Ọwọ́ NDLEA tẹ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tó n ta 'cookies' tí wọ́n fi oògùn olóro ṣe fún àwọn ọmọ́de

Bisikiiti naa ati awọn afurasi mejeeji

Oríṣun àwòrán, Ndlea nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA ti mu ọmọbinrin kan ati ọrẹkunrin rẹ, fun pe wọn n ta bisikiti ti wọn fi egboogi oloro ṣe fun awọn ọmọde nilu Abuja.

Ninu atẹjade ti ajọ NDLEA fi sita loju opo Twitter rẹ lo ti sọ pe ọwọ tẹ Rhoda Agboje.

Rhoda jẹ akẹkọọ fasiti, ati ọrẹkunrin rẹ, Ifeanyi Nwankwo, pe wọn n fi egboogi oloro pelo bisikiiti ti wọn n ta fun awọn ọmọ ileewe ati awọn eeyan mi laarin ilu, ti ko mọ iru iṣẹ ti wọn n ṣe.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ, aṣiri ikọ naa tu u, lẹyin ti ọwọ tẹ Rhoda t'ohun ti bisikiti naa mẹrin lọwọ rẹ lọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

Agbegbe NNPC Cooperative Estate ni Gaduwa, nilu Abuja, ni ọwọ ti tẹ ẹ lẹyin ti awọn kan fi ẹjọ rẹ sun pe o fun ọmọde kan ni bisikiiti naa jẹ.

Iroyin sọ pe ọmọdebinrin naa bẹrẹ si ni ṣe were-were, ko le sun, bẹẹ lo n sọrọ bi ẹni to ni aarun ọpọlọ nitori oró bisikiiti naa lara rẹ.

Lasiko ti awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA n fi ọrọ wa Rhoda l'ẹnu wo lo jẹwọ pe oun ati ọrẹ rẹ kan ni wọn jọ n ṣe bisikiiti naa.

Ọwọ tẹ Rhoda Agboje ati ọrẹkunrin rẹ, Ifeanyi Nwankwo ti ọwọ NDLEA

Oríṣun àwòrán, Ndlea nigeria

Àkọlé àwòrán, Ọwọ tẹ Rhoda Agboje ati ọrẹkunrin rẹ, Ifeanyi Nwankwo ti ọwọ NDLEA

Ẹgbẹrun kan aabọ Naira si ni wọn ma n ta ẹyọ mẹta rẹ.

Iwadii ti wọn ṣe si ile ọrẹkunrin rẹ lo mu ki wọn o ri igba bisikiiti naa ti wọn fi egboogi oloro ṣe.

Bakan naa ni wọn ba awọn irinṣẹ ti wọn fi n ṣe e.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa

Afurasi naa sọ pe oun ma n ta a ni ibi ariya, fun awọn araalu ti ko mọ nkan ti wọn fi ṣe e, to fi mọ awọn ọmọ ileewe.

Bakan naa lo ma n gbe fun awọn ile itaja ati ile ijo gẹgẹ bi alagbata rẹ.

Àkọlé fídíò, hhhhhh