Lílo pápá ìṣeré Ameisimaka fún ìpolongo ìbò Atiku dá ìjà sílẹ̀ láàrin Wike àti PDP

Wike ati Atiku

Oríṣun àwòrán, Nyesomwike/AtikuAbubakar/Twitter

Gomina Ipinlẹ Rivers Nyesom Wike ti fọwọsi lilo papa iṣere Adokia Ameisimaka fún eto ipolongo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Wike fi ọrọ naa lede nibi ipolongo ibo sipo gomina Ipinlẹ Rivers ni ijọba ibilẹ Ogu/Bolo.

O ni ọpọlọpọ eeyan lọ bẹ oun lori rẹ, idi sì niyi tí oun fi faaye silẹ ki ẹgbẹ oṣelu PDP lo papa iṣere na.

Saaju ni kọmisona fun ere idaraya nipinlẹ Rivers, Chris Green ti kọwe ransẹ si Aminu Tambuwa tii se alaga ipolongo ibo fun Atiku Abubakar.

O ni ijọba ipinlẹ naa ti fofin de lilo papa iṣere naa lọjọ kọkanla oṣu keji ọdun yii, lẹyin ti ijọba ipinlẹ Rivers ti fun wọn ni aṣẹ lati lo papa iṣere naa ni ọjọ kọkanla oṣu kinni.

Ninu lẹta ti ijọba ipinlẹ Rivers ti kọkọ fi ṣọwọ sì ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, o ni " iwadii fihan pe ẹka kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹka to risi ipolongo aarẹ Atiku Abubakar, eyi ti Tonye Cole ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ko sodi".

Aworan leta

Oríṣun àwòrán, Ijoba Ipinle Rivers

"Lẹta na ni akọsilẹ ijọba Rivers fi han pe ise awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni o ma n yọrí si ija,iṣeku pani, yiyin ado oloro".

Chris ni ijọba ipinlẹ Rivers ko fẹ ki awọn ohun elo ijọba baje niwọn igbati apa kan ẹgbẹ oṣelu APC eyiti Patrick Cole dari baa wa no papa iṣere na.

Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Gov NyesomeWike/facebook

Maa mu papa isere rẹ, a ko lo mọ - PDP

Adari eto ipolongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Rivers, Dr Leloonu Nwibubasa ni awọn ko ṣetan lati lo papa iṣere Ameisimaka mọ.

O ni iroyin ti kan awọn pe Gomina Wike ti fun ẹgbẹ PDP laye lati lo papa iṣere Ameisimaka ṣugbọn awọn ko ni lo papa iṣere naa mọ.

Leloonu ni ti Wike ba fe ki awọn lo papa iṣere naa, ko kọwe ransẹ si Ọga agba eto ipolongo idibo aarẹ fun Atiku Abubakar.

O ni bi o ti sọ níbi eto ipolongo ibo sipo Gomina Ipinlẹ Rivers ko to.

Ema gbagbe pe Gomina Ipinlẹ Rivers ati awọn gomina miiran ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti n tako iyansipo Ayu gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.