Bola Tinubu: Mo gbóṣùbà fáwọn tó ń pín ìrẹsì fún mẹ̀kúnnù pẹ̀lú àwòrán mi

Apo raisi ti wọn kọ Tinubu si lara

Oríṣun àwòrán, Twitter/Arise Nigeran Youth

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu ti sọ pe, oun kọ loun n pin irẹsi fawọn eeyan lapa ariwa orilẹede Naijiria ninu awẹ Ramadan to n lọ lọwọ yii.

Tinubu sọrọ yii ninu atẹjade kan to fisita lati ipasẹ oluranlọwọ rẹ feto iroyin, Tunde Rahman.

Laipẹ yii ni aworan apo irẹsi ti wọn ya Tinubu si lara lu ori ayelujara pa, ti ahesọ ọrọ naa si ni Tinubu lo n pin irẹsi naa lẹkun ariwa naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu ṣalaye ninu atẹjade naa pe lootọọ ni oun ri aworan apo irẹsi ti wọn ya oju oun si lara lori ayelujara, ṣugbọn oun kọ lo wa nidi rẹ.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Ẹwẹ, Tinubu gboṣuba fawọn ẹlẹyinju aanu to n pin irẹsi lasiko aawẹ yii.

O ni iwa ifẹ ati ififuni tawọn eeyan naa fihan lasiko Ramadan yii dara pupọ.

Ọpọ lo gbagbọ pe Tinubu n fi pinpin irẹsi lapa ariwa Naijiria ṣe ipolongo ṣaaju ibo aarẹ ọdun 2023 ni.