Ìjọba Katsina yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Katsina ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ si n fi aja ṣo awọn ile ẹkọ ti awọn akẹkọọ n gbe nipinlẹ naa.
Kọmiṣonna fun eto ẹkọ ipinlẹ ọhun, Badamasi Lawal Chiranci sọ fun BBC pe ijọba ipinlẹ naa ti pese 580 miliọnu ti wọn yoo fi kọ ogiri yii awọn ile ẹkọ naa ka.
O fi kun pe wọn yoo tun lo lara owo ọhun lati ra awọn aja lọna ati koju eto abo to mẹhẹ.
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga
Chiranci ṣalaye pe awọn aja naa yoo maa ta awọn agbofinro lolobo ni gbogbo igba ti nnkan ko ba fẹ ṣẹnu ire nipa ti eto abo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ "Ti awọn aja naa ba ti kofiri ohunkohun to le ṣakoba fun eto abo, wọn yoo tete ta awọn agbofinro lolobo, eyii ti yoo wulo fun gbogbo araalu."
Kọmiṣọnna naa fikun pe awọn yoo tun ṣe idanilẹkọọ fun awọn akẹkọ lori ọna ti wọn yoo fi da awọn janduku mọ, ki wọn le maa tete ke si awọn ọlọpaa.
O pari ọrọ rẹ pe, iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni Katsina kiba ma ti waye to ba jẹ pe awọn akẹkọọ mọ bi wọn ṣe le bojuto eto abo ara wọn.
- Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley ṣe le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wọlé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí 45 lórí ọ̀rọ̀ ìkọlù ẹgbẹ́ òkunkùn tó wáyé ní Ikẹrẹ Ekiti- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Makinde pàṣẹ pé kí wọ́n wó iléègbé àwọn òṣìṣẹ́ BCOS ní Ibadan?















