Prince Philip ṣètò ọkọ̀ tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ àtàwọn nǹkan míì kí ọlọ́jọ́ tó dé

Land Rover

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo wo bi eto isinku ọkọ ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, Prince Philip, lori ẹrọ amohunmaworan.

Ṣugbọn ohun ti ọpọ ko mọ ni pe oloogbe ọhun funra rẹ ti ṣe awọn eto kalẹ ki ọlọjọ to de nipa bi eto isinkun rẹ yoo ṣe lọ.

Lara awọn eto ti Prince Philip ti ṣe kalẹ ree:

1. Ọkọ ayọkẹlẹ Land Rover ti wọn fi gbe oku rẹ

Gẹgẹ bii awọn onimọ nipa eto isinku awọn ori ade ilẹ Gẹẹsi ṣe sọ, bi wọn ṣe ṣagbekakalẹ ọkọ Land Rover ti wọn fi gbe oku Prince Philip yatọ si awọn ti wọn maa n lo tẹlẹ.

Land Rover

Oríṣun àwòrán, PA Media

Eyii ko ṣẹyin bi ọkọ ọbabinrin naa ṣe ṣagbekalẹ ọkọ naa funra rẹ ko to dagbere faye.

Prince Philip jẹ eeyan kan to fẹran ọkọ Land Rover tẹlẹ, ṣugbọn ọdun mẹrindinlogun ló lò lati fi ṣe atunṣẹ ọkọ Land Rover naa si bo ṣe fẹ ki wọn le lo lasiko isinku rẹ.

Ọdun 2019 lo pari iṣẹ lara ọkọ naa ki wọn to kun si awọ ewe ti awọn ọmọ ogun n lo.

Ṣaaju lo ti kọkọ sọ fun ọbabinri Elizabeth pe ki wọn gbe oku oun si ẹyin ọkọ Land Rover naa, ki wọn si wa oun lọ si Windsor Castle ko to jẹ Ọlọrun nipe.

Oloogbe naa tun lọwọ si bi wọn ṣe ṣe ọkọ Bently to gbe ọbabinrin Elizabeth lọ si ibi isinku naa, eyii to fi taa lọrẹ lọdun 2002 lati fi sami si aadọta ọdun rẹ lori oye.

2. Asia ti wọn tẹ si ori posi rẹ

Posi Prince Philip ni St George Chapel

Oríṣun àwòrán, PA Media

Asia ti wọn tẹ le ori posi Prince Philip jẹ asia oun tikalara rẹ.

Asia naa si n ṣapẹrẹ igbe aye rẹ, lati ibẹrẹpẹpẹ ni Greece to fi mọ awọn oye to jẹ nilẹ Gẹẹsi.

Nigba ti Prince Philip ati ọmọ ọba Elizabeth bẹrẹ ere ifẹ wọn lọdun 1946, o kọ awọn ẹtọ rẹ ni Greece silẹ lati di ọmọ ilẹ Gẹẹsi.

Bakan naa ni wọn tun gbe fila to maa n de gẹgẹ bii ọmọ ogun ori omi ati ida rẹ sori posi naa.

3. Awọn irawọ to wa lara aṣọ rẹ

Irawọ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Lasiko isinku Prince Philip ni St George Chapel, wọn tẹ awọn aṣọ mẹsan an kan sori pẹpẹ nile ijọsin naa, lara eyii ti awọn irawọ ti oloogbe naa ti gba tẹlẹ wa.

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe Prince Philip funra rẹ lo tọka si awọn irawọ ti wọn yoo so mọ awọn aṣọ naa lẹyin oun.

Bo tilẹ jẹ pe oloogbe ọhun gba ami ẹyẹ ati ọpọ irawọ lawọn orilẹ-ede to le ni aadọta, diẹ lara rẹ ni wọn fi lede nile ijọsin St George ti eto isinku naa ti waye.

Lara awọn irawọ to wa lara awọn aṣọ naa ni ti Zanzibar, Brunei, Utama ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Prince Philip