Ominú ń kọ ọmọ Nàíjíríà lórí bóyá kí wọn máa ná Naira àtijọ́ lọ ni tàbí owo tuntun nìkan

Oríṣun àwòrán, CBN
Awọn ọmọ Naijiria ni ko tii mọ odo ti wọn yoo da ọrunla si nidi lilo owo naira, boya ki wọn maa na Naira tuntun lọ ni tabi ti atijọ tabi maa na mejeeji papọ.
Idarudapọ naa si lo n waye nitori bi ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa se wọgile gbedeke ọjọ Kẹwa osu keji ti CBN fi lelẹ fun lilo Naira atijọ.
Kete ti idajọ naa waye, si ni ijọba apapọ ti morile ile ẹjọ to ga julọ pada pe ko wọgile ẹjọ kan tawọn gomina APC pe, eyi to n tako atunse Naira naa.
Ni bayii ti gbedeke ti CBN fi lelẹ naa pari lọjọ Ẹti ana, banki apapọ ilẹ wa, CBN ati ijọba apapọ ko ti kede pato ohun ti yoo sẹlẹ, si irufẹ owo Naira ta maa lo.
Amọ ọmọ Naijiria ko si ti mọ boya ki wọn maa na owo Naira atijọ lọ ni tabi tuntun nikan ni ki wọn maa lo tabi mejeeji.
Awọn ọmọ Naijiria ni ileepo atawọn ibudo itaja ko gba Naira atijọ mọ
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria si lo ti n kọminu lori isẹlẹ yii nitori ko ye wọn mọ.
Koda, ọpọ Banki olokoowo lo n fi iwe ransẹ sawọn onibara wọn pe gbedeke ti CBN fi lelẹ fawọn ti kọja, owo tuntun lo ku tawọn yoo maa lo.
Meeli tawọn banki kan fi ransẹ sawọn onibara rẹ lori gbedeke naa lọjọbọ ati lọjọ Ẹti fihan pe gbedeke CBN naa n fidi mulẹ.
Ọpọ awọn eeyan to si ba BBC sọrọ lori isẹlẹ yii lo n gbara ta pe awọn ileepo atawọn ibudo itaja kan ti n fariga lati maa gba Naira atijọ lọwọ awọn.
Alaye wọn ni pe wọn ti pasẹ fawọn lati ye lo owo naa mọ
Ijọba ni oun yoo tẹle asẹ ile ẹjọ to fi wọgile gbedeke ọjọ ti lilo Naira atijọ mọ amọ awọn eeyan kan si n kọ owo atijọ
Bakan naa lo tun kede pe oun yoo tẹle asẹ ile ẹjọ naa eyi to fi wọgile gbedeke ọjọ ti lilo Naira atijọ mọ.
Sugbọn o se ni laanu pe ọpọ ọmọ Naijiria ni ko tẹle ikede ijọba naa.
Minisita feto idajọ, Abubakar Malami,sọ fun BBC pe nitori asẹ ile ẹjọ naa lori ẹjọ tawọn gomina APC pe, oun gba ki wọn maa na owo atijọ lọ
O ni "Ijọba ni ẹtọ lati ba ile ẹjọ sọrọ, ko le se alaye lẹkunrẹrẹ nipa ohun ta mọ lori igbesẹ CBN naa,.
Eleyi yoo si ran ileẹjọ lọwọ nidi idajọ ti yoo gbe kalẹ lori ọrọ yii.”
O wa yan pe niwọn igba ti ile ẹjọ ti gbe asẹ kalẹ nidi lilo Naira atijọ, ẹtọ ijọba ni lati tẹle asẹ naa.
Ipinnu yii si lo waye lasiko yii ti igbimọ majẹkobajẹ nilẹ wa rọ banki CBN lati pese owo tuntun ti yoo to ọmọ Naijiria na tabi ko da owo atijọ to ti gba sita fun nina.
Igbimọ majẹkobajẹ naa ni eyi nikan ni ọna abayọ si isoro ilẹ yii nitori isoro nla lawọn araalu n koju nidi riri owo na.
Ijọba apapọ fẹ ro awijare tiẹ lori idi ti atunse Naira fi gbọdọ waye
Ironu nla si lo bawọn ọmọ Naijiria to ba BBC sọrọ, wọn ni nigba tawọn eeyan ko gba owo atijọ mọ lọwọ awọn, ko si owo tuntun rara nilẹ ti awọn fẹ na.
Ọpọ olokoowo ti ọrọ yii kan, si lo n fi ika hanu fun wa pe akoa nla nla ni igbesẹ yii ti da si awn lọrun nidi okoowo awọn.
Koda, awọn eeyan to n ta eroja oun tẹnu n jẹ eyi to le tete bajẹ, bii ata, eso atawọn eroja miran lo n bu sẹkun nitori aita ọja, ti eroja wn si n bajẹ mọ wọn lọwọ.
Idarudapọ nla si lo n ba awọn ọmọ Naijiria lori boya ki wọn maa na owo atijọ abi tuntun
Nibayii, ijọba apapọ ti setan lati ro awijare tiẹ nigba ti igbẹjọ ba bẹrẹ nile ẹjọ to ga julọ lori idi ti atunse Naira fi gbọdọ duro ati idi ti gbedeke lilo naira atijọ mọ fi gbọdọ waye.
A fara mọ́ lílo owó Naira tuntun tí CBN ṣe - Ìgbìmọ̀ májẹ̀kóbàjẹ́ Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli
Igbimọ majẹkobajẹ ni orilẹede Naijiria ti ṣe atilẹyin fun amulo owo Naira tuntun ti banki apapọ CBN gbe kalẹ.
Amọ igbimọ majẹkobajẹ naa wa rọ Gomina banki CBN, Godwin Emefiele lati ri daju pe owo naira tuntun wa fun lilo tabi ki banki apapọ fi awọn owo naira atijọ sita fun nina.
Agbẹjọro agba fun orilẹede yii Abubakar Malami, Gomina Ipinlẹ Eko àti akẹẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Taraba pẹlu agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Femi Adesina lo kọwọrin lati ba awọn akọroyin sọrọ, lori abajade ipade aarẹ ati awọn igbimọ majẹkobajẹ naa.
Nigba toun naa n bawọn akọroyin sọrọ, Malami ni ọrọ meji ni igbimọ majẹkobajẹ naa sọrọ le lori.
"Igbimọ majẹkobajẹ rọ Emefiele lati ri wi pe owo wa fun awón ọmọ Naijiria lati na"
Malami ni ohun akọkọ ti wọn fẹnu ko le lori ni bi eto idibo to n bọ yoo se kẹsẹjari.
Alaga ajọ eleto idibo, INEC, Mahmood Yakubu ati Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpa, Alkali Baba, ṣalaye pe gbogbo eto lo ti to lati ri pe idibo naa yọri si rere.
Malami ni koko keji ni ọrọ owo naira tuntun eyi to ni igbimọ majẹkobajẹ naa sọrọ le lori julọ.
O ni igbimọ naa wa rọ Emefiele lati ri wi pe owo wa fun awón ọmọ Naijiria lati na.
Igbimọ majẹkobajẹ naa salaye pe eyi ni yoo jẹ ki iya to n jẹ awọn ọmọ orilẹede yii dikun, paapaa julọ, lori iṣoro airi owo tuntun na.
Malami ni “oun to ni i ṣe pẹlu atunse owo naira tun wa lara ọrọ ta sọ, atunse naira tuntun naa si duro.
Sugbọn igbimọ majẹkobajẹ naa wa gba banki apapọ CBN nimran lati pese owo naira tuntun fun lilo."
Awọn eeyan to jẹ ọmọ igbimọ majẹkobajẹ ni Naijiria ni aarẹ to wa nipo ati igbakeji rẹ, awọn aarẹ to ti se ijọba kọja, awọn gomina to wa nipo lọwọ bayii ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹ wọ́gílé ẹ̀jọ́ tàwọn gómìnà APC pè tako àtúnṣe Naira tí CBN ṣe, kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ - Malami

Oríṣun àwòrán, others
Minisita feto idajọ lorilẹede Naijiria, Amofin agba Abubakar Malami ti rọ ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lati wọgile ipe awọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria to tako ilana atunṣe owo Naira tuntun ti banki apapọ gbe kalẹ.
Ninu ọrọ to fi tako ipe naa, eyi ti awọn agbẹjọro rẹ, Mahmuh Magaji ati Tijanni Gazali gbe kalẹ, ijọba apapọ rọ ileẹjọ lati mase kọbi ara si ipe naa nitori ko lẹsẹ nilẹ rara.
Iwe ẹjọ ti jade lọjọ Kẹjọ oṣu keji, ọdun 2023 ni “ Ipe yii ko fi ẹri kankan han pe olujẹjọ jẹbi ohunkohun,”
Wọn ti beere pe ileẹjọ wọgile ipe naa nitori ko ni ẹsẹ nilẹ rara.
“Ipe awọn ipinlẹ mẹta ko ki ṣe ipe fun orilẹede amọ ipe lati gbogun ti ijọba apapọ ati ẹka ijọba, CBN ni.
“Ijọba apapọ yatọ si orilẹede Naijiria, wọn gbe ipe yii jade nitori wọn tako ijọba apapọ ni.
Ọsẹ to kọja ni awọn agbẹjọro agba lawọn ipinlẹ mẹta lo pe ijọba apapọ lẹjọ naa nigbati Abubakar Malami to jẹ agbẹjọro agba fun ijọba apapọ yoo jẹ olujẹjọ.
Awọn gomina mẹtẹtẹta naa, Kaduna, Zamfara ati Kogi n jiyan pe afikun ọjọ mẹwaa ti ijọba fi lelẹ ko lee tan inira ti eto ayipada owo naa n mu ba araalu.
Awọn gomina mẹtẹta n fẹ ki ijọba apapọ jawọ lori fifi gbedeke le ayipada owo naa.
Wọn ni labẹ ofin to de idasilẹ banki apapọ Naijiria, CBN Act, abala ogun ẹsẹ kẹta rẹ fihan pe Banki apapọ ko ni agbara tabi aṣẹ kankan lati fi gbedeke ọjọ si ori ayipada owo si tuntun.

















