Togo, Ghana ati Côte d’Ivoire ń páyà nípa ìbò Nàíjíríà tó ń bọ̀ - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo
Aarẹ tẹlẹ ri, Olusegun Obasanjo sọ pe ireti wa pe ko si ohun ti yoo ṣediwọ fun aṣeyọri eto idibo apapọ ọdun 2023 ti yoo waye lọjọ karunlelogun oṣu kẹji ati ọjọ kọkanla oṣu kẹta Ọdun yii.
Aarẹ tẹlẹri naa sọrọ yii nigba to n gbalejo awọn igbimo majẹkobajẹ fẹgbẹ oṣelu (BoT) African Democratic Congress (ADC) ni ile rẹ to wa ni Abeokuta, ipinlẹ Ogun.
Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu ADC ni Alaga wọn, Dokita Mani Ibrahim Ahmed; Alaga apapọ fun egbe naa, Ojogbon Ralph Nwosu ati eni to jẹ oludije Aarẹ tẹlẹri ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, Chukwuka Monye ko sodi wa ṣe abẹwo naa.
Gẹgẹ bi Obasanjo ti sọ, Naijiria wa ni akoko ti o se pataki fun idagbasoke rẹ, o si rọ awọn ọmọ orilẹede yii lati mu eto idibo naa ni ọkunkundun gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe ni awọn orilẹede ti o ti goke agba lagbaye.
Mò gbàdúrà kì mìmì kankan má mi ìbò tó ń bọ̀ - Obasanjo
Balogun Owu wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati sapa wọn lati rii daju pe eto idibo gbogbogbo yoo waye.
Obasanjo ni Oju gbogbo agbaye wa lara orilẹede yii, papajulọ eto idibo ọdun yii, to si rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati sa ipa wọn, ki eto idibo naa le lo ni irọwọrọsẹ.
Obasanjo ni "A wa ni akoko to ṣe pataki ni Naijiria, laarin ọsẹ mẹta, a o lọ dibo,
Mo gbagbọ pe ohunkohun ko ni di lọwọ, laarin ọsẹ mẹta si akoko yii, a o yan aṣaaju ti yoo tukọ orilẹde Naijiria fun ọdun mẹrin to n bọ.
“Mo lọ si Togo, Ghana ati Côte d’Ivoire ninu ọsẹ yii ; gbogbo wọn lo ni ipaya nipa eto idibo orilẹde Naijiria.















