Ṣé lóòtọ́ ni Eko dá yàtọ̀ l'Áfíríkà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọle orukọ ṣe ṣe pataki lorilẹede Naijiria ti wọn si maa fi n da awọn to di ipo nla nla mu mọ.
Ni ti aaye, ilu Eko ni ipinlẹ to kere ju ni Naijiria ṣugbọn nkankan ti ko ni ninu aaye yii, o ti fi di i ninu ara rẹ. Ni kete ti ẹ ba ti jade ninu papakọ ofurufu Murtala Muhammed lẹ o ti maa ri agbara to gbilẹ ninu ilu yii.
Asa jijẹ oniṣẹ ara ẹni
Pẹluu wi pe wọn ti fi ilu Abuja rọpo rẹ gẹgẹ bii olu ilu orilẹede Naijiria lọdun 1991, oun ṣi mi wọn n pe ni ilu nla Naijiria to ṣe pataki ju - ilu ti wọn ti n ja a mọra wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo ọmọ Naijiria jakejado orilẹede yii ati pẹlu oniruuru iṣẹ ti wọn yan laayo lo maa n tu kẹti kẹti lọ si ilu Eko tii adape orukọ rẹ n ṣe "Ibudo Titayọ" lati wa bi ayanmọ wọn yoo ṣe yan didara.
Ilu yii ni ọpọlọpọ ileeṣẹ kalẹ si latori awọn ẹka ileeṣẹ t'ọjọ ori ti lọ lori wọn bii awn ileeṣẹ to n pese atawọn ile ifowopamọ titi dori awọn to ṣe tuntun bii ti imọ ẹrọ. Ibẹ naa ni ibudokọ oju omi orilẹede yii meji pataki fi ṣe'le ti ọpọlọpọ owo si ti ngberi soke fun katakara latori iwe, iṣẹ na to fi mọ oriṣiriṣi ẹrọ amayedẹrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"L'Eko, a ni aṣa didi oniṣẹ ara ẹni lọna to lagbara tẹ o si le dede ri nibomiiran," Funmi Oyatogun to jẹ oludasilẹ TVP Adventures ti wọn ti n ṣe irinajo igbafẹ sọ.
O ni "l'Eko, gbogbo eniyan lo n gbiyanju ati kọ ohun to kan, ati wa ojutu si iṣoro to ba tun yọju, pipese ohun elo tuntun sita gbogbo eyi si lo n fi kun ijafafa ati agbara ilu nla naa".
Ẹmi Pọpọṣinṣin ati wọ sibi-sọhun
Ni Eko, atẹgun ib a maa ṣe bi ẹni nipọn loju ofurufu pẹlu ariwo. Afi bii orin adakọ ni fifọn awọ́n ọkọ, ẹrọ amunawa atawọn eeyan to n ba iṣẹ oojọ wọn kiri yala pẹlu ẹsẹ, gigun kada, ọkọ tabi awọn bọọsi danfo to pupa rusu rusu to ti di ami idamọ ilu nla naa tabi ti awọn bọọsi gigun ti igbalode, BRT. Gbogbo igba shaa lawọn ara Eko to to miliọnu mọkanlelogun eniyan n wa lọna.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii afojusun fi han pe onka iye eeyan to wa ni Eko yoo to pọ sii kiakia ti yoo si fẹrẹẹ to miliọnu mejidinlaadọrun titi ọdun 2100 eyi to n da kun aisi awọn nkan amayerọrun ṣugbọn ni ti wọn, awọn ara Eko ko ki n kaarẹ.
"Awọn eeyan to wa l'Eko da yatọ, ni Chiamaka Ọbuekwe to jẹ oludasilẹ founder of The Social Prfect Tours. ẹmi pọpọṣinṣin wa nibẹ. Wọn lagbara, wọn ja fafa wọn si jẹ olufẹ faaji ati akonimọra"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun idi eyi, kii ṣe ibi kan to maa n dede ti eeyan sinu wahala bọ sibi-sọhun rẹ. Ẹmi iyara wa nibẹ ati iwa keeyan tete maa le fara mọ ibi kan ki o si le tete ba Eko yi pẹlu ohunkohun to ba gbe wa.
'Olu Ilu Aṣa'
Ṣugbọn kii ṣe ọrọ katakara nikan la mọ Eko si, o ti pẹ ti wọn ti n ri Eko gẹgẹ bii olu ilu Naijiria fun aṣa eyi si jẹ iyi to ti n fun Eko lagbara papaa ninu ẹka sinima, oge ati ori kikọ ni Naijiria.

Nollywood, ileeṣẹ fiimu to tobi ju lagbaye ni olu ileeṣẹ rẹ nibi bẹẹ si ni to ba ti n sun mọ ipari ọdun ni ọpọlọpọ afihan nkan idaraya maa n jẹ jade gidi gan ti Eko si maa n jẹ ibudo fun ọpọlọ́pọ ayẹyẹ mọ eto.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Oun ṣi ni ilu to ja fafa ju ti mo ti ri nilẹ adulawo, Oyatogun ni oun lo lagbara ju ninu aṣa, ṣiṣe ayẹyẹ ati inawo bi wọ́n si ṣe maa n ṣe ajọyọ da yatọ si awọn ilu miiran ni Afirika.
"O ò lè wà ni Eko kí ayé sú ọ "
Inawo tun jẹ ohun kan ti wọn mọ Eko fun ati igbe aye ibẹ laṣalẹ, ara ọtọ ni. Ko si igba ti kii si ode ariya kan tabi omiran lati lọ, ile ijo, atawọn ibudo igbadun ko gbẹyim plu oniruuru awọn gbajugbaja olorin bii Burna Boy, Wizkid, Orin Fela Kuti abi meloo lẹ fẹ ka - gbogbo rẹ lẹ o ri ni Eko.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obuekwe gba pe "O o le wa ni Eko ko su ẹ lai lai"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣugbn bi o ko ba kii ṣe ni to fẹran ode ariya, to o si nifẹẹ aye kole kole, iru ohun too fẹ naa wa l'Eko. Okun, ibi iṣere, ibudo igbafẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images













