Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń ṣe agbódegbà fún àwọn agbésùmọ̀mí ní Zamfara

Soldiers

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ipinlẹ Zamfara ti sọ pe ọwọ ti tẹ awọn ọmọ ogun meje to n ṣe agbodegba fun awọn agbesumọmi ni ipinlẹ naa.

Ikede naa lo waye nibi ipade awọn akọroyin kan ti wọn ṣe nileeṣẹ to n ri si ọrọ to n lọ ati ọrọ abo.

Wọn ni awọn afurasi naa jẹwọ pe lootọ ni wọn ṣe ohun ti wọn fi ẹsun rẹ kan awọn, bẹ si ni awọn n fun awọn agbesumọmi ni awọn iroyin idankọnkọ nipa ileeṣẹ ologun.

Atẹjade naa ni ọkan ninu awọn eeyan ọhun jẹwọ pe oun maa n ko aṣọ ati irinṣẹ ologun fun awọn agbesumọmi naa.

O fikun pe N100,000 ni wọn fun oun lati ṣe iranwọ fun ẹgbẹ agbesumọmi.

Lasiko ti wọn mu, wọn ba aṣọ awọleke ti ọta ibọn kii wọ mẹsan an lọwọ rẹ, aṣọ ọmọ ogun mẹrin ati kaadi idanimọ ọmọ ogun kan.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Baka naa ni ọwọ tun tẹ dokita kan ti wọn ba ohun ija awọn ọmọ ogun lọwọ rẹ.

Atẹjade naa fi kun pe awọn ti ọwọ tẹ yii n ṣapẹrẹ ọrọ ti goimina ipinlẹ naa sọ ṣaaju pe, ẹnu yoo ya awọn arralu lẹyin ti aṣiri awọn to wa nidii iṣẹrubalu ba tu tan.

Lẹyin naa ni ijọba Zamfara rọ Aarẹ Muhammadu Bauhari lati fi alekun ọmọ ogun ṣọwọ si ipinlẹ ọhun gẹgẹ bii ileri to ṣe fun wọn ṣaaju.

Lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano fi ṣikun ofin mu ọkunrin kan to n ta alupupu fun fun awọn janduku.

Agbenusọ ileeṣẹ naa, DSP Abdullahi Haruna Kiyawa ni ọkunrin naa jẹwọ pe oun ti ta alupupu bii ọgọrun fun awọn agbesumọmi ọhun ni obitibiti owo.