Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin Foluke Daramola àti Páátọ̀ Agbala Gabriel tó ń kọ́lé fún Iya Ibeji Omo Arayele

Aworan Pasitọ Agbala Gabriel, iya ibeji ọmọ arayele ati Folukẹ Daramọla

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel Global PAGE/folukedaramolasalako

Nigba ti iroyin jade pe iranwọ ti dide fun gbajumọ agba oṣere tiata, Arabinrin Adenikẹ̀ Adegboye, ti ọpọ mọ si Iya ibeji ọmọ araye le, ti wolii kan nilu Ibadan si ti n kọ ilegbe fun.

Inu ọpọ eeyan lo dun dẹyin fun oju aanu yii, ti wọn si n kan saara si wolii naa fun ọwọ ọrọ to na si iya ibeji to n se aisan ọhun.

Amọ o ya ni lẹnu pe awuyewuye ti n waye bayii lori ọrọ ile gbigba ati ile kikọ fun gbajumọ osere naa.

Gẹgẹ bi ọrọ naa ṣe n lọ, lẹyin ti Pasitọ ijọ Agbala Gabriel bẹrẹ ile tuntun kikọ fun agba oṣere naa, ni ọkan ninu awọn oṣere tiata ni Naijiria, Folukẹ Daramọla jade sita lori ayelujara lati ṣalaye pe ọrọ naa ko ri bi ọpọ ṣe n ro o.

Awọn ololufẹ iya Ibeji n fi eebu ara ati ọrọ kobakungbe bu Foluke daramola

Foluke ni wọn ti gba ilegbe saaju fun Iya ibeji ọmọ araye le nilu Ikorodu nitori ati le e moju to itọju rẹ nile iwosan.

Awuyewuye naa ti le de ibi pe ọpọ awọn ololufẹ igun mejeeji ti n tahun si ara wọn.

Koda, awọn kan tilẹ n fi eebu ara bu Folukẹ Daramọla pẹlu oriṣiriṣi orukọ kobakungbe ti wọn fi n bu u.

Amọ ṣa, Folukẹ Daramọla naa ti jade lati sọko ọrọ ranṣẹ si awọn to n bu ẹnu atẹ lu u lori ọrọ to sọ nipa ile tuntun ti wọn fẹ kọ naa.

Alaye Foluke ni pe ile ti wn n kọ naa le e ṣokunfa ifasẹyin fun ilera iya ibeji ọmọ araye le.

Bawo ni ọrọ yii ṣe bẹrẹ?

Aworan Iya ibeji omo arayele pẹlu Folukẹ Daramọla

Oríṣun àwòrán, folukedaramolasalako/instagram

Ni ọdun 2022 ni gbajumọ oṣere tiata ati ẹlẹyinju aanu, Folukẹ Daramọla pariwo sita pe ojojo n ṣe ogun iya ibeji ọmọ arayele, ara rẹ ko si da.

Ni ọjọ karun un oṣu keje ọdun 2022 ni Folukẹ Daramọla gbe fidio kan jade loju opo instagram rẹ pe agba oṣere naa nilo iranwọ fun itọju kiakia.

Folukẹ̀ Daramọla ya fidio bo ṣe lọ ki iya ibeji ọmọ araye le ni ile iwosan. Eyi lo pe ọpọ akiyesi si ipo ilera agba oṣere naa.

“Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ka maa ranti iya ibeji ninu adura wa, ki a si fi iranwọ owo yoowu ti ẹ ba lagbara ṣọwọ si inu aṣuwọn ifowopamọsi wọn.”

Pasitọ ijọ Agbala Gabriel nawọ iranwọ

Aworan pasito ijọ agbala Gabriel global ati iya ibeji omo arayele

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel Global PAGE

Lẹyin ti BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun ọmọ agba oṣere iya ibeji ọmọ arayele, arabinrin Aderonkẹ lori ipenija wọn ni alufaa ijọ Agbala Gabriel nilu Ibadan dide iranwọ lati kọ ile fun un.

Ilẹ naa ti o ti n sun mọ ipele ati pari bayii.

Alagba naa ni wọn gbe agba oṣere ọhun wa fun itọju ni ọdọ oun ni ti ara rẹ si tun ti n ya.

Ọmọbinrin mama Ibeji ọmọ arayele fi idi igbesẹ naa mulẹ.

Folukẹ Daramọla sọrọ sita pe ile naa yoo ṣe ọpọ akoba fun iwosan Iya ibeji ọmọ araye le

Foluke Daramola ati iya ibeji ọmọ arayele

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé fídíò, Adenike Adegboye: Ó bí ọmọ méjì ṣùgbọ́n ayé kò jk kí Iya Ibeji jèrè wọn nítorí pé.....

Ninu fidio kan ti Folukẹ Daramọla gbe jade lẹyin ikede alufa Agbala Gabriel lo ti sọ pe awọn wulẹ ti gba ile fun agba oṣere naa ni ilu Ikorodu ati pe ko si idi fun un lati tun maa lọ gbe ile to sọ pe o jinna si aarin awọn eeyan.

Bakan naa ni oṣere sinima naa ṣalaye siwaju sii peawọn arugbo ni wọn maa n kọ iru ile bẹẹ fun, bẹẹ si ni loju oun, iya ibeji ọmọ arayele ko tii to fẹyinti.

O ni asiko to yẹ ki agba oṣere naa wa ni ayika awọn eeyan niyi ki o si sun mọ ibi ti ile iwosan to ti n gba itọju wa.

Sugbọn fidio naa ni ko dun mọ awn eeyan kan ninu, ti wọn si doju oro kọ Foluke Daramola.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ọmọ Iya ibeji Omo arayele sọrọ lori isẹlẹ naa

Ọmọbinrin Aderonke naa fidi ọrọ yii mulẹ to si tun dupẹ lọwọ gbajugbaja osẹrebinrin, Foluke Daramola fun aduroti rẹ lati igba ti mama ti n ṣe aisan

Aderonke ni Daramọla lo ti n pese ounjẹ fun mama lati igba ti mama ti bẹrẹ aisan to si n tọju wọn.

Bakan naa lo fikun un pe nibayii Foluke Daramola ti gba ile fun Mama ni agbegbe Ikorodu ni ilu Eko lẹyin ti o gbọ pe wọn ni iṣoro ile gbigbe.

Alufaa Agbala Gabriel pada sori ayelujara lori ọrọ ti Folukẹ Daramọla sọ

Lẹyin ti ọrọ Folukẹ Daramọla bọ si igboro ni alufaa ijọ naa sọ pe awọn ololufẹ ajọ iranwọ oun ti n fi ibinu yọ lori ọrọ ti Folukẹ Daramọla sọ naa, ti wọn si n pe e ni iwa afibisu oloore.

O ṣalaye ni fidio naa to ṣe lori ilẹ ibi ti iṣẹ ile ti nlọ naa. O ni owo to to miliọnu kan ati ẹgbẹrin naira (N1.8m) ni owo ti wọn ti na si ori ile naa ati pe ko si ohunkohun ti yoo da ile naa duro.

O ni bi ile naa ba pari Iya ibeji ọmọ arayele ni wn yoo ko kọkọrọ rẹ le lọwọ, ohun to ba si wu u ni ko fi ṣe nigba naa.

Bi o tilẹ jẹ wi pe o han loju ati ohun iranṣẹ Ọlọrun naa pe inu n bii, inu rẹ ko dun si ọrọ naa, o ni awọn ololufẹ ajọ oun kaakiri agbaye ni oun yoo bẹ lori ọrọ naa.

Awọn eeyan sọrọ alufansa si Folukẹ Daramọla lori ayelujara loun naa ba fi epe bọnu

Folukẹ Daramọla tun bọ sori ayelujara ti wa n tutọ soke foju gba a lẹyin ti awọn eeyan kan bẹrẹ si ni n fi ọrọ kobakungbe ranṣẹ si i lori ọrọ rẹ nipa ile naa.

Ohun ti wọn n sọrọ sii le lori ni bi o tun ṣe ni lati gba ile fun agba oṣere naa nilu Eko nigba ti pasitọ kan ti bẹrẹ si ni kọ ile fun un nilu Ibadan.

Lori ọrọ naa ni oṣere tiata naa ti bọhun pe ilera agba oṣere iya ibeji ọmọ arayele lo jẹ oun logun. Ati wi pe ko si bi wọn ṣe maa gbe e lọ si inu abule ti wọn kọ ile si fun un yii ti ko ni ṣe idiwọ fun itọju rẹ.

O fi kun un pe ilu Eko ni dokita to n tọju agba osere naa wa, ko si si bi yoo ṣe maa rọrun fun un lati maa na Eko si ibadan ni gbogbo igba to ba nilo ati ri dokita naa.

Bakan naa lo ṣalaye pe ṣaaju gbogbo igbesẹ yii ni awọn ọrẹ oun ti da owo to le ni miliọnu kan naira fi ra kẹkẹ Maruwa fun ọmọ iya ibeji ọmọ araye le lati maa fi ṣiṣẹ lati lee gbọ bukata wọn.

Àkọlé fídíò, Joy Adekunle Adejare: Torí òkìkí tí mo ní nídìí iṣẹ́ àgbo ni wọ́n ṣe jí ọkọ mí gbé, pa á