''Ìjoͅba ìbílẹ̀ 300 nínú 774 ni kò ní báńkì, CBN, eͅ gbé jéͅ''

Igbakeji alaga eͅgbeͅ osͅelu APC ni ariwa orileͅede Naijiria, Salihu Lukman ti fi aidunnu reͅ han si igbeseͅ ileesͅeͅ Banki apapoͅ Naijiria, CBN lori atunse owo naira ni Naijiria.
Lukman ni oͅroͅ naa gbeͅnutan nitori pe o kere tan, ijoͅba ibileͅ oͅoͅdunrun ni ko ni ile ifowopamoͅsi lagbegbe woͅn lorileͅede Naijiria.
O ni o sͅe ni laanu pe awoͅn gomina ko lee ba aareͅ Buhari soͅroͅ pe ko yi ero reͅ pada lori igbeseͅ owo naira tuntun naa.
Ninu ateͅjade to fi lede to pe akoͅlee reͅ ni “Cashless Economy and Presidential Cabal”, lo ti fi ero reͅ han.
Salihu Lukman sọrọ yii lẹyin ti ileeͅjoͅ to ga juloͅ lorileͅede Naijiria pasͅeͅ pe ki CBN dawoͅ duro lori igbeseͅ naa ni kiakia.
Ileeͅjoͅ ni gbedeke oͅjoͅ keͅwaa ti ijoͅba apapoͅ fun awoͅn eniyan lati mase naa owo naira moͅ ko lee sͅeesͅe nitori yoo fa inira fun awoͅn araalu.
Igbakeji alaga eͅgbeͅ oselu APC naa ni gomina ajoͅ CBN ko ro ti awoͅn meͅkunnu to jeͅ pe ida moͅkandinlogoji nikan lo ni apo isͅuna ninu woͅn.
‘’A ni awoͅn ijoͅba ibile to le ni oͅoͅdunrun ti woͅn ko tileͅ ni ile ifowopanoͅsi lagbegbe woͅn rara, koda woͅn ko tileͅ ni apo isuna Kankan peͅlu banki.’’
‘’Bawo ni aye sͅe feͅ roͅrun fun awoͅn eniyan yii nigba ti ijoͅba ba gbe iru igbeseͅ beͅeͅ.’’
‘’O sͅeni laanu pe CBN ko wo gbogbo awoͅn ipenija yii ki woͅn to gbe igbeseͅ pe lori gbedeke fun awoͅn eniyan lati na owo naira ti teͅleͅ naa.’’
Bakan naa lo fikun un pe ko si ami idaniloju pe igbeseͅ naa niise peͅlu dideͅku jiji ibo tabi rira ibo awoͅn oͅmoͅ Naijiria.
Lukman wa kesi aareͅ Buhari ati awoͅn gomina leͅgbeͅ osͅelu APC lati sͅisͅeͅ poͅ ki woͅn wa oͅna abayoͅ si oͅroͅ owo naira yii, ki ohun gbogbo le roͅrun fun araalu.
Ọjọ́ méje ti pẹ́ jù láti wá ojútùú sí ìnira tí owó Náírà ń kóbá ará ìlú - Afenifere sí Buhari

Oríṣun àwòrán, Collage
Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti sọ fún Ààrẹ Muhammadu Buhari pé ọjọ́ méje tó bèèrè fún láti wá ojútùú sí làásìgbò tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú lórí ọ̀rọ̀ owó Náírà tuntun ti pọ̀jù.
Afenifere nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ wọn, Jare Ajayi fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kejì ọdún 2023 ní ọjọ́ méje tí ààrẹ Buhari ń bèèrè fùn ṣàfihàn rẹ̀ pé ààrẹ kò tara sí wàhálà tí àwọn ènìyàn ń kojú láti rí owó ná.
Ajayi ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ní owó nínú akoto àsùnwọ̀n báǹkì wọn àmọ́ tí wọn kò rí owó náà gbà èyí tó ń kó ọ̀pọ̀ ìnira bá wọn.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti nù, tí okoòwò mìíràn ti dojúdé nítorí àìrí owó ná, fún ìdí èyí, ọjọ́ méje tí ààrẹ Buhari dá tún mọ̀ sí pé kí wọ́n máa jẹ̀yà lọ fún ọjọ́ méje si.
Ajayi ṣèrántí pé ní ọjọ́ Ẹtì ni ààrẹ Muhammadu Buhari lẹ́yìn ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú àwọn gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC ní kí ọjọ́ mẹ́wàá tí CBN fi kún gbèdéke ọjọ́ tí owó àtijọ́ yóò kásẹ̀ nílẹ̀ ni àwọn yóò wá ojútùú sí ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.
Àwọn gómìnà ọ̀hún ló lọ bá ààrẹ láti ṣe àgbéyẹ̀wò gbèdéke tí wọ́n fún àwọn ènìyàn ìnira tí àwọn ń kojú náà ń pa iṣẹ́ rere tí ààrẹ ti se rẹ́ kúrò lọ́kàn àwọn ènìyàn.
Agbẹnusọ Afenifere ọhun fi kun pé kò jọ́ wí pé ààrẹ ní ohun pàtó kan tó fẹ́ ṣe lásìkò tó fi ọ̀rọ̀ náà léde nítorí kò jọ wí pé àyípadà kan gbòógì kan tó ti wáyé láti ìgbà náà.
Ó tẹ̀síwájú pé Afenifere wòye láti dá sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ nítorí ewu ńlá tá àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú nítorí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù àti owó Náírà.
Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ báyìí ń fẹ́ àmójútó ní kíákíá nítorí àti dín ìdààmú àwọn ọmọ Nàìjíríà kù.
Ó ní ó ṣeni láàánú pé àwón ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí níbi àwọn ìwọ́de tó wáyé ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè yìí.
Ajayi ní ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ sí ilé ìfowópamọ́ láti lọ gba owó wọn ni wọ́n ń rí ìjákulẹ̀ nítorí báǹkì kọ̀ ;áti fún wọn ní iye owó tí wọ́n fẹ́ gbà dípò bẹ́ẹ̀ owó kékeré ni wọ́n ń fún wọn.
Bákan náà ló ní tó bá jẹ́ wí pé owó Náírà ti ń so èso rere èyí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà, Godwin Emefiele ní ó so, kò yẹ kí làálàá tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú pọ̀ tó bá yìí.
Ajayi tún ké sí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ àti àwọn mìíràn tí kò jẹ́ kí owó náà tàn kalẹ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà bẹ́ẹ̀.
Ó ní ìwà bí àwọn ilé ìfowópamọ́ ṣe kò owó pamọ́ dípò kí wọ́n ko sínú maṣíìnì ATM wọn èyí fídíò rẹ̀ ti gba ìgboro kan kù díẹ̀ káàtó.
Ó parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti rọ ààrẹ Buhari láti pàṣẹ fún CBN láti kó owó náà jáde lọ́pọ̀ yanturu kí ayé le di gbẹdẹmukẹ fún mùtúmùwà.















