Àwọn ajínigbé kò jí ẹnikẹ́ni gbé lágbègbè Igboọra sí Eruwa - Ọlọ́pàá Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Kọmiṣọna ọlọpaa n'ipinlẹ Ọyọ, Ngozi Onadeko ti ṣe alaye pe irọ lasan lo wa nidi iroyin to n ja rainain pe awọn eeyan mẹẹdọgbọn bọ si ọwọ awọn ajinigbe laarin wakati mẹrinlelogun ni agbegbe Ibarapa.
Onadeko to ba awọn oniroyin sọrọ l'Ọjọbọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyẹle, niluu Ibadan fi kun ọrọ rẹ pe irọ ti o jina si otitọ ni iroyin naa.
O ni iroyin naa to ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lowurọ Ọjọbọ wi pe awọn agbegbọn ji awọn eeyan kan gbe ni agbegbe Eruwa, pẹlu alaye wi pe ofintoto ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe lo fi idi ọrọ mulẹ wi pe irọ lasan ni iroyin naa.
- Baba Ijesha kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀
- Wọ́n ti sin òkú àwọn èèyàn tó lé ní àádọ́ta tí àwọn agbébọn pa ní Zamfara báyìí
- A ti wà nínú igbó láti ṣàwárí àwọn mẹ́ta tí wọ́n jí gbé ní Ikaramu Akoko - Amotekun Ondo
- Ṣé òtítọ́ ni pé ikú apanilẹ́ẹ̀rín Ada Jesus lọ́wọ́ ayé nínú?
Saaju ni iroyin gba ode kan lọsan Ọjọbọ wi pe awọn agbebọn ṣe ikọlu si ọkọ akero kan, ti wọn si ji awọn ero ọkọ mẹrindinlogun lọ l'opopona Igboọra si Eruwa.
Bakan naa ni iroyin mi i tun sọ pe awọn agbebọn tun ji eeyan meje mi i l'Ọjọru.
Botilẹ jẹ pe arakunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọladiran Ọladokun ni agbegbe Ibarapa sọ wi pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ni oun ṣe ipade pẹlu awọn ọga agba ajọ ọlọpaa ni agbegbe Igboọra ati Ibarapa, wọn si ni iru iṣẹlẹ bẹẹ ko waye rara.
Nibayii, Kọmiṣọna ọlọpaa n'ipinlẹ Ọyọ ti parọwa si awọn olugbe agbegbe naa ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ lati maa lọ si ẹnu iṣẹ wọn lai bẹru ati lai foya, gẹgẹ bi o ṣe n parọwa si wọn lati maa ta ileeṣẹ ọlọpaa ni olobo ki eto aabo le fi ẹsẹ mulẹ si i n'ipinlẹ naa.














