Idriss Deby: Àwọn ológun ní Chad ní Ààrẹ Idriss Deby kú lọ́wọ́ ọta ìbọn tó faragbà

Idriss Deby

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idriss Deby, Aàrẹ orílẹ̀-èdè Chad jáde láyé!

Iroyin to n jade latọdọ awọn ologun orilẹ-ede Chad n sọ pe Aarẹ Idris Deby ti orilẹede naa ti jade laye.

Awọn alaṣẹ ologun lorilẹede Chad ni Aarẹ Deby ku latari ọgbẹ ọta ibọn to gba lasiko ti wọn n koju awọn ọmọogun ọlọtẹ to ṣigun wọ olu ilu orilẹede naa, N'Djamena.

Ireti wa pe aarẹ Deby yoo wọle saa kẹfa gẹgẹ bi aarẹ orilẹede naa lẹyin idibo aarẹ to waye nibẹ lọjọ kọkanla oṣu kẹrin ọdun yii.

Kini o ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Idriss Deby jẹ aarẹ ti o ditẹ gbajọba ni orilẹ-ede Chad.

Ọpọ igba si ni wọn ti gbiyanju lati ditẹ gbajọba lọwọ rẹ ṣugbọn to n ja si pabo ni orilẹ-ede Chad nilẹ Adulawọ.

Loṣu kẹrin ọdun 2011 ni Idriss Debby di aare ilẹ Chad lẹẹkẹrin nigba ti awọn ẹgbẹ alatako kọ lati kopa ninu idibo naa gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe lọdun 2006.

Idriss Deby

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọdun 2008 nijọba waa ko pẹlu awọn ọmọ ogun alatako ninu ikọlu to gbona ni chad nigba naa.

Koda lọdun 2013 nijọba Idriss Deby ni oun ti fopin si iditẹ gbajọba lati ọdọ awọn eekan ninu iṣẹ ologun.

Tani Idriss Derby?

A bi Idriss Deby ni Fada ni ila oorun Chad lọdun 1952.

O jẹ akọṣẹmọṣẹ ọmọ ogun ilẹ nibi to ti ran Hissen Habre lọwọ si Goukouki Queddei lọdun 1982.

Lọdun 1989 lo sa lọ si orilẹ-ede Sudan lẹyin ti wọn fẹsun iditẹgbajọba kan an.

Lọdun kan lẹyin eyi ni Patriotic Salvation Movement le Ọgbẹni Habre lọ lọdun naa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Ọdun 1991 ni wọn kede Ogbeni Idriss Deby gẹgẹ bii Aarẹ ile Chad.

Lọdun 1996 ni Deby tun dibo gbajọba de ipo aarẹ alagbada labẹ akoso ẹgbẹ oṣelu alasopọ.

Lẹyin eyi ni wọn tun dibo yan an lọdun 2001, ati 2005 ni eyi to fi lọ fun saa kẹta lẹyin ayipada ọdun 2005.

Lọdun 2013 ni amnesty International se akọsilẹ kan pe Idriss Deby n fiya jẹ awọn to ba n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iṣejọba rẹ ni Chad ati pe ko mu awọn ileri tuntun to n ṣe ṣe fun ara ilu lati bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan to ṣe lọdun 1990 to gori aleefa.

Deby Idriss gbogun ti awọn oniṣẹ ibi agbesunmọmi pupọ.

O ṣiṣẹ pẹlu awọn orilẹ-ede to sunmọ Chad bii Niger, Nigeria, Cameroun, Mali ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oun lo n lewaju ninu esi idibo ti wọn n ka lọwọ ni orilẹ-ede Chad nibi ti wọn ni o ti ni ida ọgọrin bayii ṣaaju iku rẹ.

Eyi tumọ si pe ki wọn kede rẹ lo n duro de

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Iru iku wo lo pa Idriss Deby?

Awọn ọmọ ilẹ Chad sọ pe lasiko ogun ni aarẹ Idriss Deby ṣubu loju ija.

Lasiko yii ni awọn ọmọ ogun ilẹ Chad n gbogunti awọn ọmọ ogun alatako to ti dana ija ni olu ilu Chad ni N'Djamena

Eto idibo ti wọn ṣe lọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun yii ni wọn ti n reti pe Idriss Deby ni yoo bori idibo naa ti yoo si gori aleefa aarẹ Chad lẹẹkẹfa.