NDLEA mú ‘Daddy GO’ ṣọ́ọ̀ṣì tó ń gbé ògùn olóró sínú èpò pupa l’Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, NDLEA/Facebook

Ajọ to n gbogun ti gbigbe egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti fi panpẹ ofin mu adari ati oludasilẹ ilejọsin Seraphic ati Sabbath, Nnodu Azuka, akẹkọ ile ẹkọ Emmanuel College of Theology, Udezuka Udoka ati ẹni Oyoyo Mary Obasi ni paapa ofurufu Murtala Muhammed nipinlẹ Eko lori ẹsun pe wọn gbe egbogi oloro sinu epo pupa, ti wọn si fẹ gbe lọ orilẹede United Arab Emirate.

Agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi lo kede ọrọ lori opo ayelujara rẹ lọjọ Aiku ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2023.

O ni ọwọ tẹ Daddy GO lẹyin ti ọwọ tẹ awọn afurasi yooku lọjọ kẹsan oṣu keji ọdun 2023.

“Ọwọ tẹ Daddy GO! Ẹni ti sa lọ ba lati ri oju rere Ọlọrun, ni o lọwọ ninu gbigbe egbogi oloro.”

Babalola tẹsiwaju pe ninu ọrọ Mary lo darukọ olusọ naa pe oun ati ọmọ rẹ, Chisom Obi, ẹni to ti salọ bayi gbe egbogi oloro naa fun oun fun irinajo lẹyin ti wọn ta ẹjẹ adiẹ silẹ ni ile jọsin, ti olusọ si gba adura fun.

“Mary sọ fun ninu ọrọ ti a gba silẹ pe Olusọ ati ọmọ rẹ ma dunkoko mọ oun to oun ba kọ lati ba wọn sisẹ nitori wọn mọ pe oun mọ asiri wọn.

“O ni Olusọ ni orukọ to ma pe egbogo oloro, eyi to pe ni ‘Ice and Bible’

Babalola ni akẹkọọ ti ọwọ tẹ pẹlu Olusọ, Udezuka ni wọn gba lati ma ran Mary lọwọ ninu isẹ ibi naa.

“Udezuka ni milọnu meji naira ni oun gba fun isẹ naa, ti o si ṣe nitori pe o nilo owo fun eto ẹkọ rẹ.”