Idriss Deby: Wo kókó méje nípa Mahamat Kaka Deby tò gba ipò Ààrẹ fìdíhẹ tuntun ní Chad

Mahamat Deby

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin iṣekupani aarẹ Idriss Deby to n tukọ orilẹ-ede Chad lanaa ni wọn yan ọmọ rẹ Mahamat Kaka Idriss Deby sipo aarẹ nibẹ.

Lati igba ti iroyin iyansipo rẹ si ti jade ni gbogbo eeyan ti n fẹ mọ sii nipa arẹ fidihẹ to n dele naa.

Tani Mahamat Idriss Deby Itno to di aarẹ tuntun ilẹ Chad lẹyin iṣekupani baba rẹ?

Ileeṣẹ ologun Chad ti fi lede pe Mahamat Idriss Deby Itno ni yoo di aarẹ tuntun ilẹ Chad, lẹyin ti baba rẹ, Idriss Deby Itno di oloogbe.

Idriss Deby to jẹ baba aarẹ tuntun naa ni o ti wa ni ijọba fun ọgbọn ọdun, ki o to ba ogun lọ nibi ikọlu to waye lorilẹ-ede naa.

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

Wo koko meje to ṣe pataki nipa aarẹ tuntun naa, Mahamat kaka Deby:

•Mahamat Idriss Deby to jẹ ogagun yoo di ipo baba rẹ mu fun oṣu mejidinlogun.

•Ọdun 1983 si 1984 ni wọn bi Mahamat Idriss Deby, to si jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji si ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

•Orilẹ-ede Faranse lo ti lọ kọ iṣẹ ologun lẹyin to lo ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni orilẹ-ede Chad.

•Ni ọdun 2013 ni wọn yan an gẹgẹ bi igbakeji adari ikọ ọmọogun ilẹ Chad to pegede julọ (Chadian Special Forces).

•Ki baba rẹ to ku, o ṣiṣẹ gẹgẹ bi igbakeji adari ikọ ọmọogun ilẹ Chad lasiko ogun abẹlẹ ariwa ilẹ Mali.

•Bakan naa o ṣiṣẹ gẹgẹ bi Alaga ajọ to n risi gbigbe ijọba ologun silẹ ni Chad.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa

•Lasiko ti ọgagun Kaka wa ni ipo aarẹ tuntun yii, o yẹ ki Abẹnugan Ile Igbimọ Asofin orilẹede naa pe fun idibo sipo aarẹ, eleyii ti Kaka ko ni kopa nibẹ.

Aare Idriss Deby to papoda naa je okan gboogi ninu awon to ja fitafita tako iko Boko Haram ni agbegbe Chad nigba aye re.

Mahamat Deby

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọ́n ti kéde ọmọ Ààrẹ Chad tẹ́lẹ̀, Kaka Deby gẹ̀gẹ́ bíi Ààrẹ fìdíhẹ tuntun

Ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹ-ede Chad ti kede ọgagun Mahamat Idriss Deby, to jẹ ọmọ Aarẹ Idriss Deby to papopda gẹgẹ bii dari igbimọ ọmọ ogun ti yoo maa dari orilẹ-ede naa fun saa yii.

Ikede yii lo waye lẹyin iku Aarẹ Idriss Deby ọhun lẹyin to fara gba ọta ibọn loju ija pẹlu awọn ọmọ ologun ọlọtẹ.

Wọn sọ pe ọgagun Mahamat Kaka ni yoo tukọ orilẹ-ede naa gẹgẹ bii Aarẹ fidihẹ fun ọdun kan abọ.

Kini o n ṣẹlẹ̀ ní Chad lẹ́yìn ikú Idriss Deby?

Ki wọn to kede ipo tuntun yii, ọgagun Kaka ni alaga igbimọ to n ri si ayipada ijọba ologun ni Chad.

Onimọ nipa eto oṣelu kan, Ọjọgbọn Evariste Ngarlem Toldé ṣalaye fun BBC pe, o lodi si ofin orilẹ-ede Chad bi wọn ṣe kede ọmọ Idriss Deby gẹge bii olori lẹyin iku baba rẹ.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ṣaaju ji wọn ti kọkọ kede konile-o-gbele lorilẹ-ede naa lẹyin iku Aarẹ Deby, igbele naa yoo si maa bẹrẹ lati aago mẹfa irọlẹ si marun un owurọ.

Idriss Deby ni Aarẹ Chad lati ọdun 1990 titi di ọdun 2021 to dagbere faye.

Chad

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba Chad kéde kónílé-ó-gbélé aláìlọ́jọ́ lẹ́yìn ikú Ààrẹ Idriss Deby

Ijọba orilẹ-ede Chad ti kede ofin konile-o-gbele lẹyin iku Aarẹ ana, Idriss Deby Ta ni Idriss Deby tí kò bá tún gorí àlééfà ipò aarẹ Chad lẹ́ẹ̀kẹfà tó wá ṣaláìsí yìí?

Konile-o-gbele alailọjọ naa yoo bẹrẹ lati aago mẹfa irọlẹ si marun u owurọ, bakan naa ni ọkọ ofurufu kankan ko ni jade tabi wọle si orilẹ-ede naa fun saa yii.Ẹlẹ́wọ̀n 44 kú sọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí ooru tó mú púpọ̀

Deby jade laye lẹyin to fara gba ọta ibọn lasiko to n koju awọn ọmọogun ọlọtẹ to ṣigun wọ olu ilu orilẹede naa, N'Djamena.

Ọjọ kọkanla oṣu yii ni awọn ọmọ ogun ọlọtẹ naa bẹrẹ si n ṣakọlu lemọlemọ lẹyin idibo sipo Aarẹ ti wọn di, eyii ti abajade rẹ n fi han pe Deby ni yoo gori alefa fun saa kẹfa.

Idriss Deby jẹ aarẹ ti o ditẹ gbajọba ni orilẹ-ede Chad.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Ọpọ igba si ni wọn ti gbiyanju lati ditẹ gbajọba lọwọ rẹ ṣugbọn to n ja si pabo ni orilẹ-ede Chad nilẹ Adulawọ.

Loṣu kẹrin, ọdun 2011 ni Idriss Debby di aare ilẹ Chad lẹẹkẹrin nigba ti awọn ẹgbẹ alatako kọ lati kopa ninu idibo naa gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe lọdun 2006.