Baba Ijesha: TAMPAN ní ìbànújẹ́ ọkàn ni pé ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ òun hùwà ìdójútini

Baba Ijesha:Ìbànújẹ́ ọkàn ni pé ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ wa hùwà búburú yìí-Tampan

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ eré orí itàgẹ́ ẹ̀ka ti TAMPAN, ti fi ẹ̀dún ọkàn wọn hàn lórí bí wọn ṣe ni ìjákulẹ̀ ọkàn tó nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ẹ̀sùn tí wọn fi kan ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ náà kan, Olarewwaju James, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Baba Ijesha.

Tampan ni oun ri bii ojuse oun lati bu ẹnu atẹ lu iwa biba ọmọde lopọ ti Baba Ijesha jẹ́wọ́ pe oun se, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa se fidi rẹ mulẹ.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí adari ìwádìí fun ẹgbẹ́ náà, Yemi Amodu fọwọ́ sí, TAMPAN fí kún pé, ǹkan ìdójútini gbá à ni, tí ó sì pọ̀ndandan pé kí ẹgbẹ́ tàbùkù ẹni tó hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí ọmọdé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe jẹ́ ǹkan ẹlẹgẹ́, tí ó sì wà lábẹ̀ ìwádìí pẹ̀lú, síbẹ̀ TAMPAN fi yé gbogbo àgbáyé pé, òun kò lè sí lẹ́yìn irú ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ nítórí pé àwọn gan ni oní wàásù tó n sọ̀rọ̀ lòdì sí irú ǹkan báyìí.

Ọrọ ti Tampan kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, tampanglobal/Instagram

" Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ a mọ ìwà, ìṣesí àti ìhùwà sí àwọn ènìyàn wà gẹ́gẹ́ bi oníwàásù.

"Nítorí náà, a kò ní kùnà láti ran ìjọba lọ́wọ́ láti ri dájú pé irú ìwà báyìí dí òhun ìgbàgbé láwùjọ wa"

Ẹgbẹ́ tún bá ẹbi ọmọ tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ̀lẹ̀ sí kẹ́dùn, wọ́n sì rọ gbogbo òbí lápapọ̀ láti máa fún àwọn ọmọ wọn ni àànfàni láti sàlàyé ara wọ́n láì bẹ̀rù tí ìrú nǹkan yìí bá ṣẹ̀lẹ̀ sí wọ́n, kí àwọn ẹni ibi bẹ́ẹ̀ má bá ri ibi sá sí nínú àwùjọ wa.

Àkọlé fídíò, Hisham Wadan: Ìlanilọ́yẹ̀ nípa àrùn ojú ló mú mi ṣe fíìmù Lost in London

"Lákotan ẹgbẹ́ Tampan ni oun dúro fún ìwà jíjẹ ọmọlúwàbí láwùjọ atí àlátẹ̀lé òfin nígbogbo ìgbà.

Amin iyasọtọ kan

Rotimi Makinde ní kí aráàlú má ṣe ìdájọ́ saájú iléẹjọ́, ní aráàlú bá gbanájẹ

Baba Ijesha ati Rotimi Makinde

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha Instagram/Rotimi Makinde Facebook

Ọrọ isẹlẹ to waye nipa gbajumọ osere tiata kan, Olanrewaju James ti n fa oniruuru awuyewuye miran lori ayelujara.

Ọkan lara rẹ ni ti gbajumọ osere miran, Rotimi Makinde, ti ko fi bẹẹ se ere tiata mọ amọ to jẹ asoju sofin tẹlẹ nile asofin agba ilẹ wa, to soju ẹkun idibo Ife.

Makinde lo bọ soju opo Facebook rẹ, to si n rọ awọn araalu to n bu ẹni atẹ lu iwa ti baba Ijesa hu pe ki wọn se suuru, ki wọn jẹ ki idajọ ileẹjọ waye na.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni o yẹ kawọn eeyan tiẹ kọminu tabi siyemeji nipa ẹsun biba ọmọde lopọ ti wọn fi kan baba Ijesa,titi ti ileẹjọ to n gbọ ẹjọ naa ba kede pe afurasi naa jẹbi ẹsun naa.

Ọrọ ti Rotimi Makinde kọ si Facebook rẹ

Oríṣun àwòrán, Rotimi Makinde Facebook

"Mo mọ pe wọn fi ẹsun kan pe o sẹ si ẹsun ti wọn fi kan... abi se ẹsẹ ni ki eeyan jẹ gbajumọ osere tiata ni, ẹ jẹ ka ni suuru, ka si fi ifẹ han si.

Lootọ la n bu ẹnu atẹ lu iwakiwa ni awujọ amọ ẹ dẹkun sise idajọ lọwọ ara yin lori ẹsun biba ọmọde sun ti wọn fi kan afurasi naa.

O dabi ẹni pe ọpọ wa gan la ti ni ninu tẹlẹ lati mu Baba Ijesa walẹ ko to di akoko yii. Iwa ọdaran ko dara amọ iwa kikan afurasi mọ agbelebu gan jẹ iwa ọdaran.

...Lootọ la le se aanu ọmọde ti wọn lo fara gba iwa naa."

Ọrọ ti Rotimi Makinde kọ si Facebook rẹ ati esi araalu

Oríṣun àwòrán, Rotimi Makinde Facebook

Ohun ti Rotimi Makinde kọ soju opo Facebook rẹ ree, ti ọpọ eeyan fi gba ya, ti wọn si n kọ kobakungbe ọrọ si abẹ ọrọ rẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe Makinde ti yọ ọrọ naa kuro loju opo Facebook rẹ amọ sibẹ ko dẹkun lati maa tako iwa idalẹbi tawọn eeyan n hu, tawọn onitọun naa si n da lohun pada.

Koda, Makinde tun kọ ọrọ miran pe ẹja goolu ko ni ibi to le sa pamọ si, ki aye ma rii, to si se adura pe ki Ọba Oke mase jẹ ka di ẹni ilẹlẹ lasiko iporogan.

Ọrọ ti Rotimi Makinde kọ si Facebook rẹ ati esi araalu

Oríṣun àwòrán, Rotimi Makinde Facebook

O ni oun ko fi igba kankan fara mọ ohun ti wọn ni Baba Ijesa se, to si ni ki ẹni ti inu ba n bi lori ọrọ ohun lọ di ina mu.

Ọrọ yii naa lo fun n mu esi to gbona jade lati ẹnu awọn ololufẹ Rotimi Makinde lori ayelujara naa, ti ọpọ wọn si n sọ fun asoju-sofin tẹlẹ naa pe afurasi ti jẹwọ ẹsun ti wọn fi kan.\Wọn ni ọrọkọrọ ni Makinde n sọ lẹnu, ti wọn si ni oun gan buru ju baba Ijesa lọ.

Amin iyasọtọ kan

Baba Ijesa ko si gbaga Ọlọpaa lori ẹsun pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla lopọ

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, @OlofofoMusic

Saaju la ti sọ fun yin pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti fi ṣikun ofin mu gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Olanrewaju James, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Ijesha.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa, Muyiwa Adejobi fi sọwọ si BBC Yoruba, o ni awọn mu Baba Ijesha lori ẹsun pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla ni ibalopọ.

Atẹjade naa ni "Ileeṣẹ ọloọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu Olanrewaju James, ẹni ọdun mejidinlaadọta, ti awọn eeyan mọ si Baba Ijesha lori ẹsun pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla lopọ."

"Obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Princess Adekola Adekanya lo fi ọrọ naa to ile iṣẹ wa to wa ni Sabo leti lọjọ kọkandinlogin, oṣu Kẹrin, ọdun 2021."

Adejobi tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe iwadii ti awọn ṣe fi han pe afurasi naa ti n ba ọmọ ọhun ni ibalopọ lati akoko to wa ni ọmọ ọdun meje.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

O ni "Afurasi naa jẹwọ pe lootọ ni oun ṣe ẹṣun ti wọn fi kan oun."

Adejọbi fi kun pe ẹrọ ayaworan CCTV to wa ninu ile ti iṣẹlẹ naa ti waye tun ka afurasi naa silẹ.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, o si ṣeleri pe idajọ odo ni yoo tẹle iwadii ọhun.

Gbogbo akitiyan lati kan si oṣere naa tabi awọn ojugba rẹ nidii iṣẹ tiata lo ja si pabo.

Àkọlé fídíò, hhhhhh