Insecurity in Nigeria: Wo àwọn ìkọlù àgọ́ ọlọ́pàá tó ti wáyé lẹ́kùn àríwá gúúsù Nàìjíríà ní lọ́wọ́ yì

Ajoku agọ ọlọpaa kan

Oríṣun àwòrán, Ebonyi police

Lẹnu lọwọlọwọ yii gbọnmọgbọnmọ ikọlu awọn agbebọn sawọn agọ ọlọpaa lẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria n kọ ọpọlọpọ lominu paapaajulọ awọn alaṣẹ eto abo lorilẹede Naijiria.

Amọṣa, iṣẹlẹ naa ti wa di lemọlemọ to si n mu ki ọpọ awọn olugbe naa o maa kọrin araba tunra mu, odo n gbarere.

Eyi ni ṣisẹ n tẹle bi awọn ikọlu naa ti ṣe waye laarin oṣu mẹfa titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ :

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ebonyi:

Eyi waye ni ọjọ kẹjọ oṣu kini, ọdun 2021 ninu eyi ti awọn ọlọpaa mẹta ti padanu ẹmi wọn.

Agọ ọlọpaa to wa ni ilu Onueeke ni ijọba ibilẹ Ezza south ni ipinlẹ naa ni wọn kọlu.

Awọn ọlọpaa kogberegbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia:

Ni ọjọ kini oṣu keji ọdun 2021 leyi waye to si mu ẹmi ọlọpaa kan lọ.

Agọ ọlọpaa to wa ni Omoba ni Ijọba ibilẹ Isiala Ngwa south leyi ti waye.

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ebonyi:

Ni ọjọ kẹrin, oṣu keji ọdun 2021, awọn agbebọn kan tun kọlu agọ ọlọpaa ni Isu ni Onitsha Isu nibiti wọn ti jo agọ ọlọpaa kan bolẹ.

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo:

Ni ọjọ karun un oṣu keji, ọdun 202, awọn agbebọn kan tun kọlu agọ ọlọpaa kan ni Umulowo nijọba ibilẹ Obowo nibi ti wọn ti pa ọlọpaa meji.

Ọkọ ọlọpaa kan ti wọn dana sun

Oríṣun àwòrán, Ebonyi police

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia:

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji yii kan naa, awọn agbebọn yii tun ṣe ọṣẹ nipinlẹ Abia nibi ti wọn ti pa ọlọpaa meji lagọ ọlọpaa to wa ni Abayi ni ilu Aba.

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo:

Nigba to di ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji ọdun 2021, Aboh Mbaise ni wọn gbe iṣẹ ibi wọn lọ ni ipinlẹ Imo nibi ti wọn ti dana sun odindi agọ ọlọpaa kan bolẹ.

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo:

Awọn oniṣẹ ibi yii tẹsiwaju ni ipinlẹ Imo ni ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta nigba ti wọn tun kọlu agọ ọlọpaa kan ni Ihitte-Uboma ti wọn si jo agọ ọlọpa to wa nipa.

Ọkọ ọlọpaa kan ti wọn dana sun

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra:

Lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta, ọdun 2021, wọn tun ṣekupa ọlọpaa kan ni ibudo ayẹwo ọkọ tawọn ọlọpaa gbe kalẹ ni Neni nijọba ibilẹ Anaocha.

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra:

Lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹta ọdun 2021, awọn agbebọn tun pa ọlọpaa kan nigba ti wọn kọlu agọ ọlọpaa Ekwulobia ni Nanka ni ipinlẹ naa.

An alaṣẹ ijọba n se abẹwo si agọ ọlọpaa kan ni Abia

Oríṣun àwòrán, other

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia:

Ipinlẹ Abia ni wọn tun gbe iṣẹ laabi wọn lọ ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun 2021 nigba ti wọn kọlu agọ ọlọpaa ni Abiriba, iyẹn ni ijọba ibilẹ Ọhafia.

ọlọpaa mẹta ni wọn pa lasiko ikọlu naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra:

Lọjọ kẹsan an, oṣu kẹrin, ọdun 2021, awọn agbebọn kan tun kọlu agọ ọlọpaa ni Ukpo ni ipinlẹ Anambra.

Eyi waye nigba tawọn agbebọn naa ya wọ olu ileeṣẹ ẹkun kẹtala ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa ni nnkan bi agogo mẹrin.

Sugbọn iroyin sọ pe awọn ọlọpaa da wọn lọwọ duro ki wọn to le ṣe ọṣẹ ju bi o ti yẹ lọ.

Awọn ọlọpaa ni awọn agbebọn naa ko ri ibọn ọlọpaa ko salọ lasiko ikọlu naa

Awọn iroyin abẹle kan sọ pe wọn pa ọlọpaa meji lasiko ikọlu naa.

An alaṣẹ ijọba n se abẹwo si agọ ọlọpaa kan ni Abia

Oríṣun àwòrán, other

Ikọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia:

Ni ọjọ kẹsan an, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii kan naa awọn agbebọn tun kọlu agọ ọlọpaa ni Ozokoli, nijọba ibilẹ Bende nipinlẹ Abia.

Lasiko ikọlu wọn naa, wọn tu awọn ti wọn wa lahamọ ọlọpaa ni agọ naa silẹ ti wọn si dana sun ile ọkọ atawọn dukia miran to jẹ ti ọlọpaa nibẹ.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Nibi ti ọrọ de duro bayii, ko si ẹni lee sọ ni pato iye ọlọpaa to ti ku sọwọ ikọlu awọn agbebọn yii ṣugbọn gbogbo igba ti ikọlu yii ba n waye ni ileeṣẹ ọlọpaa n fi da araalu loju "pe ko si apaniyan kan ti yoo lọ laijiya"

Ọpọlọpọ igba ni wọn si ti fi ẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ ajijangbara IPOB pe awọn lo wa nidi ikọlu naa, ṣugbọn IPOB ti ni awọn ko mọwọ-mẹsẹ nipa awọn ikọlu buruku naa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh