Yollywood: Wo àwọn òṣèré Yoruba tí wọ́n bí ní ọjọ kan náà
Njẹ ẹyin mọ wi pe ọjọ kan naa ni wọn bi Mustapha Solagbade,Mercy Aigbe, Moyo Lawal ati Ibrahim Yekini?
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Ọjọ kini, Osu Kini, ọdun 1978 ni wọn bi gbajugbaja oṣere, Mercy Aigbe ni ipinlẹ Edo. Yato si iṣẹ oṣere, Mercy tun n ta awọn ohun ẹsọ ara gbogbo.
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Ibrahim Yekini ti awọn eniyan ma n pe ni Itẹlẹ ni wọn bi ni ọjọ Kini, Osu Kini ọdun 1980 ni agbeegbe Bariga, ni ilu Eko. O ti ba gbajugbaja oṣere bii Odunlade ADEKOLA, Tunde Usman, Kelvin Ikeduba ati Femi Adebayo laarin ọpọ awọn osere miran.
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Mustapha Solagbade jẹ ilumọọka oṣere, ti wọn bi si agbeegbe Ebute Mẹta ni ipinlẹ Eko, ni ọjọ Kini, Osu Kini, ọdun. Oun si ni akọbi awọn obi rẹ.
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Ọjọ Kini, Osu Kini bakan naa ni wọn bi Moyo Lawal ti o ti kopa ninu ọpọlọpọ awọn ere agbelewo. Awọn osere bii Iyabo Ojo, Biodun Okeowo ati bẹẹ lọ ni wọn ti jọ kopa ninu ere.
Ọjọ Karun un, Osu Keji, ọdun ni wọn bi Saheed Balogun ati Faithia Williams ti wọn ti figbakan jẹ lọkọlaya , ki wọn to tuka.
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Ọjọ Karun un, Osu Keji, ọdun 1969 ni wọn bi gbajugbaja oṣere Fathia Akorede Adunni Balogun ti wọn bi ni agbegbe Opara
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Bakan naa ni Saheed Akolawole Alabi Balogun ti o jẹ agbaọjẹ ninu ere amuludun ni Naijiria ni wọn bi ni ọjọ karun un, ọdun 1966 ni ipinlẹ Kwara amọ ti awọn obi rẹ wa lati ipinlẹ Oyo.
Ninalowo Bolanle ati Olaitan Sugar jọ kọwọrin wa ni ọjọ kan naa ni:
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Ọjọ Keje, Osu Karun un, ọdun 1980 ni wn bi gbajugbaja oṣere Bolanle Ninalowo ti wọn bi ni agbeegbe Ikorodu ni ilu Eko si idile Alhaji Jamiu Ninalowo ati Alhaja Ninalowo
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Obinrin oṣere arẹwa, Olaitan Sugar ni wọn bi ọjọ keje, osu karun un, ni o wa lati Ile Ifẹ. O darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Naijiria ni ọdun 2008. Ninu ere to ṣe ti wọn pe akọle rẹ ni Olaitan Sugar ni wọn ti bẹrẹ si ni pe e ni orukọ naa
Bakan naa ni Gbajugbaja osere Bimbo Osin ko danikan waye o, nise lo mu Doris Simeon naa dani ni Ọjọ Kẹrinlelogun, ni Osu Keje.
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Awẹlẹwa oṣere, Bimbo Osin ni wọn bi ni Ọjọ Kẹrinlelogun, ọdun 1971 ni ilu Ondo, ti o si jẹ ọmọ kẹfa ninu ẹbi marun un.
Oríṣun àwòrán, Instagram
Àkọlé àwòrán, Doris Simeon to jẹ oṣere to gbajugbaja ni wọn bi ni ọjọ kẹrinlelogun,Osu Keje ni agbeegbe Ọjọta ni ipinlẹ Eko. Bakan naa ni Doris n ṣe ere Yoruba ati Ede Gẹẹsi.