Tinubu fáwọn ẹbí ọdẹ ìbílẹ̀ tí agbébọn pa ní N100m, ó lérí láti fòpin sí ìgbéṣùnmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, @BATofficial
Olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Party, APC Bola Ahmed Tinubu ti ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi tẹ̀síwájú láti ṣe ìpolongo ìbò ní ìpínlẹ̀ Katsina pẹ̀lú àjálù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ní ọjọ́bọ̀ tó kọjá ni àwọn agbébọn ṣekúpa àwọn fijilanté tó le ní ọgọ́rùn-ún nínú igbó Yargoje, agbègbè Kankara, ìpínlẹ̀ Katsina.
Tinubu níbi ìpolongo náà ní òun pẹ̀lú gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Aminu Masari ṣe ìpàdé títí di alẹ́ ọjọ́ Àìkú láti fẹnukò bóyá kí àwọn tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpolongo náà tàbí ṣe ìdádúró rẹ̀.
Iwa ika ti ko ba iwa ọmọluabi mu ni awọn agbebọn n hu - Tinubu
Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó ba ni lọ́kàn jẹ́ ni nǹkan tí àwọn agbébọn náà ṣe àmọ́ gómìnà Masari ní tí àwọn kò bá tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpolongo á jẹ́ wí pé nǹkan àwọn agbébọn náà fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ti wá sí ìmúṣẹ nìyẹn.
Ó fi kun pé ìjọba kò ní ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn agbébọn náà nítorí wọn yóò gbèrè ọṣẹ́ tí wọ́n ṣe.
Tinubu kọminú pé ìwà ìkà èyí tí kò bá ìwà ọmọlúàbí ni àwọn agbébọn náà ń hù tó sì sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn ni àwọn máa ṣẹgun wọn.
Ṣaájú ni Tinubu ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà fún mọ̀lẹ́bí àwọn tó forí ṣọ̀tà ìwà ìgbéṣùmọ̀mí ní ìpínlẹ̀ Katsina.
Tinubu nìkan ló le mú ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà - Buhari
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ Muhammadu Buhari níbi ètò ìpolongo ìbò náà jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn tó gbópọn fún Tinubu láti di ààrẹ nígbà tí òun bá gbésẹ̀.
Ó ní òunàti ẹgbẹ́ òṣèlú APC lápapọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Tinubu láti gbé Nàìjíríà dé èbúté ayọ̀.
Ó rọ gbogbo àwọn tó wà níbi ìpolongo náà láti dìbò fún Tinubu àti ẹgbẹ́ APC níbi ètò ìdìbò gbogbogboò tí yóò wáyé ní oṣù yìí.
Ààrẹ Buhari ní Tinubu nìkan ló le mí ìdúróre bá Nàìjíríà, tí ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè yóò fi wà.
Ó fi kun pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí ìjọba òun kojú, àwọn gbìyànjú láti lapa ire ju ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ.
Agbébọn gbẹ̀mí èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún lásìkò tí wọn jí màálù lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, awọn ọdẹ ibilẹ to le ni ọgọrun ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbebọn ni opin ọsẹ to kọja yii.
Isẹlẹ yii waye lasiko tawọn agbebọn kọlu awọn ọdẹ ibilẹ naa ninu igbo Yargoje to wa nijọba ibilẹ Kankara nipinlẹ Katsina.
O si le ni oku awọn ọdẹ ibilẹ mọkanlelaadọrin ti wọn ti sin bayii nigba ti aayan ti n lọ lọwọ lati sawari oku awọn to le ni aadọrin, tawọn agbebọn ọhun pa.
Olugbe ilu naa kan sọ fun BBC pe o le ni ọjọ meji tawọn agbebọn ọhun atawọn ọdẹ ibilẹ naa fi n wọya ija.
Ikọlu yii si lo kan awọn eeyan to wa ni igbo Yargoje nibi ti awọn abule bii Bakori, Kankara ati Malumfashi wa.
Nilu Jargaba to wa lagbegbe Malumfashi, o le ni eeyan mẹwa ti wọn ti sin nitori ikọlu naa.
Ki lo sokunfa aawọ naa?
Iroyin to tẹ BBC lọwọ sisọ loju rẹ pe awọn agbebọn yii lo lugọ de awọn darandaran, ti wọn si ji awọn maalu wọn lọ.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa to ba BBC sọrọ ni “Ibọn olowo iyebiye lawọn agbebọn naa gbe lọwọ amọ ibọn ilewọ lasan lo wa lọwọ awọn ọdẹ ibilẹ naa.
Idi si niyi to fi rọrun fawọn agbebọn naa lati pa awọn ọdẹ ibilẹ yii ni ipakupa, ti wọn si bori wọn.”
Awọn eeyan agbegbe naa ni lọgan lawọn figbe ta lati beere fun iranlọwọ sugbọn ẹnikẹni ko wa seranwọ fun awọn.
Igbo Yargoje yii si lo ti jẹ ibuba nla fun ọpọ awọn adigunjale atawọn agbebọn eyi to n dunkooko mọ igbe aye awọn eeyan to wa lẹkun guusu ipinlẹ Katsina.
Lara awọn ilu to wa lẹun guusu Katsina ti ọrọ naa si kan ni ijọba ibilẹ Bakori, Malumfashi, Kafur, Kankara, Faskari ati Funtua
















