Benue, Tanker explosion in Agatu: Ọkọ̀ agbépògb[aná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná

Oríṣun àwòrán, @Olikita Ekani
Ọjọ buruku esu gbomi mu ni ọjọ Aiku yi jẹ fawọn eeyan abule Oshigbudu ni ijọba ibilẹ Agatu nipinlẹ Benue ni aarin gbungbun Naijiria.
Ohun to fa ẹkun ati ose ni abule naa ni bi eeyan mẹsan an ti se padanu ẹmi wọn ninu ibugbamu ọkọ agbepo kan.

Oríṣun àwòrán, @Olikita Ekani
Ninu isẹlẹ yi, sọọbu ati ile mejilelaadọrin ni ina to sẹyọ yi jo gẹgẹ bi awọn alasẹ ti se sọ fun BBC.
Ibugbamu naa waye nigba ti ọkọ agbepo yi subu lulẹ ti epo inu rẹ to da soju ọna si gbana.
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga
- Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley ṣe le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wọlé
- Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Mourinho, akọ́nimọ̀ọ́gbá Tottenham
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
Sunday Oteyi to jẹ akọwe ijọba ibilẹ Agatu sọ pe nkan bi ago mejila oru lọjọ Kejidinlogun, osu Kẹ́rin ni isẹlẹ yi waye.
Ọkọ agbepo yii la gbọ pe o n ba ere bọ lati agbegbe Otukpo. Bo ti se de Ikorita Oshigbudu-Ogbagaji, ni se lo subu lulẹ to si gbana
Oteyi sọ pe adugbo yi jẹ ibi ti karakata ti maa n waye sugbọn inu ibanujẹ lọpọ awọn ọlọja lagbegbe naa wa bayi nitori ajalu ti o de bawọn.
Awọn tọrọ naa soju wọn ni nise ni awọn ri eefin ina to n jo awọn ile to wa ni tosi lokeloke.
Okunrin naa ni: "Iru ijamba ina ọkọ agbepo bayi kii se nkan tuntun ni Naijiria.
Losu Keje ọdun 2019, eeyan marundinlaadọta lo ku tawọn to le ni ọgọrun un si farapa ni agbegbe yii nigba ti awọn eeyan n gbiyanju lati bu epo ninu ọkọ agbepo to danu soju ọna.
Ati ile mi ati ọna ijẹ mi ni mo padanu ninu ijamba ina Agatu."
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- PDP borí ìdìbò káńsù ní Rivers, AAC, SDP fárígá
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí 45 lórí ọ̀rọ̀ ìkọlù ẹgbẹ́ òkunkùn tó wáyé ní Ikẹrẹ Ekiti- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá
Ugbona Chijioke to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta si n banujẹ lori ijamba ina yi to jo isẹ ọwọ to fi nkan to le ni ọdun mẹẹdogun ko jọ.
Nigba to wa lọdun mọkanlelọgbọn lo de si abule Oshigbudu lati ipinlẹ Enugu lati wa ma a ta oogun.
Nibi lo pẹka si, kọ ile ara rẹ si to si tun fẹ iyawo to tun bi ọmọ mẹrin si.
Ugbona ni oun n jẹun lọwọ nita loun gbọ ibugbamu yi. Nigba ti yoo fi de ile rẹ, o sọ pe awọn ọmọ nikan loun ri ko jade.
Iroyin ti a gbọ ni pe ọkọ agbepo to subu lulẹ yi, ko ribi ko ijanu rẹ lasiko ni o fi subu.
- Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley ṣe le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wọlé
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
Nigba ti yoo fi de abule Oshigbudu, nise lo danu ti disu inu rẹ si gbina.
Igbiyanju awọn panapana lati pa ina yi ja si pabo bi kii se pe awọn ara adugbo ati awọn ọlọpaa fọwọ kun wọn ki wọn to ribi pa eyi to sẹku ninu ina naa.
Awọn ọlọpaa ni eeyan kan to wa ninu tirela naa to farapa ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Oríṣun àwòrán, @Olikita Ekani














