Eͅ yoͅ adarí INEC l’Eko, ó ti gbàbọ̀dè fún bó ṣe fẹ́ lo ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò fétò ìdìbò lábẹ́ ìdarí MC Oluomo - Atiku Abubakar

Atiku Abubaka, MC Oluomo àti Mahmood Yakubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oludije sipo aareͅ leͅgbeͅ osͅelu PDP ni Naijiria, Atiku Abubakar ti kesi Ajoͅ eleto idibo ni Naijiria INEC lati yoͅ adari ajoͅ naa nipinleͅ Eko, Olusegun Agbaje kuro ni ipo.

Ninu ateͅjade kan ti agbeͅnusoͅ fun Atiku, Phrank Shaibu fisita, o ni woͅn ti fi eͅhoͅnu woͅn lede.

Atiku ni awoͅn ko faramoͅ bi Agbaje sͅe teͅnumoͅ pe awoͅn awakoͅ nipinleͅ Eko ti Musiliu Akinsanya aka MC Oluomo jeͅ adari fun, ni woͅn yoo lo fun idibo naa.

Eͅgbeͅ oselu PDP ni gbogbo aye lo moͅ pe eͅgbeͅ osͅelu APC ni MC Oluomo n se atileͅyin fun un.

Shaibu sapejuwe oͅro ti Agbaje soͅ wi pe awoͅn ko lee lo ajoͅ NURTW ati RTEAN fun idibo nipinlͅeͅ Eko nitori woͅn ti fofin de woͅn geͅgeͅ bi oͅroͅ ti ko leͅseͅ nleͅ.

‘’ Ofin fi lede pe ileeͅjoͅ nikan lo lasͅeͅ labeͅ ofin lati soͅ wi pe ajoͅ kan ko fi eͅseͅ muleͅ moͅ nipinleͅ kan tabi omiran.’’

‘’Ko bojumu ki woͅn fi eto idibo le awoͅn ti woͅn jeͅ pe eͅgbeͅ osͅelu kan ni woͅn n sͅisͅeͅ fun paapaa MC Oluomo ti gbogbo eniyan moͅ pe yoo sͅisͅeͅ fun Bola Tinubu.’’

Shaibu pe akiyesi INEC si iroyin pe Agbaje kan naa lo se akoso eto idibo to waye ni oͅdun 2018 ni ipinleͅ Osun, to si fihan pe magomago waye ninu eto idibo naa.

‘’Nitori naa kii se iru eniyan ti woͅn ti fi eͅsun kan pe eto idibo to sagbateͅru fun ni magomago ninu lo yeͅ ki woͅn gbe wa si ipinleͅ Eko’’

Bakan naa ni woͅn fi eͅsun kan woͅn pe awoͅn oludibo miran ko i tii ri PVC woͅn gba ni awoͅn agbegbe kan, ti woͅn sapejuwe geͅgeͅ bi eleyii ti awoͅn alatileͅyin woͅn poͅsi juloͅ.

Nitori naa Shaibu ni awoͅn kesi alaga ajoͅ INEC ni Naijiria, Mahmoud Yakubu lati yoͅ Agbaje ni kiakia ki otitoͅ le joͅba ni eto idibo ti yoo waye ni Naijiria, paapaa nipinleͅ Eko.

Bakan naa ni woͅn ke si INEC lati mase lo eͅnikeͅni to niise peͅlu MC Oluomo ni eto idibo naa lati pin iwe idibo ni oͅjo idibo nitori yoo ni magomago ninu.

Mi ò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú MC Oluomo, èmi kọ́ ni mo wà nídìí ọkọ̀ wíwá - Agbaje fèsì padà fún Atiku

Olusegun Agbaje

Oríṣun àwòrán, Segun Agbaje/TWITTER

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Eko, Olusegun Agbaje ti júwe ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àjọ náà pé ó ń lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú alága páàkì àti gáràjì Eko, Musiliu Akinsanya láti fi ṣèrú ìbò pé kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Agbaje ní gbogbo ìpèníjà tó ń kojú Nàìjíríà lásíkò yìí wà lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú bó o ba o pá, bó ò ba ó bù ú lẹ́sẹ̀ tí wọ́n le ṣe ohunkóhun láti fi jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò.

Ó tẹnumọ pé òun kò ní báwọn lọ́wọ́ sí ètò tàbí ìgbésẹ̀ kankan èyí tó le ba ṣàkóbá fún INEC láti ṣètò ìdìbò èyí tí kò ní ní ẹja n bákàn nínú.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé àwọn lẹ́nulọ́rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko, Agbaje fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun kìí fi ẹ̀rí ọkàn òun ṣeré àti pé ìpínlẹ̀ Eko ti kojú àwọn làásìgbò lásíkò ìbò sẹ́yìn, tí àwọn kò sì gbèrò láti ní òmíràn báyìí.

Ó ní gbogbo ènìyàn ló gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ láti ri pé ètò ìdìbò lọ ní pẹ̀lẹ́ kùtù ní ìpínlẹ̀ Eko.

Agbaje ṣàlàyé pé òun kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú MC Oluomo àti pé àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ní ìjọba ìbílẹ̀ ló máa ń ṣiṣẹ́ lórí bí wọ́n yóò ṣe wá àwọn awakọ̀ tó le báwọn kó ẹrù káàkiri.

Ó fi kun pé funfun ni ọwọ́ òun mọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Ẹ má fikún ìyà tó ń jẹ aráàlú, ẹ kò gbọdọ̀ sún ìdìbò síwájú - PDP ṣèkìlọ̀

Aworan ààrẹ Buhari nibi to ti n dibo

Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kan, Timi Frank ti ṣèkìlọ̀ fún ààrẹ Muhammadu Buhari láti máse gbèrò tàbí gbà sí àwọn tó ń pè fún sísún ọjọ́ tí ètò ìdìbò gbogbogbò yóò wáyé síwájú.

Frank, tó ti fìgbà kan jẹ́ igbákejì agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ní àwọn tó ń pè fún sísún ọjọ́ idibo náà síwájú, ń wá ọ̀nà láti ṣe èrú ìbò ni.

Ó ní kò yẹ kí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC tún fikún gbogbo ìpèníjà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú, nípa sísún ọjọ́ ìdìbò síwájú.

Ó sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ti ẹ̀ ní gba ìjọba láàyè bẹ́ẹ̀ nítorí ìjọba tó wà lóde ti sú wọn, tí wọ́n sì ti ṣetán láti fi ìbò wọn gbé wọn kúrò.

Tinubu mọ pe oun ko le bori ibo lo se fẹ dọgbọn pe ki wọn sun idibo siwaju - Frank

Frank nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní ìlú Abuja ní ìpè òun pọn dandan nítorí gbogbo ipá tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti olùdíje rẹ̀, Bola Ahmed Tinubu ń sà láti sún ètò ìdìbò ọ̀hún síwájú.

Ó ní ó ti hàn sí Tinubu pé ó ṣeéṣe kí ó má jáwé olúborí ló ṣe ń dọ́gbọ́n wá bí ètò ìdìbò náà yóò ṣe sún síwájú láti parí gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọ́n fi máa ṣèrú ìbò ọ̀hún.

Ó tún fẹ̀sùn kan pé Tinubu ti lọ fún àwọn àwọn àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba lówó káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti máa pè fún sísún ọjọ́ ìdìbò náà síwájú èyí tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ ọ̀wọ́ngógó epo àti owó Náírà ṣe ìkẹ́wọ́.

Àkọlé fídíò, Biyi Otegbeye: Ìrẹ́jẹ àti ìrìn ìdọ̀tí wà nínú APC l‘Ogun, ni mo ṣe lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlu ADC

"Buhari ko gbọdọ gba pe ki awọn abẹsinkawọ Tinubu si oun lọna"

Frank tẹnumọ pé ipa rere kan ṣoṣo tí Ààrẹ Buhari yóò fi lélẹ̀ ni tó bá ṣe àmúṣẹ ìlérí rẹ̀ láti ṣètò ìdìbò èyí tí kò ní ẹja ń bákàn nínú.

Ó fi kun pé Tinubu ti ṣaájú sọ pé ìṣèjọba ẹgbẹ́ òṣèlú APC kùnà nínú ìjọba wọn àti pé ohun tí ààrẹ le fi fọ ara rẹ̀ mọ́ ni láti ṣètò ìdìbò tó mọ́yán lórí.

“Buhari ti ṣe ìlérí fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà àti àgbáyé láti ṣètò ìdìbò tí yóò gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀, kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àwọn gómìnà APC àti àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ Tinubu ṣi òun lọ́kàn.”

“Ó nílò láti já irọ́ Tinubu pé ìjọba òun ṣe dada nípa ríri pé ètò ìdìbò lọ ní ìrọ̀wọ́rọsẹ̀”

Frank sọ wí pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ṣetán láti kópa nínú ètò ìdìbò kí wọ́n le yan adarí tuntun tó wù wọ́n ìyẹn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.