Ondo crime: Happiness tó fọ́gi mọ́ orogún rẹ̀, Blessing Emmanuel lórí tó fi kú l'Ondo ti wà láhámọ́ ọlọ́pàá

Afurasi naa atawọn afurasi ọdaran yoku

Oríṣun àwòrán, Thenewstrack.com.ng

Arabinrin Nanko Happiness ni iyale ti Napre Blessing si jẹ iyawo nile arakunrin Emmanuel.

Ọrọ kan lo ṣe bi ọrọ laarin awọn tiyale tiyawo mejeeji yi to fa ija laarin wọn

Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami to ṣe afihan arabinrin Happiness pẹlawọn afurasi ọdaran kan lolu ileeṣẹ ọlọpaa ni lu Akurẹ sọrọ ilẹ kun.

O ṣalaye pe ọjọ keje oṣu, kẹrin ọdun 2021 ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Sunshine Garden Estate, Ọda nilu Akurẹ.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

O fi kun pe Happiness to jẹ iyale yọgi to fi lu iyawo rẹ Blessing lori lasiko ija naa.

Igba ti eyi ko tẹẹ lọrun lo ba tun mu ọkọ iroko ti iyawo rẹ naa to sha lori ati ni ara eleyi ti wọn ni o ṣokunfa iku rẹ.