Rivers state local government elections: PDP gba gbogbo ipò alága káńsù àti káńsélọ̀ ní ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Rivers

Awọn oṣiṣẹ idibo n yanju eto idibo ni Rivers

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ti jawe olubori ipo alaga kansu mẹtalelgun nibi idibo ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ Rivers lopin ọṣẹ to kọja.

Alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Rivers, RSIEC, Adajọfẹyinti George Omereji kede awọn alaga tuntun ati kansilọ fawọn ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa ni ipinlẹ naa.

Bakan naa lo si ṣalaye fun gbogbo wọn pe ki wọn rii daju pe wọn ko akoyawọ, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn to fidirẹmi ninu idibo naa lati ṣiṣẹ sin araalu fun idagbasoke ijọba ibilẹ wọn.

O ni: "Ọkan naa ni awọn to jawe olubori atawọn to fidirẹmi nitori ẹbi kan naa ni yin, lẹyin idibo yii ẹ fun ara yin ni ọwọ to yẹ ki ẹ si jumọ ṣe iṣẹ pọ fun idagbasoke ipinlẹ Rivers."

Amọṣa, awọn ẹgbẹ oṣelu kan ti n fi iru na igba yangan lori esi idibo ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ Rivers ti wọn si ti n pe fun wiwọgile esi idibo naa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Ẹgbẹ oṣelu African Action Alliance, AAC to wa lara awọn ẹgbẹ oṣelu to n pe fun wiwọgile esi idibo ijọba ibilẹ naa tọka si idibo naa gẹgẹ bi iwọsi nlanla fun eto iṣejọba tiwantiwa.

Atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ oṣelu AAC ni ipinlẹ Rivers, Progress Ogbokuma Aselemi fọwọsi rọ ijọba apapọ lati wọgile ajọ eleto idibo tipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria.

O ni pe nitori wọn ti sọ iyi ati aiṣegbe pẹlu ojuṣe iṣakoso eto idibo nu.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP pẹlu tun ti pe fun wiwọgile idibo naa.

Wọn pe fun atundi ibo sijọba ibilẹ nipinlẹ Rivers amọṣa labẹ iṣakoso alaga tuntun fi ajọ to n ṣamojuto idibo nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n