Ó ti di òkú 11,000 tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríri lọ ní Turkey àti Syria

Turkey

Akọsilẹ iye awọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi ijamba ilẹ riri Syria ati Turkey ti pọ si.

Nibayii, awọn alasẹ orilẹede mejeeji ti kede pe awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun mkanla (11,000) lo ti bá iṣẹlẹ naa lọ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ to risi iṣẹlẹ pajawiri ni Turkey, eeyan to to ẹgbẹrun mẹjọ (8000) lo ba isẹlẹ naa lọ.

Amọ o soro lati sọ pato akọjọpọ iye awọn eeyan to padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ ilẹ riri ni Syria.

Sugbọn iroyin lati ile iṣẹ iroyin ijọba ati awọn adoola ẹmi fihan pe o le ni eeyan ẹgbẹrun meji ati aabọ (2500) to ti padanu ẹmi wọn sinu isẹlẹ naa.

Bakan naa, o ti to eeyan bii okoolelẹgbẹfa ati aabọ (1250) to padanu ẹmi wọn ni awọn agbegbe to wa labẹ iṣakoso ijọba.

Àkọlé fídíò, Turkey earthquake demolishes buildings in Malatya

Afikun ti de ba iye awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ilẹ riri waye lorilẹede Turkey ati Syria. Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AFP ṣe sọ o to eeyan ẹgbẹrun mẹfa ku diẹ lorilẹede Turkey ati ọpọlọpọ eeyan ni Syria.

Bakan naa ni ijọba orilẹede Turkey kede ọjọ meje lati ṣe idaro awọn eeyan orilẹede naa to ba isẹlẹ naa lọ.

Aarẹ Recep Tayyip Erdogan, ninu ọrọ to fi sita lori ayelujara Twitter, “A ti bẹrẹ ibanidaro awọn eeyan wa fun ọjọ meje. Asia orilẹede naa ni yoo wa ni agbedemeji titi di ọjọ kejila oṣu keji ọdun 2023, fun awọn ogo ilu wa ati awọn eeyan wa lati oke okun to ba isẹlẹ naa lọ.”

Ọpọlọpọ awọn orilẹede lo ti ṣe ileri lati pese iranlọwọ lẹyin ti isẹlẹ ilẹ riri ṣe ikọlu si orilẹede Turkey ati Syria nigba ti awọn eeyan n sun lọwọ.

Ilẹ riri
Àkọlé fídíò, Turkey earthquake: Video shows destroyed buildings

Turkey ni kawọn ile ẹkọ mẹwaa ti ilẹ riri ṣe ijamba fun wa ni titi pa fun ọsẹ kan

Ọpọ ile ti awọn eeyan wa ninu rẹ lo dawo ni awọn orilẹede mejeeji, ti wọn si ni lati ma yọ awọn eeyan kuro labẹ awọn ile to dawo naa.

Igbakeji re ti isẹlẹ ilẹ riri yoo kọlu orilẹede Syria ati Turkey, isẹlẹ naa waye ni ago kan abọ lọjọ Aje ọsẹ yii.

Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ti ransẹ ibanikẹdun si orilẹede mejeeji to si ṣe ileri lati pese ohun iranlọwọ fun wọn.

Putin ni oun gba aladura pe ki alaafia de ba awọn to ṣe sẹ, ti orilẹede Russia si ṣetan lati pese ohun iranlọwọ fun awọn orilẹede naa,

Igbakeji aarẹ orilẹede Turkey Fuat Oktay ti kede pe awọn ile ẹkọ mẹwaa ti ilẹ riri ṣe ijamba fun ni wọn yoo wa ni titi pa fun ọsẹ kan.

Pátá lásán ló wà nídí ọmọ mi, tí mo fi gbé e sáré síta nínú yìnyín nígbà tí ilẹ̀ ríri bẹ̀rẹ̀ - Ọmọ Nàíjíríà

Aworan Johnson ati idile rẹ

Oríṣun àwòrán, emmanuel olaitan johnson/facebook

“Emi, Victor ati gbogbo idile mi lo ti di alainilelori bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii.”

Ọrọ ti Emmanuel Ọlaitan Johnson, ọmọ Naijiria kan to n gbe lorilẹede Turkey sọ fun BBC News niyi pẹlu bi awọn alaṣẹ ṣe n fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹlẹgbẹ ẹmi lo ti sọnu sinu iṣẹlẹ ilẹ riri to waye lorilẹede Turkey ati Syria.

Ilu Gaziantep to jẹ ọkan lara awọn ilu to fara kaasa iṣẹ ajalu ilẹ riri to waye ni Turkey lọjọ Aje.

“Nnkan bii agogo mẹrin kọja iṣẹju mẹtadinlogun owurọ ni o bẹrẹ.”

O ni oun n ṣẹṣẹ n ji nile oun to wa ni aja kẹta ile alaja mẹrin kan nibẹ ni lasiko ti ajalu ilẹ riri naa fi waye eleyi to ti gbẹmi eeyan to le lẹgbẹrun meji lorilẹede Turkey bayii.

"Mo fori la iku lati lọ ba ọmọ mi mu bata rẹ ninu ile tori o n fi ẹsẹ rin ninu yinyin"

Emmanuel Ọlaitan Johnson sọ pe, “Ori iduro ni mo wa nigba ti ilẹ riri naa bẹrẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n waye lọpọ igba. Amọṣa nigba ti mo bẹrẹ si nii ri i pe awọn ogiri n la, ni bo ba sare fa iyawo mi ati ọmọ mi ti a si sare jade kuro ninu ile.”

O tun ṣalaye siwaju sii pe, “Ki ile mi to bẹrẹ si nii wo, mo sare pada sinu ile nigba meji ọtọọtọ lati ko bata iyawo mi, ti ọmọ mi ati temi, ti mo si tun ko awọn iwe patakipataki kuro ninu ile naa.

Ọmọ meji ni ọgbẹni Johnson bi- ọmọ ọdun mẹrin ati meji ni wọn.

O ni nṣe ni eyi to jẹ ọmọ ọdun mẹrin n fi ẹsẹ rin ninu yinyin bayii lai wọ bata.

Idi niyi ti oun fi fori la iku pada lọ sinu ile naa lati lọ mu bata rẹ.

Àkọlé fídíò, Aworan iṣẹlẹ ilẹ riri naa bi o ṣe ri lati ofurufu

"Ile ti mo n gbe lati ọdun mẹwa sẹyin ti wo, mo ti di alainilelori"

“Ṣokoto awọtẹlẹ ati ẹwu awọtẹlẹ singilẹti ni a wọ nigba ti a kuro ninu ile.

Nitori naa mo tun ni lati sare pada lati lọ ko awọn nnkan ti ẹbi mii yoo nilo ninu otutu naa.

“Koda bi mo ṣe n sare sọ kalẹ lori akasọ ile naa, mo fẹrẹ ṣubu pẹlu bi ile naa ṣe n mi.”

O ni ile ọhun naa ni oun ti n gbe lati nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin, amọ bayii oun ti di alainilelori “nitori ile naa yoo dawo ni bi nnkankan ba ṣeṣi kan an. Gbogbo awọn to n gbe ile naa lo ti palẹmọ fi ibẹ silẹ.”

Ọgbẹni Johnson ni ile ọrẹ oun kan ni oun ati iyawo oun n fori pamọ si bayii.

‘Fidio ikọlu 9/11 ni mo n wo lọwọ, ki ilẹ riri naa to bẹrẹ’

Aworan awoku ile kan ni Turkey

Oríṣun àwòrán, ANADOLU AGENCY VIA GETTY IMAGES

O ni kayeefi ọrọ oun ni pe ni ọjọ to Aiku loun ṣi n wo fidio kan lori ikọlu 9/11 awọn agbesunmọmi si ilẹ Amẹrika .

“Mo ṣi n ro o pe iru ipo wo lawọn to wa lawọn ile ti iṣẹlẹ ikọlu naa ti waye nigba naa wa, lai mọ pe iru nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ si emi naa lọjọ keji.”

Lẹyin ti Johnson wo sakun iriri rẹ pẹlu iṣẹlẹ ilẹ riri naa lo fi ni oun ko gbadura lati ri ogun rara.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, awọn kan ti lọ n ṣe atipo lawọn ibudo ere idaraya ati ibudo ikonkan iṣẹmbaye pamọ si nibi ti simẹnti ti dunlẹ lara ile wọn daadaa pẹlu bi wọn tun ṣe n wuu gbọ pe iṣẹlẹ ilẹ riri miran n bọ lọna.

Àkọlé fídíò, Iṣẹlẹ ilẹ riri ni Turkey ati Syria

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, Johnson ati ẹbi rẹ ko tii gbọ ohunkohun lati ọdọ ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria lorilẹede Turkey.

“Abo ni a n wa kiri bayii nitori titi di bi a ṣe n sọrọ yii, iṣẹlẹ yii ko tii dawọ duro. Ni gbogbo wakati-wakati ni eeyan ṣi n gburo bi ilẹ ṣe n mi.”

Nnkan bii agogo kan abọ ọsan ni iṣẹlẹ ilẹ riri keji ti iwọn rẹ jẹ 7.5 magnitude tun kọlu orilẹede Turkey ati Syria.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Turkey sọ peo le ni ẹgbẹrun kan ati mọkanlelọgọfa eeyan to ti ku ni orilẹede naa nikan lẹyin ti iṣẹlẹ ilẹ riri naa waye. Ẹgbẹrun marun o le ọọdunrun eeyan lo ti farapa pẹlu.

Lorilẹede Syria ni tirẹ, eeyan ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o le mẹta, 783 lawọn alaṣẹ lorilẹede naa n kede pe ilẹ riri naa ti ran lọ sọrun, ti awọn to le lẹgbẹrun meji si ti fara pa.

Igbakeji aarẹ orilẹede Turkey, Fuat Oktay ọ pe ọsẹ kan gbako ni wọn yoo fi ti awọn ile ẹkọ to wa kaakiri awọn ilu mẹwaa to fara gba ajalu ilẹ riri naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Awọn ilu ti ọrọ kan ni Kahramanmaraş, Hatay, Gaziantep, Osmaniye, Adıyaman, Malatya, Şanlıurfa, Adana, Diyarbakır, Kilis.

Bakan naa ni igbakeji aarẹ, Fuat Oktay sọ pe gbogbo eto irinna ofurufu ni papakọ ofurufu lẹkun Hatay ni wọn ti so rọ bayii.

Wọn si tun ti ti awọn papakọ ofurufu ni Maraş ati Antep. Ọkọ ofurufu ologun nikan lo lee fo lawọn agbegbe naa bayii.