Àjọ Alálàájì kéde ìye èèyàn tí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan yóò kó lọ Hajj ní 2023

Awọn alalaaji

Ajọ to n se akoso eto Hajj ni Naijiria, NAHCON ti kede iye alalaji ti ipinlẹ kọọkan lorilẹede yii yoo ran lọ si Mecca lọdun yii.

Atẹjade kan ti igbakeji oludari ẹka eto iroyin labẹ ajọ naa, Mousa Ubandawaki fisita lọjọ Ẹti salaye pe awọn igbimọ alalaji nipinlẹ kọọkan ni ilana pinpin iye awọn alalaji ọhun kan.

Ubandawaki salaye pe nibi ipade igbimọ alasẹ fun ajọ Alalaji ni Naijiria ni wọn ti se odiwọn iye Alalaji ti ipinlẹ atawọn ileesẹ tọrọ kan yoo fi ransẹ fun Hajj ọdun yii.

Bakan naa ni ipin iye awọn eeyan ti yoo lọ si Hajj lọdun 2023 yii kan awọn ileesẹ ijọba, igbimọ lajọlajọ, olu ilu ilẹ wa, Abuja ati ileesẹ ologun orilẹede yii.

Ajọ Alalaji naa wa kede pe ipin ẹgbẹrun lọna ogun ni wọn fi silẹ fawọn ileesẹ aladani to n ko awọn eeyan lọ si Mecca, ti wọn yoo si pin fun wọn lẹyin eto ayẹwo ati ẹri gbigba iwe asẹ irinna.

Atẹjade naa tun fikun pe gbogbo ipinlẹ to n ko awọn Alalaji lọ si Mecca lọdun yii lo gbọdọ san idaji owo awọn eeyan ti wọn n ko lọ ko to di ọjọ kẹwa osu Keji ọdun 2023.

Wo awọn ipinlẹ ti ipin Alalaji wọn pọ, wo awọn to kere julọ

Atẹjade ti ajọ Alalaji naa fi sọwọ salaye pe ipinlẹ Kaduna lo ko ida ipin to pọ julọ ninu awọn ipinlẹ ti yoo fi Alalaji ransẹ pẹlu ipin 5,982 ti wọn fun.

Ipinlẹ Kano si lo sun mọ pẹkipẹki pẹlu ipin 5,902 nigba ti ipinlẹ Sokoto si se ipo kẹta pẹlu ipin 5,504.

Nilẹ Kaarọ Oojire, ipinlẹ Eko ni 3,576, Oyo ni ipin 1,441, Ogun ni 1,139, Osun ni 1,054, Ondo ni 436, ti ipinlẹ Ekiti si ni 197.

Ipinlẹ Enugu lo ni ipin to kere julọ pẹlu ipin ogoji pere nigba ti ipinlẹ Bayelsa tẹle pẹlu ipin marunlelọgbọn, 35 pere.

Ipinlẹ Akwa Ibom ko ni ipin kankan ninu awọn ipinlẹ ti yoo ko Alalaji lọ si Mecca ldun yii nitori bi ko se sọ iwe asẹ rẹ di ọtun, ti wn si ti gbẹsẹ le isọwọ sisẹ igbimọ Alalaji nipinlẹ naa.

Ileesẹ Alalaaji naa ni oun ti gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de ipinlẹ Kogi lẹyin to se iwadi isọwọsisẹ igbimọ Alalaji rẹ bo se yẹ.

Bi ipin iye Alalaji ti ipinlẹ kọọkan yoo ko lọ si Mecaa lọdun 2023 se lọ ree:

Abia 53

Adamawa 2669

Anambra 39

Bauchi 3, 132

Bayelsa 35

Benue 236

Borno 2,735

Cross Rivers 66

Delta 74

Nassarawa 1,567

Niger 5,165

Ogun 1,139

Ondo 436

Osun 1,054

Oyo 1,441

Yobe 1,968

Ebony 117

Edo 274

Ekiti 197

Enugu 40

FCT 3,520

Gombe 2,301

Imo 30

Jigawa 1,525

Kaduna 5982

Kano 5,902

Katsina 4,913

Kebbi 4871

Kwara 3,219

Lagos 3,576

Plateau 1,984

Rivers 50

Sokoto 5,504

Taraba 1,590

Zamfara 3,083