'Lẹ́yìn ìgbàdún ìyàwó púpọ̀, àti tọ́jú adúrú àwọn ọmọ yìí di ti ìṣòro ńlá fún mi'

“Eeka ilẹ meji pere ni mo jogun lọdọ̀ baba mi, ibẹ naa ni mo kọle si ti mo si bi gbogbo awọn ọmọ yii si amọ o ti di iṣoro nla fun mi bayii”.
O ṣalaye pe oun ti ni ọpọlọpọ iṣoro ti oun n koju bayi.
“A ti ran ọmọ lọ ile ẹkọ, pipese ounjẹ fun gbogbo wọn, aṣọ wiwọ ...”
Bi Musa ko tilẹ ranti orukọ gbogbo awọn ọmọ rẹ, o ni iwe to kọ orukọ gbogbo awọn ọmọ rẹ si to fi mọ deeti ọjọ to bi wọn.
Musa ṣalaye pe nigba ti awọn rii pe gbogbo awọn yii ti n pọju loun ati gbogbo awọn iya wọn jọ pinu pe ki wọn lọ ṣe ifetosọmọbibi ki iye wọn ma baa tun lọ soke.
“Mi o mọ pe ọkọ mi tun maa fẹ ọpọlọpọ iyawo lẹyin wa.”
Iyawo Musa kẹta ba BC sọrọ, o ni nigba toun rii pe o gbe iyawo mii, oun binu gan oun si faraya.
Amọ ko kuku lodi si ofin ni ilu Musa, orilede Uganda lati fẹ iyawo pupọ.
Orilẹede Uganda jẹ ọkan lara awọn orilẹede agbaye ti awọn eeyan ti n bi ọmọ to pọ ju.






