Oduduwa Nation: Ọlọ́pàá dá ìwọ́de fún ìyapa Nàíjíríà dúrò fún ìgbà díẹ̀ ní Sagamu

Awọn to n se iwọde ati ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Awọn ọlọpaa to wa nilu Sagamu da iwọde ita gbangba tawọn eeyan to n polongo Oduduwa Nation n se nilu naa duro fun igba diẹ ni ọjọ Ẹti.

Olayomi Koiki, tii se agbẹnusọ fun asaaju ajijagbara to n polongo orilẹede Oduduwa, Sunday Igboho, lo kede isẹlẹ yii loju opo Facebook rẹ.

Koiki, to n gbe iwọde naa bo se n waye, lo jẹ ki awọn eeyan to n wo iwọde naa loju opo Facebook rẹ gbọ nipa iro ibọn to n dun nibi iwọde naa.

Iwọde ọhun lo ti kọkọ waye ni ọja kan to gbajumọ nilu Sagamu lati ta awọn eeyan ji nipa orilẹede Oduduwa ti wọn n fẹ ko jẹ dida silẹ.

Awọn to n se iwọde ati ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Awọn iyalọja to si n tẹti si ipolongo idasilẹ orilẹede Yoruba naa ni inu wọn n dun lati gbọ ọrọ awọn olupolongo ọhun, bi wọn se n salaye fun wọn nipa ipo ti Naijiria wa.

Koda, awọn iyalọja to bawọn eeyan naa lo sọrọ ni wọn fi ero wọn han pe awọn n fẹ ki orilẹede tuntun naa wa si imusẹ laisi rogbodiyan kankan.

Amọ bi awọn olupolongo naa se de iwaju agọ ọlọpaa to wa ni Sagamu, ni awọn ọlọpaa to wa nibẹ tu jade ni ọgọọrọ, ti wọn si n yinbọn soke.

Awọn to n se iwọde ati ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Isẹlẹ yii lo mu ki awọn oluwọde yii sọkalẹ kuro ninu awọn ọkọ ti wọn n gbe kiri lati se iwọde, ti wọn si fi ẹsẹ rin lọ ba awọn ọlọpaa naa.

Wọn ba wọn sọrọ alaafia, ti wọn si salaye pe awọn ko ba ti ija wa, iwọde ẹ̀rọ̀ ni awọn n se, eyi ti ko le ni ọwọ rogbodiyan ninu, eyi tawọn n se fun idasilẹ orilẹede tuntun.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Awọn ọlọpaa naa wa rọ awọn oluwọde naa lati se iwọde wọn ni pẹlẹ putu, ti awọn mejeeji si jọ sere ati awada, ki wọn to pinya.