Children replacing their fathers as presidents in Africa: Wo àwọn olórí orílè-èdè ilẹ̀ Áfíríkà mẹ́fà tó rọ́pò òbí wọn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.

Kò ṣẹlẹ̀ rí kan kò wáyé nípa pé ọmọ ń rọ́pò òbí rẹ nínú ètò isèjọba nípa ètò òṣèlú tàbí isèjọba lọ́balọ́ba lágbàyéé.
Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí n sọ ètò isèjọba di nkan ti ọmọ lè jogún lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ tàbí àwọn babáńlá rẹ̀.
Ológun Mahamat Idriss Déby to jẹ́ ọmọ ààrẹ orileede Chad, Idriss Déby ni wọ́n búra wọlé fún lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun lẹ́yìn ikú bàbá rẹ tó farapa lójú ogun to sì gba ibẹ kú.
Yàtọ̀ sí orile-ede Chad, ọ̀pọ̀ àwọn orileede ilẹ̀ Áfíríkà mìíran ló ti yan àwọn ọmọ olórí orile-ede to di olóògbé tàbí tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ jẹ ààrẹ bótilẹ̀ jẹ́ pé èyí kò sí nínú Ìwé òfin orile-ede wọn tàbí bá òfin mu.
- Tọkọtaya tí wọ́n yípadà láti akọ si abo àti abo sí akọ ti bí ọmọ tuntun
- Kére ooo! Oyo, Eko, Ogun atàwọn ìpínlẹ̀ míràn yóò dojúkọ ìṣẹ̀lẹ̀ òmíyale, àyàfi..-
- Akeredolu sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Emfiele, ké sí Buhari láti yanjú ìṣòro àìsí owó naira tuntun
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ṣe lè jàǹfàní ṣíṣe àtìpó ní Britain
Èyí ni àwọn olórí orílè-èdè tó gba oyè òbí wọn:
Joseph Kabila -Democratic Republic of Congo
Orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ni Joseph Kabila ti jẹ ààrẹ láti inú oṣù kini, odun 2001, titi di oṣù kini, ọdún 2019
Lẹ́yìn ọjọ́ Mẹ́wàá tí awọn agbanipa pa bàbá rẹ̀, Laurent-Désiré Kabila ló gorí àlééfà
A bí Joseph ni ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹfà, ọdún 1971, ni ẹkùn Sud-Kivu, ni ìdílé ológun àti olóṣèlú.

Kabila tó jẹ́ ọmọ-ọmọ alákatakítí ni orileede Congo, Laurent Kabila dàgbà o si kàwé ni orile-ede Tanzania.
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alákatakítí tó ń gbógun ti ìjọba ti wọ́n sì ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ láti yọ ààrẹ Mobutu Sese Seko ti Zaire níjọba lọ́dún 1997
Lẹ́yìn tí Laurent di ààrẹ ló dá orúkọ orílè-èdè náà padà sí Democratic Republic of Congo, Ó rán Joseph lọ sí China láti lọ ní ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú iṣẹ́ ológun.
Bi ó ṣe padà dé ní wọ́n fi jẹ olórí àwọn ọmọ ogun orílè-èdè náà.
Ni ọdún 1998 ni Laurent Kabila bẹ̀rẹ̀ si ni bẹnu ìwà kò sí ẹni tó le mú mi àti ìgbésùmọ̀mí, èyí lo sì mu kí ọ̀pọ̀ àwọn orílè-èdè Áfíríkà rán àwọn ọmọ Ogun wọn lọ síbẹ̀.
Lẹ́yìn tí àwọn agbanipa mú ààrẹ Laurent kúrò lọ́nà, wọ́n yan Joseph gẹ́gẹ́ bí ààrẹ tuntun ni ọjọ́ kẹrìndínlógbọ̀n, oṣù kíní, ọdún 2001.
Ọ̀pọ̀ ogún tó ní ìlapa ló ti ṣẹlẹ̀ sí orílè-èdè náà tí nkan sì ti bajẹ́ nítorí wọn kò ní ìjọba tó yanrantí àti Ogun ojoojúmọ́
Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kabila gbìyànjú láti dá àlàáfíà padà sí orílè-èdè naa, síbẹ̀ o ni ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ alátakò.
Kabila sì n gbìyànjú láti mú ìṣọ̀kan bá orílè-èdè naa, lẹ́yìn tí o ṣe àtúngbéyẹ̀wò ìwé òfin orílè-èdè naa lọ́dún 2002 ti wọ́n sì gba ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú láàyè láti díje dupò ààrẹ lẹ́yìn ogójì ọdún tí irú rẹ̀ kò tíì ṣẹlẹ̀.
Kabila jáwé olúborí, tó sì fi ẹ̀yìn alátakò rẹ̀ Jean-Pierre Bemba janlẹ̀ nínú oṣù Kẹ̀wá ọdún 2006.
Ni ọdún 2008, Kabila buwọ́lu ìwé àlàáfíà pẹ̀lú ẹgbẹ́ alákatakítí ogún tó n bá orílè-èdè náà jà, àdéhùn náà padà forísọ́npọ́n lẹ́yìn tí àwọn kan tún padà sí orí omi.
- Tani Mahamat Kaka Idriss Deby tó di aàrẹ̀ tuntun ilẹ̀ Chad lẹ́yìn ìṣekúpani bàbá rẹ̀?
- Ta ni Idriss Deby tí kò bá tún gorí àlééfà ipò aarẹ Chad lẹ́ẹ̀kẹfà tó wá ṣaláìsí yìí?
- NDLEA mú ‘Daddy GO’ ṣọ́ọ̀ṣì tó ń gbé ògùn olóró sínú èpò pupa l’Eko
- 'Lẹ́yìn ìgbàdún ìyàwó púpọ̀, àti tọ́jú adúrú àwọn ọmọ yìí di ti ìṣòro ńlá fún mi'
- Àwọn Wòlìí kan ń sọtẹ́lẹ̀ torí àwọn tó ti fún wọn lówó ni, a ní láti tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ Ọlọ́run – Oyedepo
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn afurasí jàǹdùkú tó kọlù èèyàn mẹ́rin níbi iponlogo ìbò Peter Obi l'Eko
Faure Gnassingbé - Togo
A bí ààrẹ Faure Essozimna Gnassingbé Eyadéma ni ọjọ́ kẹfa, oṣù kẹfà, ọdún 1966, ó jẹ́ olóṣèlú tó sì ti di ààrẹ láti ọdún 2005.
Kí ó tó di ààrẹ Togo, bàbá rẹ̀ ààrẹ Gnassingbé Eyadéma, tí fún ni oyè mínísítà láti 2003 sí 2005.
Nígbà tí ààrẹ Eyadéma kú ni ọdún 2005 Gnassingbé ni wọ́n sáré yàn bí ààrẹ tuntun láti gbárùkù ti àwọn ológun.
Ọ̀rọ̀ lórí bóyá òfin orílè-èdè náà fàyè gba irú ǹkan bẹ́ẹ̀ fi Gnassingbé sábẹ́ wàhálà púpọ̀, bákan náà ló jáwé olúborí nínú ìdíje ààrẹ ni ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kẹrin, ọdún 2005, wọ́n sì búra wọlé fún gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.
Wọ́n tún Gnassingbé yan ni ọdún 2010, àwọn ẹgbẹ́ alátakò yarí pé kò ní sí àtúndì ìbò, èyí sí jẹ kí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò tí ọ̀pọ̀ sá kúrò ní ibùgbé wọn.

Mahamat Idriss Déby - Chad
Ààrẹ tuntun ti Chad, Mahamat Idriss Déby, jẹ́ ológun ti kò tíì pé ọmọ ogójì ọdún ló gbà ipò bàbá rẹ̀, ààrẹ Idriss Deby Itno tó kú ní ogúnjọ́, oṣù kẹrin, ọdún 2021.
Ọdún 1983 ni a bí Mahamat Idriss Déby gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú ọmọ Idriss Déby tó dolóògbé
Ọ̀pọ̀ ló máa ń pè é ni Mahamat Kaka nítorí ìyá àwọn òbí rẹ̀ ló tọ̀ọ.

Lásìkò tí bàbá rẹ̀ kú, òun ni olórí àwọn ẹ̀sọ́ ààbò ààrẹ gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn BBC tó wà ni Chad ṣe sọ.
Bákan ni o ti kópa nínú onírúurú Ogun.
Ni ọdún 2009, Mahamat Idriss Deby ti jagun lorisirisi ni Am Dam tí òun ati ẹbi rẹ̀ Timan Erdimi to tún jẹ́ ẹbí ààrẹ Eastern Chad.
Ali Bongo Ondinba - Gabon
Ààrẹ Ali Bongo Ondimba jẹ́ ọmọ ààrẹ Gabon, Omar Bongo, tó jẹ ààrẹ láti ọdún 1967 títí o fí kú ní ọdún 2009.
Ààrẹ Gabon ni ààrẹ kẹta láti Oṣù kẹwàá, ọdún 2009, lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú
A bí ni Gabon ni inú oṣù kejì, Odun 1959 sí ìdílé Ali Bongo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Alain Bernard Bongo ni agbègbè Congo-Brazzaville.
Ọdún mẹ́jọ ni nígbà tí bàbá rẹ̀ di ààrẹ ni ọdún 1967, asọ̀tàn orílè-èdè France François Gaulme sọ fun BBC.
Ayé ààrẹ Ali Bongo kún fún ílà-ílo pàápàá jùlọ nígbà tó wà ní ọ̀dọ́kùnrin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kódà, láti ìgbà tí wọ́n tí bí ní wọ́n tí máa n sọ̀rọ̀ ahesọ pé wọ́n gbáàtọ́ ni lati ìhà gúúsù ìlà-oòrùn Nàìjíríà lásìkò ogún abẹ́lé
Àwọn mìíràn ríi gẹ́gẹ́ oluṣègbè fábo tí ó sì fẹ́ran epo rọ̀ọ̀bì orílè-èdè Gabon
Àìsàn to daa wólẹ̀ ni ọdún dïẹ̀ sẹ́yìn jẹ́ èyí tó ń kọ orílè-èdè náà lóminú, ìdìtẹ̀gbàjọba tí àwọn ọmọ ogún ṣe pẹ̀lú f'ori sánpọ́n.
Ìdí tí wọ́n fi fẹ́ dìtẹ̀ gbà jọba ni pé àwọn fẹ́ dá orílè-èdè náà padà sí bí ó ṣe yẹ kí ó wà lẹ́yìn ìdìbò odun 2016, tí o mú ìtàjẹ̀ silẹ̀ àti wàhálà dání.
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn àdúgbò tó ta lẹ́nu jùlọ nílùú Ibadan
- Àwọn agbébọn ṣekúpa DPO àti ọlọ́pàá mẹ́rin mìíràn ní Niger
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ àwọn tó ń kó ìbọn wọ ìpínlẹ̀ Oyo lábẹ́ ìbòjú ìwọ́de Naira tuntun – Kọmísọ́nà ọlọ́pàá Oyo
- NDLEA mú ‘Daddy GO’ ṣọ́ọ̀ṣì tó ń gbé ògùn olóró sínú èpò pupa l’Eko
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ibi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé? Kínni pàtàkì ibi ọmọ?
Ọba MuhammEd Bin Sidi Alaouite
Ọba Muhammed Bin Sidi Alaouite ti Morocco ni a bi ni ọjọ́ kọkànlélógun, Oṣù Kẹjọ, ọdún 1963, ni Rabat tíì ṣe olu ilu Morocco.
O gorí àlééfà ni ọjọ́ kẹtàlélógun, oṣù keje odun 1999, lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀, Ọba Hassan Keji kú.
Ni kété tó gorí àlééfà ló kéde lórí amohunmaworan pé òun yóò gbógun ti, òsì, ìwà àjẹbánu bákan náà ni òun yóò pèsè isẹ àti lati mú kí ètò fifaaye gba ẹ̀tọ́ ọmọ nìyàn búrẹ́kẹ síi.
Ẹ̀wẹ̀ àwọn àyípadà yìí bi àwọn alákatakítí ẹṣin Islam kan nínú.
Nínú oṣù kejì ọdún 2000, o ṣe àgbékalẹ̀ òfin ìdílé mìíràn, èyí tó fi ààyè gba ìrọkunsápá obìnrin.
Nínú oṣù Kejìlá ọdún 2020, Oba Mohammed kẹfà gba láti tún ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú orílè-èdè Israel lábẹ́ àdéhùn tí ìjọba ilẹ̀ Amẹrika yóò fi ṣe ni túmọ̀ nílẹ̀ Africa labẹ àkóso Morocco.
- Wo bí àwọn gbájúẹ̀ ṣe lu ìyá ẹni ọdún 90 ní jìbìtì $32 mílíọ́nù dọ́là
- Irọ́ ni o! A kò gbé ìgbésẹ̀ láti dìtẹ̀ gbàjọba ṣáájú ìdìbò Naijiria – Iléeṣẹ́ ológun
- Wo àwọn 'App' tó ń ba fóònù jẹ́ ní Nàìjíríà
- Gbogbo ìlérí tí mo ṣe fún ọmọ Nàìjíríà ni mo ti mú ṣẹ - Ààrẹ Buhari
- Ètò ìdóòlà ẹ̀mí níbi àjálù ilẹ̀ ríri ní Turkey, Syria kò ní pẹ́ wá sópin - Àjọ UN
Oba Mswati III ti Eswatini
Ọba Mswati III (Makhosetive) jẹ́ ọmọ ọba Sobhuza II ti ọkan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀, Ntfombi Tfwala bí.
A bí ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù kẹrin, ọdún 1968 ni Manzini.
Ó jẹ́ ọmọ òye Mswati kẹta ni Ingwenyama tí o sì padà di ọba ni Swaziland ni ọjọ́ karùn-úndínlọ́gbọ̀n 1986, lẹ́ni ọdún méjìdínlógún, òun sì ni ọba tí ó kéré jùlọ lágbàyé lásìkò náà
Ọba Sobhuza kejì kú ní ọjọ́ kokanlelogun, inú oṣù kẹjọ, ọdún 1982, ti ọmọ ọba Makhosetive sì di empirọ̀ tuntun.




















