Sotayo Sobola: N kò le ṣeré farakinra pẹ̀lú ọkùnrin mọ́ lẹ́yìn ìgbeyàwó

Sotayo Gaga

Oríṣun àwòrán, Instagram/sotayogaga

Iyawo dun lọsingin, ọkọ tun mi gbe. Ọkan gboogi ni iran Yoruba jẹ ninu awọn to maa n bu ọla fun awọn to ba gbeyawo tabi re ile ọkọ.

Eyi lo difa fun gbajugba arẹwa oṣere tiata Yoruba, Tayo Sobola, ti ọpọ mọ si Sotayo Gaga, to sọ pe awọn eeyan n fun oun ni apọnle lẹyin ti oun ṣe igbeyawo tan ju ti tẹlẹ lọ.

Lẹyin to ṣe igbawo bonkẹlẹ tan, Sotayo ni ile ọkọ dun, o si larinrin pẹlu.

Arẹwa oṣere tiata Yoruba sọ pe ọdun meje loun fi ṣe ọrẹ pẹlu ọkọ oun ko to di pe awọn ṣe igbeyawo.

O ni lootọọ ni pe ko le ṣalai maa si idojukọ ninu igbeyawo, amọ Sotayo ni oun ati ọkọ oun dagba to lati wa ojutuu si idojukọ to ba wa.

Sotayo Gaga

''Igba tuntun mii ni igbeyawo jẹ fun emi ati ọkọ mi, a ṣi ti n rinrin ajo naa lọ diẹ diẹ,'' Sotayo lo sọ bẹẹ.

Nigba to n sọrọ nipa ayipada to ti ba ipa ti o maa n ko ninu ere lẹyin to ṣe igbeyawo tan, Sotayo ni oun ti semẹdọ nipa ṣiṣe awọn ere ti yoo mu ki oun farakinra ju pẹlu ọkunrin ninu ere bayii.

O ni bo tilẹ jẹ pe, ọkọ oun mọ pe iṣẹ tiata ni iṣẹ oun ki awọn to fẹra, oun naa ko ni ko ipa ti inu ọkọ oun ko le dun si ninu ere.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Sotayo ti wọn ṣẹṣẹ fi joye Sarauniya (Yeye) Uke Kingdom nipinlẹ Nasarawa sọ pe, o gbọdọ ni awọn nkan ti aafin Uke ri lara oun ki wọn to fun oun loye naa.

''Emir Uke gangan an sọ fun mi pe ibeji baba oun lo jẹ oye naa kẹyin, lẹyin naa ni wọn fi oye yii da oun lọla.

Wọn gbọdọ ri mi gẹgẹ bi awokọsẹ rere fawọn obinrin ni Nasarawa ki wọn to fun mi loye yii,'' Sotayo ṣalaye.