Mounrinho: Tottenham gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Mourinho gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ rẹ̀

Jose Mourinho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti gba iṣẹ lọwọ Jose Mourinho gẹgẹbi akọnimọọgba ikọ naa lẹyin ọdun kan ati oṣu marun un.

Ni oṣu kọkanla ọdun 2019 ni wọn yan Mourinho lati rọpo Mauricio Pochettino gẹgẹ bi akọnimọọgba ikọ Spurs to si gbe e lọ si ipo kẹfa lori atẹ liigi Premiership fun saa to kọja.

Lọwọ yii ipo keje ni wọn wa lori atẹ liigi fun saa liigi tọdun 20220/2021 to n lọ lọwọ, lẹyin ti wọn ri ami meji mu ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba sẹyin ti wọn si tun ti jabọ ninu idije Europa loṣu kẹta ọdun 2021.

Spurs yoo maa koju Manchester city ni aṣekagbaidije Carabao ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹrin, ọdun 2021.

ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham wa lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to n darapọ mọ idije liigi tuntun nilẹ Yuroopu.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Bakan naa ni wọn tun yọ awọn alabaṣiṣẹ pọ Mourinho Joao Sacramento, Nuno Santos, Carlos Lalin ati Giovanni Cerra.

Daniel Levy, alaga ẹgbẹ agbabọọlu Tottenhan ṣapejuwe Mourinho gẹgẹ bi "akọṣẹmọṣẹ to fi ifaẹnijin han paapaa lasiko ajakalẹ arun COVID-19"

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ni Mourinho ati ikọ Tottenham rẹ ti fidirẹmi ni liigi yii, eleyi to si jẹ igba akọkọ rẹ lati igba to ti gba iṣẹ akọnimọọgba rẹ.

Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Everton to waye lọjọ Ẹti ni ikẹyin fun Mourinho gẹgẹbi akọnimọọgba Everton, ọmi oni goolu mejimeji ni wọn si ta.

Agbabọọlu Tottenham tẹlẹ, Ryan Mason to n mojuto awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu ikọ naa ni yoo gba iṣakoso eto igbaradi awọn agbabọọlu ikọ naa lọjọ Aje.