‘’Èͅsͅẹ̀ tí n kò moͅ ǹkankan nípa rẹ̀ ló gbé mi dé ọgbà èͅwòͅn, ti mo sì pàdánù kíndìnrin mi’’

Aworan

Arakunrin Chikodi Mneregini ti soͅ iriri reͅ lori bi o sͅe di ero oͅgba eͅwoͅn leͅyin ti woͅn mu u fun eͅsun ti ko moͅ oͅwoͅ tabi moͅ eͅseͅ nipa reͅ.

Chijoke ni oun feͅreͅ lo ju oͅdun meji loͅ ni oͅgba eͅwoͅn leͅyin ti oͅloͅpaa mu oun fun eͅsun ti oun ko moͅ nkankan nipa reͅ.

‘’Nigba ti oͅloͅpaa fi panpeͅ mu mi, woͅn fi foonu toͅ ipaseͅ mi, ti woͅn si fi mi han ni gbangba ni adugbo.’’

’Nigba ti awoͅn eniyan bere pe iru eͅsͅeͅ wo ni mo sͅeͅ, ohun ti woͅn n soͅ fun awoͅn eniyan ni pe mo loͅwoͅ ninu ijinigbe.’’

Arakunrin Chikodi to soͅ iriri reͅ fun BBC Pidgin ni o sͅeͅ wa lati ilu Abia amoͅ woͅn bi si ilu Eko.

''Eͅsun aloͅniloͅwoͅgba ni woͅn fi kan mi.''

Chikodi ni leͅyin ti oun kuro ni ile baba ati iya oun ni oun loͅ gba yarakan ni ilu Eko.

Lasiko yii ni oun gba oͅmoͅkunrin kan si ile leͅyin ti awoͅn pade ni ilu Eko, ti woͅn si joͅ n gbe papoͅ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Geͅgeͅ bi oͅroͅ reͅ, oͅmoͅkunrin naa jeͅ osͅisͅeͅ eto aabo ni ileesͅeͅ naa, ni awoͅn oͅloͅpaa ba mu u pe ki o loͅ mu eͅni ti woͅn joͅ n gbe wa, ti woͅn joͅ padipoͅ lati jale nibi ti oͅkunrin naa ti n sͅisͅeͅ.

‘’Laleͅ oͅjoͅ naa ni boͅboͅ oͅun loͅ si ibi isͅeͅ to si pemi lori foonu pe, oun ko ni pada wa si ile moͅ, ati pe ti eͅnikeͅni ba bere reͅ, ki o sͅoͅ fun woͅn pe oun ko gbe ibeͅ moͅ.’’

‘’Mo bere loͅwoͅ reͅ pe se nkankan sͅeͅleͅ ni ileesͅeͅ reͅ naa ni to si ni ko si nkankan to sͅeͅleͅ.’’

‘’O ni leͅyin oͅjoͅ naa oun ko tun fi oju gan an ni oͅmoͅkunrin naa titi di oni.’’

‘’Lati ilu Eko, awoͅn oͅloͅpaa gbe mi loͅ si Benin, amoͅ ti woͅn fi mi sileͅ leͅyin ti woͅn gba beeli mi fun eͅgbeͅrun loͅna aadoͅta naira.Iya mi lo sakiri lati ri owo beeli oͅun.’’

‘’Leͅyin naa ni woͅn tun fi panpeͅ gbe mi, ti woͅn tun fi mi sileͅ. Ni eͅleͅeͅkeͅta, panti ni woͅn gbe mi loͅ , ti mo si wa nibeͅ fun oͅseͅ meji gbako.’’

‘’Ni gbogbo asiko Endsars ati Covid-19 , oͅgba eͅwoͅn ni mo wa.’’

‘’Leͅyin naa ni woͅn tun gbe mi pada loͅ si ileeͅjoͅ, tii woͅn si fi eͅsun ole jija, fifoͅle ati iditeͅmoͅni kan oun.’’

‘’Lati ibeͅ ni mo ti di ero kirirkiri ni Ikoyi, ti mo si loͅ oͅdun meji nibeͅ.’’

Aworan

‘’Mo padanu kidinrin mi ni oͅgba eͅwoͅn’’

‘’Iriri mi ni oͅgba eͅwoͅn buru jai, kii se ohun to yeͅ ki eniyan eͅleͅran ara la koͅja ni.’’

‘’Oͅgba eͅwoͅn ti ko yeͅ ko ju eniyan 800 to yeͅ ko wa nibeͅ, o le ni 2000 eniyan to wa nibeͅ.’’

‘’Ni aaroͅ, eͅwa olomi ni a ma n jeͅ, ni oͅsan, ao mu gaari, ni aleͅ a o mu garri tabi ki a jeͅ ireͅsi funfun.Awoͅn ounjeͅ yii, aja a tileͅ koͅ oͅ.’’

‘’Bi ibeͅ ti gbona to ,to mu orun ni oͅkan lara awoͅn eͅleͅwoͅn bii ti emi gbeͅmi mi si.’’

‘’O seese ko jeͅ ohun lo da wahala si agoͅ ara mi, ti mo si beͅreͅ si ni se aisan, ti woͅn si ni mo ni aisan kidinrin, eleyii to fa kin maa ru, amoͅ ti ikun mi si n tobi si.’’

Leͅyin ti Chikodi gba itusileͅ ni o loͅ se isͅeͅ abeͅ nibi ti woͅn ti paaroͅ kidinrin reͅ, ti woͅn si yoͅ eleyii to ti bajeͅ kuro.

Bi Chikodi se gba itusileͅ…

Aworan

Lasiko igbeͅjoͅ reͅ to n loͅ si ileeͅjoͅ naa ni oͅkan ninu awoͅn agbeͅjoͅro naa ti siju aanu wo o, to sig be oͅroͅ reͅ lori.

Agbeͅjoͅro naa lo fihan fun adajoͅ pe ko tileͅ moͅ oͅwoͅ moͅ eͅseͅ ninu eͅsun ti woͅn fi kan an .

Amoͅ o di ero eͅwoͅn nitori woͅn ko ri eͅni ti woͅn fi eͅsun kan.

Ni Ogunjoͅ, Osu keͅrin, oͅdun to koͅja ni adajoͅ fi sileͅ fun ajoͅ Justice Project lati gba sileͅ.

Lͅeͅyin ti woͅn gba itusileͅ mi ni mo to moͅ pe ajoͅ ajafeͅtoͅ oͅmoͅniyan ni woͅn, ti woͅn si pe orukoͅ woͅn ni ‘’Justice project’’’

Adari ajoͅ naa ni awoͅn ti gba awoͅn eniyan bii Chikodi to le ni oͅgboͅn eniyan to jeͅ pe eͅseͅ aimoͅdi lo gbe woͅn de oͅgba eͅwoͅn.

Aworan

Ba wo ni igbe aye Chikodi leͅyin to kuro ni oͅgba eͅwoͅn?

Ki Chikodi to di ero oͅgba eͅwoͅn, iseͅ awoͅn to n koͅle lo n se, to si tun ni oye sͅise isͅeͅ ni ile ounjeͅ.

O ni bi oͅloͅpaa se fi panpeͅ mu oun, ti woͅn si se yeͅyeͅ oun ni igbooro, ba oͅpoͅloͅpoͅ nkan jeͅ fun oun.

‘’Bi o tileͅ jeͅ pe isͅeͅleͅ yii mu mi ni iyemeji nipa riran awoͅn eniyan loͅwoͅ, amoͅ mi o ni salai ran awoͅn eniyan loͅwoͅ.’’

‘’Iseͅleͅ yii yi aye mi pada, ti oͅpoͅ eniyan si n sa fun mi.’’

‘’Amoͅ ajoͅ ‘Justice Project naa wa isͅeͅ funmi ni ile ounjeͅ kan nipinleͅ Eko. Eͅrongba mi ni lati da ile ounjeͅ temi sileͅ ni oͅjoͅ iwaju.’’

''Ida aadoͅrin awoͅn to wa ni oͅgba eͅwoͅn ni woͅn n reti idajoͅ''

Oͅpoͅloͅpoͅ awoͅn to wani oͅgba eͅwoͅn ni woͅn n reti idajoͅ, eleyii to mu ki oͅgoͅoͅroͅ eniyan poͅ si oͅgba eͅwoͅn kaakiri orileͅede Naijiria.

Ninu oͅroͅ reͅ, minisita fun oͅroͅ abeͅle, Rauf Aregbesola ni iye awoͅn eniyan to w ani oͅgba eͅwoͅn ni Naijiria n koͅ awoͅn lominu.

Bakan naa lo fikun gbe awoͅn 51,541 ninu awoͅn 75,635 to w ani oͅgba eͅwoͅn ni woͅn n reti idajoͅ.