Nollywood Yoruba: Ẹjọ́ ń bẹ lọ́run fún gbogbo ẹ̀yin tí kò wàásù fáwọn tó ń tẹ lé yín lórí Instagram àti Facebook- Mike Bamiloye

Ẹjọ́ ń bẹ lọ́run fún gbogbo ẹ̀yin tí kò wàásù fáwọn tó ń tẹ leyín lórí Instagram àti Facebook- Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Mount Zion

Gbajugbaja ajinhinrere ninu ere ori itage Kristẹni, Mike Bamiloye ti kilọ fawọn eeyan ti ko sọrọ Ọlọrun fun awọn to tẹ le wọn loju opo Facebook ati Instagram.Bamiloye ni gbogbo awọn ti ko ri nkan gidi fawọn ololufẹ wọn ju awọn nkan ti ko tọ ati nkan amunidẹṣẹ ni yoo jiyin lọjọ idajọ niwaju Eledua Oṣere naa ni ọrọ kọta dọtii ni ọpọ ilumọọka maa n bawọn ololufẹ wọn sọ lori Instagram àti Facebook.

Bamiloye sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn maa jẹ ki awọn to n tẹ le maa pongbẹ lati gbọ ọrọ iye.Oṣere Bamiloye ni "anfaani nla ti ẹ o jiyin lọjọ idajọ ni ẹ n sọnu."O ni ko si ohun to dabi k'awọn eeyan maa fi ọrọ Ọlọrun bọ ọgọọrọ eeyan to n tẹ le wọn loju opo ayelujara Instagram ati Facebook.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Oṣere yii ti maa n sọ nipa igbe aye ododo nigba kugba loju opo ayelujara rẹ.Bamiloye ni oludasilẹ gbajugbaja ileeṣẹ oṣere Kristẹni, Mount Zion Films eleyi to ti gbe oriṣiiriṣii ere jade.

Aworan agbejade mi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àìsàn wo ló dá gbajúmọ̀ òṣèré, Kemi Afolabi wólẹ̀ tí kò fo ṣiṣẹ́ tíátà fóṣu márùn ún báyì

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Kẹmi Afọlabi ti sọọ di mimọ pe ojojo n ṣe ogun ara ogun oun ko le bayii ati pe idubulẹ aisan loun wa lọwọ yii.

Kẹmi Afọlabi fi to awọn ololufẹ leti lori ikanni ikansiraẹni ayelujara rẹ.

Kemi ṣalaye pe oṣu kejila, ọdun 2020 loun lọ sode iṣẹ tiata kẹyin nitori aisan naa ti ko darukọ rẹ.

Amọṣa, o dupẹ lọwọ Ọlọrun fun didasi ẹmi rẹ to si n sọ fawọn ololufẹ rẹ pe oun maa jẹri ọpẹ laipẹ.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

"iṣẹ ti mo gbakẹyin ni #Disẹmb2020 niyi n ko le lọ si ode tiata kankan lọdun #2021 nitori ailera ara mi."

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa