Kaduna student kidnapping: Gómìnà El-Rufai sọ pé owó ìdóòlà yóò túbọ̀ ṣe ìwúrí fún àwọn ọ̀daràn

Aworan Gomina Nasir El Rufai

Oríṣun àwòrán, Twitter@elrufai

Gomina Nasir El-Rufai ti ipinlẹ Kaduna ti sọ pe ijọba oun ko ni i san owo kankan fun awọn agbebọn to n ṣoro nipinlẹ naa.

El-Rufai sọ eyi gẹgẹ bi esi nipa bi awọn eeyan kan ṣe n pín fidio to ti sọ fun ijọba aarẹ Naijiria nigba kan, Goodluck Jonathan, pe ko san owo fun itusilẹ àwọn akẹkọọ Chibok ti Boko Haram gbe lọdun 2014.

Laarin bi oṣu kan ni awọn janduku ti kọlu àwọn ileewe giga ni ipinlẹ Kaduna, ti wọn si ti pa marun-un lára àwọn akẹkọọ to wa ni ahamọ wọn.

Ọsan ọjọ Iṣẹgun si ni awọn agbebọn tun fi fidio kan si ori ayelujara, nibi ti wọn ti ṣe afihan àwọn akẹkọọ ileewe imọ ọgbin kan nipinlẹ naa ti wọn jigbe ninu oṣu Kẹta.

Oludamọran fun Gomina El-Rufai lori eto ibaraẹni sọrọ, to fi atẹjade sita lorukọ gomina, Muyiwa Adekeye sọ pe awọn iṣẹlẹ ijinigbe to n waye lasiko yii yatọ si ti ọdun 2014.

O ni igbesẹ owó sísan, ijiroro, idunadura ati aforijin ti ijọba ń ṣe fún awọn janduku kan n fun wọn ni agbara ati igboya si ni lati tẹsiwaju ninu iṣẹ ibi.

Abawọle fasiti Greenfield

Oríṣun àwòrán, Greenfield University

"Ti nkan ba ṣe n yi pada, naa lo ṣe koko ki ayipada ba igbesẹ ti eeyan ba fẹ ẹ gbé fun ọna abayọ.

" Nitori naa, imọran ti eeyan kan (gomina) mu wa ni ọpọlọpọ ọdún sẹyin, ko le jẹ ọna abayọ si wahala nla to ti bẹrẹ lati ọdun 2014, botiwu ki wọn o pin fidio naa kiri to."

O ni "pe awọn ọdaran di wa ni gogongo mú, ko tumọ si pe ka fun wọn ni owo ti wọn o tun fi ma a gbe isẹ ọwọ wọn lárugẹ."O ṣalaye pe diẹ ni igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Kaduna le gbe, nitori pe abẹ ìṣàkóso ijọba apapọ ni àwọn ileesẹ eto aabo wa.

Sugbọn ṣa, Gomina El-Rufai sọ pe awọn ti n jiroro pẹlu ijọba apapọ lori ọna abayọ.

Bakan naa lo sọ pe ijọba kẹdun ijinigbe àwọn akẹkọọ náà, ati iku àwọn ti wọn ti pa lara wọn.

Aworan ọlọde to gbe ibọn lọwọ lati koju awọn janduku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn agbébọn tún ti pa méjì lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Greenfield University tí wọ́n jí gbé ní Kaduna

Wọn tun ti ri oku meji lara awọn akẹkọọ Fasiti Greenfield, ti awọn agbebọn ji gbe nipinlẹ Kaduna lọsẹ to kọja.

Ninu ikede ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi sita lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, wọn ni wọn ti gbe oku mejeeji lọ si mọsuari, ti wọn si tun ti sọ fun awọn alasẹ fasiti naa.

Ọjọ diẹ sẹyin ni wọn kọkọ ri oku mẹta lára àwọn akẹkọọ naa ni abule kan nipinlẹ Kaduna.

Kọmisanna fun eto aabo abẹle nibẹ, Samuel Aruwan sọ pe ibanujẹ ni isẹ ibi ọwọ àwọn eeyan naa jẹ fun Gomina Nasir El-Rufai.

"Ibanujẹ ni ikọlu si awọn akẹkọọ ti ko mọ nkankan, lasiko ti wọn n kekọọ wọn fun ọjọ ọ̀la to dara."

Bakan naa ni ijọba ti ránṣẹ ibanikẹdun si ẹbí àwọn akẹkọọ naa.

Abawọle fasiti Greenfield

Oríṣun àwòrán, Greenfield University

Wọn ti kọkọ ri oku akẹkọọ mẹta ṣaaju

Mẹta lara awọn akẹkọọ fasiti Greenfield ti awọn agbebọn kan ji gbe ni ipinlẹ Kaduna ti dero ọrun.

Awọn akẹkọọ naa wa lara awọn akẹkọọ ti awọn agbebọn ji gbe ni fasiti aladani naa to wa loju ọna marosẹ Kaduna si Abuja loru ọjọ Iṣẹgun.

Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin, kọmiṣọna fun eto abo ati ọrọ abẹle ni Kaduna, Samuel Aruwan sọ pe wọn ti ko oku awọn akẹkọọ naa lọ sile igbokusi.

O ni wọn ri oku awọn ekẹkọọ naa ni abule Kwanan Bature, iyẹn lagbegbe ti ko fi bẹẹ jina si fasiti ọhun.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii lawọn agbebọn kan ṣadede kọlu fasiti naa ni Kasarami, lẹba oju ọna marosẹ Kaduna si Abuja, ti wọn si ji awọn akẹkọọ kan gbe lọ.

Oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin pe awọn agbebọn naa ya bo fasiti ọhun, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ, ki wọn to ji awọn akẹkọọ naa gbe lọ.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

Awọn eeyan to n gbe lagbegbe fasiti ọhun sọ pe ile ẹkọ naa, ti gbogbo awọn akẹkọọ rẹ ko ju bii ogoji ko ni eto abo to peye, wọn ni eredi ree to fi rọrun fun awọn agbebọn naa lati kọlu fasiti ọhun.

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn agbebọn bẹrẹ si n ṣakọlu lemọ-lemọ ni ipinlẹ Kaduna, ti wọn si sọ oju da awọn akẹkọọ.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Àwọn agbébọn tún ti jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní fásitì kan ní Kaduna

Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Kaduna lapa iwọ oorun ariwa orilẹ-ede Naijiria ti fidi rẹ mulẹ fun BBC pe awọn agbebọn ti ṣigun wọn fasiti GreeFiel University, ileẹkọ fasiti aladani kan nipinlẹ naa ti wọn si ji ọpọ awọn akẹkọọ ko lọ.

Awọn ọlọpaa pẹlu ni awọn agbebọn naa ya wọ Ileewe giga fasiti naa ti o wa lagbegbe opopona Kaduna si Abuja ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ogunjọ oṣu kẹrin ọdun 2021.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna Mohammed Jalige ṣalaye pe ni bi a ṣe n sọrọ yii, awọn ọlọpaa ko tii le sọ ni pato iye awọn akẹkọs ti wọn ko lọ tabi ibi ti wọn ko wọn gba.

O ni "awọn ọlọpaa ti wa lọgba ileewe naa bayii awọn si ti n beere fun iwe iforukọ silẹ awọn akẹkọọ nibẹ lati lee mọ iye awọn akẹkọọ ti awọn agbebọn naa jigbe salọ"

Inu yara awọn akẹkọọ naa ni wọn ti ji wọn gbe, okunrin ati obinrin pẹlu.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa