Autonomy for Judiciary: Àwọn Gomina ṣetán láti yọwọ́ kúrò nínú sísan owó oṣù àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ àti Adájọ́- Fayemi

Oríṣun àwòrán, Getty/kayode fayemi
Ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2020 ni Aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu ofin ti yoo fun awọn ile aṣofin ipinlẹ, ati ẹka eto idajọ ni awọn ipinlẹ ni ominira lati da duro ninu eto inawo wọn.
Igbesẹ Aarẹ ko ṣẹyin atunsẹ to waye si abala ofin naa ninu iwe ofin ọdun 1999.
Ọpọlọpọ awọn gomina ipinlẹ lo fi aidunnu wọn han lori igbesẹ naa, eyi to mu ki Aarẹ ṣe ipade kan pẹlu wọn lo ri ayelujara.
Bakan naa ni aarẹ da sisọ ofin naa di aṣẹ ijọba duro, titi ti Agbẹjọro Agba Naijiria yoo fi ṣe ipade pẹlu awọn gomina lati yanju ibẹru ti wọn n ba ni lori igbesẹ aarẹ.
Amọ, ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria kede pe awọn ti fi ara mọ ofin yii.Àwọn Gomina ṣetán láti yọwọ́ kúrò nínú sísan owó oṣù àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ àti Adájọ́- Fayemi
Ikede wọn waye lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ ati awọn agbẹjọro bẹrẹ iwọde ati iyanṣẹlodi lori ọrọ naa.
Iru ofin wo ni wọn fi n ṣe eto owo iṣuna ẹka idajọ tẹlẹ?
Ṣaaju ki Aarẹ Buhari to o pa aṣẹ naa, awọn gomina ipinlẹ lo ma n sọ iye owo ti wọn yoo fun awọn ẹka ijọba yooku, to fi mọ yiyọnda owo naa fun wọn.
O ma n farahan ninu aba owo isuna ti wọn n gbe lọ siwaju awọn aṣofin ipinlẹ.
Eyi mu ki awọn gomina o ni aṣẹ ati agbara lori ẹka eto idajọ ati awọn aṣofin.
- Lórí ayélujára 'Zoom' ni ìdájọ́ ẹjọ́ láàrin Akeredolu àti Jegede lórí ipò gómìnà Ondo yóò ti wáyé
- Àwọn ọlọ́pàá ti dóòlà ọmọbìnrin tí àwọn òbí rẹ̀ so mọ́lẹ̀ fún ọdún 10
- Ṣé lóòtọ́ ni Sotayo Gaga ti di ìyá Ọba nílẹ̀ Hausa?
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
Kini ofin tuntun sọ?
Gẹgẹ bi alaye ti ileeṣẹ amofin Lori Niji Oni & Co ṣe lori ofin tuntun yii ni ori ayelujara rẹ, nijioni.com, Aarẹ ti paṣẹ pe ki Oluṣiro owo Agba fun Naijiria, o ma a yọ lara owo to tọ si ipinlẹ ti ko ba ti tẹle aṣẹ tuntun yii, ki owo naa to tẹ wọn lọwọ.
Awọn ipinlẹ gbọdọ fi si inu ofin eto isuna wọn pe ominira wa fun ẹka idajọ ati aṣofin, lati ṣeto isuna funra wọn. Awọn ti ko ba ni ofin yii tẹlẹ gbọdọ fi kun ofin wọn.
Kini ojuṣe Oluṣiro owo Agba ninu aṣẹ yii?
1) Aṣẹ aarẹ fihan pe Oluṣiro owo Agba nipasẹ aṣẹ aarẹ, tabi eyi ti Agbẹjọro agba ba pa, le fọwọ si i pe ki wọn o yọ lara owo to n lọ si apo ijọba ipinlẹ to ba kuna lati yọnda owo to tọ si ẹka idajọ ati ile aṣofin ipinlẹ rẹ, ni ibamu pẹlu Abala ofin 121 (3) ti Naijiria fun ọdun 1999.

2) Aṣẹ tuntun yii tun fi lelẹ pe ẹka to n dari ijọba 'executive' ko gbọdọ ṣe aba eto isuna fun ẹka idajọ mọ:
a)O ni igbimọ mii fun owo isuna ni yoo ma ṣe e , ti yoo si tun mojuto bi wọn ṣe n na.
b) Ẹka eto idajọ ni ipinlẹ kọọkan ni yoo yan igbimọ rẹ fun eto iṣuna, amojuto ati nina owo iṣuna rẹ.
c) Awọn ti yoo si wa ninu igbimọ naa ni Adajọ Agba ni ipinlẹ naa (Alaga), Aarẹ ile ẹjọ Sharia/ile ẹjọ ibilẹ, eeyan meji lati inu ajọ to n dari ẹka eto idajọ (Adajọ Agba ni yoo yan wọn lẹyin to ba jiroro pẹlu awọn ọmọ igbimọ to kù).
d) Akọwe ile ẹjọ giga ipinlẹ ni yoo jẹ Akọwe igbimọ yii.
Kini yoo jẹ ojuṣe igbimọ owo iṣuna?
a)Ti igbimọ naa ba ti tẹwọ gba àbá owo isuna fun lọdọọdun, yoo ranṣẹ pe awọn Oluṣiro owo ni ile ẹjọ kọọkan tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni ẹka eto idajọ, lati wa ṣalaye lori aba isuna wọn.
b) aba isuna naa yoo da lori awọn ilana ti igbimọ to wa fun isuna ba fun awọn ile ẹjọ ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni ẹka eto idajọ. Eyi ni wọn o si gbe lọ si iwaju awọn aṣofin ipinlẹ.
c) ti ijọba ba ti yọnda owo isuna naa, igbimọ yii yoo ma ranṣẹ si ọfiisi ti wọn ti n ṣeto owo isuna, boya ni oṣooṣu tabi asiko to ba pinnu, pe ko yọnda owo fun oṣu naa tabi oṣu mẹta.
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga
Ibeere wọn yii ni Oluṣiro owo Agba ni ipinlẹ yoo fi aṣẹ si pe ki wọn o yọnda owo fun awọn oludari nile ẹjọ ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni ẹka eto idajọ, ni ibamu pẹlu ofin to de eto isuna.
Ilana ti ijọba ipinlẹ n gba ṣe akọsilẹ, eto agbekalẹ owo iṣuna tẹlẹ naa ni ẹka eto idajọ ati aṣofin yoo tẹle.

Oríṣun àwòrán, others
Àwọn Gomina ṣetán láti yọwọ́ kúrò nínú sísan owó oṣù àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ àti Adájọ́- Fayemi
Ijọba ti ni ki awọn adajọ ati aṣofin ni ipinlẹ fi ọkan balẹ nitori awọn gomina ti ṣetan lati jẹ ki wọn da duro lori owo osu wọn.
Gomina ipinlẹ Ekiti ati Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorilẹede Naijiria, Kayode Fayemi lo kede rẹ lẹyin ipade ni ile ijọ,ba ni ilu Abuja

Oríṣun àwòrán, @Fayemi
Fayemi ni ko si otitọ ninu iroyin pe awọn gomina ipinlẹ tako aba ki awọn aṣofin daduro lai si iranwọ ijọba ipinlẹ ati eto idajọ ni ipinlẹ naa pẹlu.
O ni ori ọwọ kan naa ni awọn Abẹ̣ṇ̣ugan ile igbimo aṣofin ipinlẹ ati awọn adajọ wa pẹlu gomina.
- Láàrin Akeredolu àti Jegede, ta ni ilé ẹjọ́ yóò gbé ipò gómìnà fún lónìí?
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
Amọ, gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ko sọ ni ẹkun rẹrẹ bi idaduro awọn ẹka iṣejọba mejeeji naa yoo ṣe lọ.
''Inu mi dun wi pe olori awọn oṣiṣẹ aarẹ Buhari, Ibrahim Gambari ti bẹrẹ igbese ti yoo tẹ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lọrun.''
''A ko tii le sọ ọjọ gan an ti idaduro ẹka aṣofin ati idajọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu, amọ inu oṣu to n bọ ni.''
Bakan naa ni Fayemi wa kesi awọn adajo to gunle iyanṣelodi lati jọwọ pada si ẹnu iṣẹ wọn fun itẹsiwaju orilẹede Naijiria.
O ni awọn adajọ yẹ ki wọn woo ṣe bayii nibi ti ọrọ de duro, nitori awọn gomina ipinlẹ kaakiri Naijria lo ti gbe igbeṣẹ akọni lati ri pe wọn ko fi eto wọn dun wọn.
Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kẹrin ni ẹgbẹ awọn oṣiṣe ni ẹka eto idajọ ni Naijiria, JUSUN gunle iyanṣelodi lati bere fun ẹto to fun wọn ni aṣẹ lati daduro nitori bi ijọba ipinlẹ ṣe n fi owo ajẹmọnu wọn dun wọn.
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- PDP borí ìdìbò káńsù ní Rivers, AAC, SDP fárígá
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí 45 lórí ọ̀rọ̀ ìkọlù ẹgbẹ́ òkunkùn tó wáyé ní Ikẹrẹ Ekiti- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley ṣe le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wọlé
















