti o ko ba tii de ilu Eko ri, wo awọn adugbo mẹwaa ti o yẹ ki o mọ nipa awọn ibi to gbajumọ julọ nipinlẹ Eko.
Broad Street

Oríṣun àwòrán, Others
Agbegbe erekusu Eko, ti ọpọ eeyan mọ si Lagos Island ni adugbo Broad street wa, to si jẹ ọkan ninu awọn adugbo to ti wa fun ọpọlọpọ ọdun lorilẹede Naijiria.
Ohun ti o wọpọ ni agbegbe yii ni awọn ileeṣẹ nla nla, ile ifowopamọsi, awọn ile alaja nla nla ati awọn ile awoṣifila lo wọpọ ni adugbo yii.
Awọn eniyan ti wọn wa ni agbegbe yii ni awọn oniṣowo, oṣiṣẹ banki ati awọn ti wọn n jẹun ni awọn ile ounjẹ igbalode to wa ni bẹ.
Agbegbe Broad Street yoo jẹ ki o ri awọn aworan ati iriri to pọ nipa Lagos Island.
Allen Avenue

Oríṣun àwòrán, Others
Adugbo Allen Avenue jẹ adugbo to gbajugbaja ni agbegbe Ikeja ni ipinlẹ Eko.
Adugbo ti awọn ọlọla n gbe ni, ti ọpọlọpọ ofisi si wa nibẹ to fi mọ awọn ile itaja nla nla.
Adugbo Allen Avenue yii jasi awọn opopona to gbajumọ bi Opebi Road ati Adeniyi Jones.
Ti o ba si fẹran ounjẹ awọn Chinese, ti o ba ti de Allen Avenue, ọpọlọpọ ibi ti wọn ti n ta ounjẹ igbalode yii ni o ma a ri.
Opopona Bourdillion

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye Instagram
Lara awọn adugbo to gbajumọ julọ ni Ikoyi nilu Eko ni opopona Bourdillon wa.
Ti wọn ba si darukọ Ikoyi nilu Eko, ohun ti yoo kọkọ wa si ọkan ọpọ eeyan, paapaa awọn oloselu ni Bourdillion.
Idi ni pe agbegbe yii ni agba oloselu nni, Asiwaju Bola Tinubu n gbe, ti ọpọ awọn oloselu yika Naijiria si maa n ya lọ sibẹ fun ipade wọn.
Bakan naa ni awọn eeyan to nilo iranlọwọ kan tabi omiran kii fi Bourdillion sere nitori o da wọn loju pe oke isoro wọn yoo di pẹtẹlẹ nibẹ.
Iwọ to ba si wa silu Eko, to ba tii de Bourdillion, tete yara lọ mọ ibẹ.
Toyin Street

Oríṣun àwòrán, Google
Adugbo miran to tun gbajugbaja ni ipinlẹ Eko ni Toyin Street, ti ko jina si agbegbe Allen Avenue ni opopona Opebi Road.
Ohun to dara nipa adugbo yii ni wi pe ile itura igba lode lorisirisi lo wa ni ibẹ, awọn ile igbafẹ pẹlu orin aladun ko gbẹyin nibẹ.
Adugbo yii wọpọ fun igbafẹ ni alẹ nitori orisirisi ounjẹ, oti ati orin aladun ni yoo ma a da eniyan laraya.
Bẹẹ si ni awọn eniyan ma n wa si adugbo yii lati wa jẹ Pizza, ibẹ si awọn alẹjọ lati ilẹ okeere ti ma n lọ lati lọ gbadun.
Ademola Adetokunbo Street

Oríṣun àwòrán, Others
Arakunrin Sir Adetokunbo Adegboyega Ademola ni wọn fi orukọ adugbo yii sọ ori rẹ.
Oun si ni ọmọ Adajọ Agba patapata lorilẹede Naijiria tẹlẹri ri, Ọmọọba Alake ti ilu Ẹgba, Ladapọ Ademola Keji.
Ti o ba rin ni adugbo yii, o ma rin awọn ile alaja lorisirisi ti awọn eniyan lo fun ileeṣẹ, ile itaja ati ile ifowopamọsi.
Bakan naa ni awọn eniyan ma n dara lorisirisi ni adugbo naa.
Ozumba Mbadiwe Avenue

Oríṣun àwòrán, Google
Agbegbe Victoria Island ni Ozumba Mbadiwe Avenue wa ni ipinlẹ Eko, ti o si jẹ agbegbe awọn olowo.
Awọn ile igbafẹ nla nla, ile itura ati adugbo to gbamuṣe lo wa ni Ozumba Mbadiwe Avenue.
Ohun ti ọpọlọpọ eniyan mọ agbegbe yii fun ni ile igbe oni ẹgbẹrun mẹrin ''4000 Flats'' ti awọn eniyan n gbe.
Adeola Odeku Street

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹni to ba wa si ilu Eko fun igba akọkọ yoo fẹran adugbo Adeola Odeku Street fun bi o ṣe gbayi pẹlu ọpọlọpọ eniyan.
Adeola Odeku Street to wa ni agbegbe Victoria Island jẹ agbegbe ti o wuyi fun awọn eniyan gbogbo.
Ati awọn oṣiṣẹ ofisi to fi mọ awọn oniṣowo nla nla, awọn to n ta iwe iroyin pẹlu awọn to n ta esọ.
Bakan naa ni awọn ileeṣẹ nla nla, banki ati awọn ile itaja ko gbẹyin nibẹ.
Ogunlana Drive, Surulere

Oríṣun àwòrán, Google
Agbegbe Ogunlana Drive jẹ ọkan lara awọn adugbo ilumọọka ni Surulere ni ipinlẹ Eko.
Ibẹ ni awọn ileeṣẹ nla nla wa, pẹlu awọn ofisi, ile ounjẹ loriṣiriṣi wa nibẹ.
Awọn ile aye atijọ pẹlu ti igbalode lo wa ni ibẹ.
Adeniran Ogunsanya Street

Oríṣun àwòrán, Google
Adugbo Adeniran Ogunsanya Street jẹ ọkan lara awọn adugbo to wọpọ ni agbegbe Surulere, ti awọn eniyan si ma n lọ sibẹ nitori ọja igbalode nla nla to wa nibẹ.
Awọn ọlọla ati awọn to ku diẹ ka to ni wọn n pejọ sibẹ lati ra ọja.
Bakan naa ni awọn ile itaja, ile ounjẹ lorisirisi wa nibẹ.
Bode Thomas Street

Oríṣun àwòrán, Google
Adugbo Bode Thomas Street jẹ ọkan lara awọn adugbo ti o gbajumọ julọ ni agbegbe Iponri ni Surulere.
Orukọ oloṣelu to gbajugbaja ni orilẹede Naijiria,Bode Thomas ni wọn fi sọ ori rẹ.
Ọpọ̀lọpọ ohun igbalode ati awọn ile to buyi lo wa ni agbegbe naa.
Isaac John Street, GRA

Oríṣun àwòrán, Google
Adugbo Isaac John Street wa ni agbegbe ijọba ti wọn n pe ni GRA ni agbegbe Ikẹja ni ilu Eko.
Adugbo yii ọpọlọpọ nkan to rẹwa fun oju ati awọn eniyan lati ri fun alejo ati onile.
Bakan naa ni awọn ile igbafẹ ati ile itura lorisirisi wa nibẹ.

















